God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Èmi ó fi ìwọ àti ìyá tí ó bí ọ sọ̀kò sí ilẹ̀ mìíràn, níbi tí a kò bí ẹnikẹ́ni nínú yín sí. Níbẹ̀ ni ẹ̀yin méjèèjì yóò kú sí.
Ìwọ ilẹ̀, ilẹ̀, ilẹ̀, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa!
Báyìí ni Olúwa wí: “Kọ àkọsílẹ̀ ọkùnrin yìí sínú ìwé gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́mọ, ẹni tí kì yóò ṣe rere ní ọjọ́ ayé rẹ̀; nítorí ọ̀kan nínú irú-ọmọ rẹ̀ kì yóò ṣe rere, èyíkéyìí wọn kì yóò jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi tàbí jẹ ọba ní Juda mọ́.”
“Ègbé ni fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn tí ń tú agbo ẹran mi ká tí ó sì ń pa wọ́n run!” ni Olúwa wí.
Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ ní ti àwọn olùṣọ́-àgùntàn tí ń darí àwọn ènìyàn mi: “Nítorí tí ẹ̀yin tú agbo ẹran mi ká, tí ẹ lé wọn dànù tí ẹ̀yin kò sì bẹ̀ wọ́n wò. Èmi yóò jẹ yín ní yà nítorí nǹkan búburú tí ẹ ti ṣe,” ni Olúwa wí.
“Èmi Olúwa tìkára mi yóò kó ìyókù agbo ẹran mi jọ láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo ti lé wọn, Èmi yóò mú wọn padà sínú pápá oko wọn, níbẹ̀ ni wọn ó ti bí sí i, tí wọn ó sì pọ̀ sí i.
Èmi ó wá olùṣọ́-àgùntàn fún wọn, tí yóò darí wọn, wọn kì yóò bẹ̀rù tàbí dààmú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan kì yóò sọnù,” ni Olúwa wí.
“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí Èmi yóò gbé ẹ̀ka òdodo dìde fún Dafidi, ọba tí yóò lo ìjọba pẹ̀lú ọgbọ́n tí yóò sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ lórí ilẹ̀ náà.
Ní ọjọ́ rẹ̀ ni a ó gba Juda là, Israẹli yóò sì máa gbé ní aláìléwu. Èyí ni orúkọ tí a ó fi máa pè é: Olúwa Òdodo wa.
Nítorí náà, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí ènìyàn kì yóò tún wí pé, ‘Dájúdájú Olúwa wà láààyè tí ó mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.’
Ṣùgbọ́n wọn yóò máa wí pé, ‘Dájúdájú Olúwa ń bẹ tí ó mú irú-ọmọ ilé Israẹli wá láti ilẹ̀ àríwá àti láti àwọn ilẹ̀ ibi tí mo tí lé wọn lọ,’ wọn ó sì gbé inú ilẹ̀ wọn.”
Nípa ti àwọn wòlíì èké. Ọkàn mi ti bàjẹ́ nínú mi, gbogbo egungun mi ni ó wárìrì. Èmi dàbí ọ̀mùtí ènìyàn, bí ọkùnrin tí ọtí wáìnì ń pa; nítorí Olúwa àti àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀.
“Wòlíì àti àlùfáà kò gbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run; kódà nínú tẹmpili mi ni mo rí ìwà búburú wọn,” ni Olúwa wí.
“Nítorí náà, ọ̀nà wọn yóò di yíyọ́, a ó lé wọn jáde sínú òkùnkùn; níbẹ̀ ni wọn yóò ṣubú. Èmi yóò mú ìdààmú wá sórí wọn, ní ọdún tí a jẹ wọ́n ní ìyà,” ni Olúwa wí.
“Láàrín àwọn wòlíì Samaria, Èmi rí ohun tí ń lé ni sá. Wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ Baali wọ́n sì mú Israẹli ènìyàn mi ṣìnà.
Àti láàrín àwọn wòlíì Jerusalẹmu, èmi ti rí ohun búburú. Wọ́n ṣe panṣágà, wọ́n sì ń ṣèké. Wọ́n fún àwọn olùṣe búburú ní agbára, tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹnìkan tí ó yípadà kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀. Gbogbo wọn dàbí Sodomu níwájú mi, àti àwọn ènìyàn olùgbé rẹ̀ bí Gomorra.”
Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Alágbára wí ní ti àwọn wòlíì: “Èmi yóò mú wọn jẹ oúnjẹ kíkorò, wọn yóò mu omi májèlé nítorí láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì Jerusalẹmu ni àìwà-bí-Ọlọ́run ti tàn ká gbogbo ilẹ̀.”
Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ má ṣe fi etí sí àsọtẹ́lẹ̀ tí àwọn wòlíì èké ń sọ fún un yín. Wọ́n ń kún inú ọkàn yín pẹ̀lú ìrètí asán. Wọ́n ń sọ ìran láti ọkàn ara wọn, kì í ṣe láti ẹnu Olúwa.
Wọ́n ń sọ fún àwọn tí ó ń gàn mí pé, ‘Olúwa ti wí pé, ẹ̀yin ó ní àlàáfíà.’ Wọ́n sì wí fún gbogbo àwọn tí ó rìn nípa agídí ọkàn rẹ̀ pé, ‘Kò sí ìpalára kan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí yín.’
Ṣùgbọ́n èwo nínú wọn ni ó dúró nínú ìgbìmọ̀ Olúwa láti rí i tàbí gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀? Ta ni ó gbọ́ tí ó sì fetí sí ọ̀rọ̀ náà?
Wò ó, afẹ́fẹ́ Olúwa yóò tú jáde pẹ̀lú ìbínú à fẹ́ yíká ìjì yóò fẹ́ sí orí àwọn olùṣe búburú.
Ìbínú Olúwa kì yóò yẹ̀ títí tí yóò sì fi mú èrò rẹ̀ ṣẹ, ní àìpẹ́ ọjọ́, yóò yé e yín yékéyéké.
Èmi kò rán àwọn wòlíì wọ̀nyí síbẹ̀ wọ́n lọ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọn. Èmi kò tilẹ̀ bá wọn sọ̀rọ̀, síbẹ̀ wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀.
Ṣùgbọ́n ì bà ṣe pé wọn dúró nínú ìgbìmọ̀ mi, wọn ìbá ti kéde ọ̀rọ̀ mi fún àwọn ènìyàn mi. Wọn ìbá ti wàásù ọ̀rọ̀ mi fun àwọn ènìyàn wọn ìbá ti yípadà kúrò nínú ọ̀nà àti ìṣe búburú wọn.
“Ǹjẹ́ Ọlọ́run tòsí nìkan ni Èmi bí?” ni Olúwa wí, “kì í sì í ṣe Ọlọ́run ọ̀nà jíjìn.