Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Má ṣe di ìbẹ̀rù fún mi, ìwọ ni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú.

  2. Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún mi: “Lọ dúró ní ẹnu-ọ̀nà àwọn ènìyàn níbi tí àwọn ọba Juda ń gbà wọlé tí wọ́n ń gbà jáde àti ní gbogbo ẹnu-bodè Jerusalẹmu.

  3. Sọ fún wọ́n pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọba Juda àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn Juda àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé ní Jerusalẹmu tí ń wọlé láti ẹnu ibodè yìí.

  4. Báyìí ni Olúwa wí, “Ẹ kíyèsi láti máa ru ẹrù lọ́jọ́ ìsinmi tàbí kí ẹ gbé wọlé láti ẹnu ibodè Jerusalẹmu.

  5. Má ṣe gbé ẹrù jáde kúrò nínú ilé yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ṣùgbọ́n kí ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ fún àwọn baba ńlá yín.”

  6. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá kíyèsi láti gbọ́ tèmi ní Olúwa wí, tí ẹ kò sì gbe ẹrù gba ẹnu-bodè ìlú ní ọjọ́ ìsinmi, ṣùgbọ́n tí ẹ ya ọjọ́ ìsinmi, sí mímọ́, nípa pé ẹ kò ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà.

  7. Àwọn ènìyàn yóò wá láti ìlú Juda àti ní agbègbè Jerusalẹmu, láti ilẹ̀ Benjamini, láti pẹ̀tẹ́lẹ̀, àti láti òkè, àti láti gúúsù wá, wọn yóò wá pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun, àti ọrẹ ẹran, àti tùràrí, àti àwọn tó mú ìyìn wá sí ilé Olúwa.

  8. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá pa òfin mi mọ́ láti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, kí ẹ má sì ṣe ru ẹrùkẹ́rù bí ẹ̀yin yóò ṣe máa gba ẹnu ibodè Jerusalẹmu wọlé ní ọjọ́ ìsinmi, nígbà náà ni èmi yóò da iná tí kò ní ṣe é parun ní ẹnu-bodè Jerusalẹmu tí yóò sì jó odi agbára rẹ̀.’ ”

  9. Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremiah wá wí pe:

  10. “Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé amọ̀kòkò, níbẹ̀ ni èmi yóò ti bá ọ sọ̀rọ̀.”

  11. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé:

  12. “Ẹyin ilé Israẹli, èmi kò ha lè ṣe fún un yín gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe?” ni Olúwa wí. “Gẹ́gẹ́ bí amọ̀ ní ọwọ́ amọ̀kòkò bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin rí ní ọwọ́ mi, ẹ̀yin ilé Israẹli.

  13. Bí ó bá jẹ́ ìgbà kan, tí èmi kéde kí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan di fífà tu láti dojúdé àti láti parun,

  14. tí orílẹ̀-èdè ti mo kìlọ̀ fún bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú wọn, nígbà náà ni Èmi yóò yí ọkàn mi padà nínú àjálù tí mo ti rò láti ṣe sí wọn.

  15. Ní ìgbà mìíràn tí èmi bá tún kéde láti tẹ̀dó tàbí gbin orílẹ̀-èdè kan tàbí ìjọba kan.

  16. Bí ó bá sì ṣe búburú níwájú mi, tí kò sì gba ohùn mi gbọ́, nígbà náà ni èmi yóò yí ọkàn mi padà ní ti rere, èyí tí mo wí pé, èmi ó ṣe fún wọn.

  17. “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, sọ fún àwọn ènìyàn Juda àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa wí: Wò ó! Èmi ń gbèrò ibi sí yin, èmi sì ń ṣe ìpinnu kan lórí yín. Nítorí náà ẹ yípadà kúrò lọ́nà búburú yín kí olúkúlùkù yín sì tún ọ̀nà àti ìṣe rẹ̀ ṣe.’

  18. Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí: “Ẹ béèrè nínú orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá ti gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí ri? Ohun tí ó burú gidi ni wúńdíá Israẹli ti ṣe.

  19. Nítorí àwọn ènìyàn mi gbàgbé mi, wọ́n sun tùràrí fún òrìṣà asán, tí ó mú wọn kọsẹ̀ ní ọ̀nà wọn, àti ọ̀nà wọn àtijọ́. Wọ́n mú wọn rìn ní ọ̀nà àtijọ́, àti ní ojú ọ̀nà ti a kò ṣe.

  20. Gẹ́gẹ́ bí afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn, Èmi yóò tú wọn ká lójú àwọn ọ̀tá wọn. Èmi yóò sì kọ ẹ̀yìn sí wọn, n kì yóò kọjú sí wọn ní ọjọ́ àjálù wọn.”

  21. Dẹtí sí ọ̀rọ̀ mi Olúwa, gbọ́ ohun tí àwọn tí ó fi mí sùn ń sọ.

  22. Ṣe kí a fi rere san búburú? Síbẹ̀ wọ́n ti gbẹ́ kòtò fún mi. Rántí pé mo dúró níwájú rẹ, mo sì sọ̀rọ̀ nítorí wọn, láti yí ìbínú rẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.

  23. Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa mọ gbogbo ète wọn láti pa mí, má ṣe dárí ẹ̀bi wọn jì wọ́n bẹ́ẹ̀ ni má ṣe pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ kúrò lójú rẹ. Jẹ́ kí wọn kí ó ṣubú níwájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì ṣe sí wọn nígbà ìbínú rẹ.

  24. Èyí ní ohun tí Olúwa wí: “Lọ ra ìkòkò lọ́dọ̀ alámọ̀, mú dání lára àwọn àgbàgbà ọkùnrin àti wòlíì.

  25. Kí o sì lọ sí àfonífojì ọmọ Beni-Hinnomu, níwájú ẹnu ibodè Harsiti, níbẹ̀ ni kí o sì kéde gbogbo ọ̀rọ̀ tí èmi yóò sọ fún ọ.