God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Ẹ jẹ́ kí ẹni tí ń ṣògo nípa èyí nì wí pé: òun ní òye, òun sì mọ̀ mí wí pé, Èmi ni Olúwa tí ń ṣe òtítọ́, ìdájọ́ àti òdodo ní ayé, nínú èyí ni mo ní inú dídùn sí,” Olúwa wí.
“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí Èmi yóò fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí a kọ ilà fún nínú ara nìkan.
Gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ fún yín ẹ̀yin ilé Israẹli.
Báyìí ni Olúwa wí: “Má ṣe kọ́ ìwà àwọn kèfèrí, kí àmì ọ̀run kí ó má sì dààmú yín, nítorí pé wọ́n ń dààmú orílẹ̀-èdè.
Kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ Olúwa; o tóbi orúkọ rẹ sì tóbi lágbára.
Ta ni kò yẹ kí ó bẹ̀rù rẹ? Ọba àwọn orílẹ̀-èdè? Nítorí tìrẹ ni. Láàrín àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní orílẹ̀-èdè àti gbogbo ìjọba wọn, kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ.
Ṣùgbọ́n Olúwa ni Ọlọ́run tòótọ́, òun ni Ọlọ́run alààyè, ọba ayérayé. Nígbà tí ó bá bínú, ayé yóò wárìrì; orílẹ̀-èdè kò lè fi ara da ìbínú rẹ̀.
Ọlọ́run dá ayé pẹ̀lú agbára rẹ̀, ó dá àgbáyé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀, ó mú kí ọ̀run kí ó fẹ̀ síta nípa òye rẹ̀.
Nígbà tí ó bá sán àrá, àwọn omi lọ́run a sì pariwo; ó mú kí ìkùùkuu ru sókè láti òpin ayé. Ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò, ó sì ń mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀.
Ẹni tí ó bá jẹ́ ìpín Jakọbu kò sì dàbí èyí, nítorí òun ni ó ṣẹ̀dá ohun gbogbo àti Israẹli tí ó jẹ́ ẹ̀yà ìjogún rẹ̀. Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.
Nítorí èyí ni Olúwa wí: “Ní àkókò yìí, èmi yóò gbọn àwọn tí ó ń gbé ilẹ̀ náà jáde. Èmi yóò mú ìpọ́njú bá wọn, kí wọn kí ó lè rí wọn mú.”
Àwọn olùṣọ́-àgùntàn jẹ́ aṣiwèrè, wọn kò sì wá Olúwa: nítorí náà wọn kì yóò ṣe rere àti pé gbogbo agbo wọn ni yóò túká.
Èmi mọ̀ Olúwa wí pé ọ̀nà ènìyàn kì í ṣe ti ara rẹ̀, kì í ṣe fún ènìyàn láti tọ́ ìgbésẹ̀ ara rẹ̀.
Tún mi ṣe Olúwa, pẹ̀lú ìdájọ́ nìkan kí o má sì ṣe é nínú ìbínú rẹ, kí ìwọ má ṣe sọ mí di òfo.
Tú ìbínú rẹ jáde sórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́n, sórí àwọn ènìyàn tí wọn kò pe orúkọ rẹ. Nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run, wọ́n ti jẹ ẹ́ run pátápátá, wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ̀ di ahoro.
Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremiah wá:
Sọ fún wọn wí pé èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Ègbé ni fún ẹni náà tí kò pa ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí mọ́.
Àwọn májẹ̀mú tí mo pàṣẹ fún àwọn baba ńlá yín, nígbà tí mo mú wọn jáde láti Ejibiti, láti inú iná alágbẹ̀dẹ wá.’ Mo wí pé, ‘Ẹ gbọ́ tèmi, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún un yín. Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ènìyàn mi, Èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run yín.
Nígbà náà ni Èmi ó sì mú ìlérí tí mo búra fún àwọn baba ńlá yín ṣẹ; láti fún wọn ní ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti fún oyin,’ ilẹ̀ tí ẹ ní lónìí.” Mo sì dáhùn wí pé, “Àmín, Olúwa.”
Olúwa wí fún mi pé, “Kéde gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ní àwọn ìlú Juda àti ní gbogbo òpópónà ìgboro Jerusalẹmu pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí, kí ẹ sì se wọn.
Láti ìgbà tí mo ti mú àwọn baba yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá títí di òní, mo kìlọ̀ fún wọn lọ́pọ̀ ìgbà wí pé, “Ẹ gbọ́ tèmi.”
Ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kọbi ara sí i dípò èyí wọ́n tẹ̀síwájú ni agídí ọkàn wọn. Mo sì mú gbogbo ègún inú májẹ̀mú tí mo ti ṣèlérí, tí mo sì ti pàṣẹ fún wọn láti tẹ̀lé, tí wọn kò tẹ̀lé wa sórí wọn.’ ”
Olúwa sì wí fún mi pé, “Ọ̀tẹ̀ kan wà láàrín àwọn ará Juda àti àwọn tí ń gbé ní Jerusalẹmu.
Wọ́n ti padà sí ìdí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn tí wọn kọ̀ láti tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi, wọ́n ti tẹ̀lé àwọn ọlọ́run mìíràn láti sìn wọ́n. Ilé Israẹli àti ilé Juda ti ba májẹ̀mú tí mo dá pẹ̀lú àwọn baba ńlá wọn jẹ́.
Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Èmi yóò mu ibi tí wọn kò ní le è yẹ̀ wá sórí wọn, bí wọ́n tilẹ̀ ké pè mí èmi kì yóò fetí sí igbe wọn.