God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Kí o sì wí pé, ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọba àwọn Juda àti ẹ̀yin ará Jerusalẹmu. Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli sọ. Dẹtí sí mi! Èmi yóò mú ìparun wá síbí, etí gbogbo wọn tó bá gbọ́ ọ yóò hó yaya.
Nítorí wọ́n ti gbàgbé mi, wọ́n sì ti sọ ibí di ilé fún òrìṣà àjèjì; wọ́n ti sun ẹbọ nínú rẹ̀ fún òrìṣà tí àwọn baba wọn tàbí tí ọba Juda kò mọ̀ rí, wọ́n ti fi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kún ilẹ̀ yìí.
Wọ́n ti kọ́ ibi gíga fún Baali láti sun ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí ohun ẹbọ sísun sí Baali—èyí tí èmi kò pàṣẹ láti ṣe, tí èmi kò sì sọ, tàbí tí kò sì ru sókè láti inú ọkàn mi.
Nítorí náà ṣọ́ra ọjọ́ ń bọ̀ ni Olúwa wí nígbà tí àwọn ènìyàn kì yóò pe ibí ní Tofeti mọ́ tàbí àfonífojì ọmọ Hinnomu, ṣùgbọ́n àfonífojì Ìpakúpa.
“ ‘Ní ibí yìí ni èmi yóò ti pa èrò Juda àti Jerusalẹmu run. Èmí yóò mú wọn ṣubú nípa idà níwájú àwọn ọ̀tá wọn, lọ́wọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn. Èmi yóò sì fi òkú wọn ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀.
Èmi yóò sọ ìlú yìí di ahoro àti ohun ẹ̀gàn, gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò bẹ̀rù wọn yóò sì máa fòyà nítorí gbogbo ọgbẹ́ rẹ̀.
Èmi yóò mú kí wọ́n jẹ ẹran-ara ọmọ wọn ọkùnrin àti ẹran-ara ọmọ wọn obìnrin, ẹnìkínní yóò sì jẹ ẹran-ara ẹnìkejì, nígbà ìdótì àti ìhámọ́ láti ọwọ́ ọ̀tá wọn, àti àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn.’
Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. Èmi a fọ́ orílẹ̀-èdè yìí àti ìlú yìí gẹ́gẹ́ bí ìkòkò amọ̀ yìí ṣe fọ́ tí kò sì ní sí àtúnṣe. Wọn a sì sin àwọn òkú sí Tofeti títí tí kò fi ní sí ààyè mọ́.
Èyí ni ohun tí èmi yóò ṣe sí ibí yìí àti àwọn tí ń gbé ní ibí yìí ni Olúwa wí. Èmi yóò mú ìlú yìí dàbí Tofeti.
Jeremiah sì padà láti Tofeti níbi tí Olúwa rán an sí láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ó sì dúró ní gbangba tẹmpili Olúwa, ó sì sọ fún gbogbo ènìyàn pé,
“Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Tẹ́tí sílẹ̀! Èmi yóò mú ìdààmú tí mo ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ bá ìlú yìí àti ìgbèríko tí ó yí i ká, nítorí ọlọ́rùn líle ni wọ́n, wọn kò si ní fẹ́ fetí sí ọ̀rọ̀ mi.’ ”
Ní ìgbà tí àlùfáà Paṣuri ọmọkùnrin Immeri olórí àwọn ìjòyè tẹmpili Olúwa gbọ́ tí Jeremiah ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nǹkan wọ̀nyí.
Ó mú kí wọ́n lù wòlíì Jeremiah, kí wọ́n sì fi sínú túbú tí ó wà ní òkè ẹnu-ọ̀nà ti Benjamini ní tẹmpili Olúwa.
Ní ọjọ́ kejì tí Paṣuri tú u sílẹ̀ nínú túbú, Jeremiah sì sọ fún un wí pé, “Orúkọ Olúwa fun ọ kì í ṣe Paṣuri bí kò ṣe ìpayà.
Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa sọ. Èmi yóò mú ọ di ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ sí ara rẹ àti sí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Ní ojú ara rẹ, ìwọ yóò sì rí tí wọ́n ṣubú nípa idà ọ̀tá wọn. Èmi yóò fi gbogbo àwọn ọ̀tá Juda lé ọba Babeli lọ́wọ́, òun yóò sì kó wọn lọ sí Babeli tàbí kí ó pa wọ́n.
Èmi yóò jọ̀wọ́ gbogbo ọrọ̀ inú ìlú yìí fún ọ̀tá wọn. Gbogbo ìní wọ́n gbogbo ọlá ọba Juda. Wọn yóò sì ru ìkógun lọ sí Babeli.
Olúwa, o tàn mí jẹ́, o sì ṣẹ́gun. Mo di ẹni ẹ̀gàn ní gbogbo ọjọ́, gbogbo ènìyàn fi mí ṣẹlẹ́yà.
Nígbàkígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, èmi sì kígbe síta èmi á sọ nípa ipá àti ìparun. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Olúwa ti mú àbùkù àti ẹ̀gàn bá mi ni gbogbo ìgbà.
Ṣùgbọ́n bí mo bá sọ pé, “Èmi kì yóò dárúkọ rẹ tàbí sọ nípa orúkọ rẹ̀ mọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bẹ bi iná tí ń jó nínú mi nínú egungun mi, agara dá mi ní inú mi nítòótọ́ èmi kò lè ṣe é.
Ṣùgbọ́n Olúwa ń bẹ pẹ̀lú mi gẹ́gẹ́ bí akọni ẹlẹ́rù. Nítorí náà, àwọn tí ó ń lépa mi yóò kọsẹ̀, wọn kì yóò sì borí. Wọn yóò kùnà, wọn yóò sì gba ìtìjú púpọ̀. Àbùkù wọn kì yóò sì di ohun ìgbàgbé.
Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ìwọ tí ó ń dán olódodo wò tí o sì ń ṣe àyẹ̀wò ọkàn àti ẹ̀mí fínní fínní, jẹ́ kí èmi kí ó rí ìgbẹ̀san rẹ lórí wọn, nítorí ìwọ ni mo gbé ara mi lé.
Kọrin sí Olúwa! Fi ìyìn fún Olúwa! Ó gba ẹ̀mí àwọn aláìní lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.
Kí ọkùnrin náà dàbí ìlú tí Olúwa gbàkóso lọ́wọ́ rẹ̀ láìkáàánú Kí o sì gbọ́ ariwo ọ̀fọ̀ ní àárọ̀, ariwo ogun ní ọ̀sán.
Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá nígbà tí ọba Sedekiah rán Paṣuri ọmọ Malkiah àti àlùfáà Sefaniah ọmọ Maaseiah sí i; wọ́n wí pé:
“Wádìí lọ́wọ́ Olúwa fún wa nítorí Nebukadnessari ọba Babeli ń kọlù wá. Bóyá Olúwa yóò ṣe ìyanu fún wa gẹ́gẹ́ bí ti àtẹ̀yìnwá, kí ó sì yípadà kúrò lọ́dọ̀ wa.”