God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Nígbà náà àwa kí yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ; mú wa yè, àwa o sì máa pe orúkọ rẹ.
Tún wa yípadà, Olúwa Ọlọ́run alágbára; kí ojú rẹ̀ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa, kí á ba à lè gbà wá là.
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti Asafu. Kọrin sókè sí Ọlọ́run agbára wa ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run Jakọbu!
Èyí ni àṣẹ fún Israẹli, àti òfin Ọlọ́run Jakọbu.
Ó fi múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún Josẹfu nígbà tí ó la ilẹ̀ Ejibiti já. Níbi tí a ti gbọ́ èdè tí kò yé wa.
Ó wí pé, “Mo gbé àjàgà kúrò ní èjìká yín, a tú ọwọ́ wọn sílẹ̀ kúrò nínú apẹ̀rẹ̀.
Nínú ìnilára ni ẹ pè mo sì gbà yín là, mo dá a yín lóhùn nínú ìkọ̀kọ̀ àrá, mo dán an yín wò ní odò Meriba. Sela.
“Gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi ó sì kìlọ̀ fún un yín, bí ìwọ bá fetí sí mi, ìwọ Israẹli.
Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti. Ẹ la ẹnu yín gbòòrò, èmi yóò sì kún un.
“Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kì yóò gbọ́ tèmi; Israẹli kò ní tẹríba fún mi.
Nítorí náà ni mo ṣe fi wọ́n fún ọkàn líle wọn láti máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tàn wọn.
“Bí àwọn ènìyàn mi yóò bá gbọ́ tèmi bí Israẹli yóò bá tẹ̀lé ọ̀nà mi,
ní kánkán ni èmi yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn kí n sì yí ọwọ́ mi padà sí ọ̀tá wọn!
Àwọn tí ó kórìíra Olúwa yóò tẹríba níwájú rẹ̀. Ìjìyà wọn yóò sì pẹ́ títí láé.
Ṣùgbọ́n a ó fi ọkà tí ó dára bọ́ ọ yín èmi ó tẹ́ ẹ yín lọ́rùn pẹ̀lú oyin inú àpáta.”
Saamu ti Asafu. Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú ìpéjọpọ̀ ńlá, ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn “ọlọ́run òrìṣà”.
“Mo wí pé, ‘Ẹyin ní “Ọlọ́run òrìṣà”; ẹ̀yin ní gbogbo ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ.’
Dìde, Ọlọ́run, ṣe ìdájọ́ ayé, nítorí gbogbo orílẹ̀-èdè ni ìní rẹ.
Orin. Saamu ti Asafu. Ọlọ́run, má ṣe dákẹ́; má ṣe dákẹ́, Ọlọ́run má ṣe dúró jẹ́ẹ́.
Wo bí àwọn ọ̀tá rẹ ti ń rọ́kẹ̀kẹ̀ lọ, bi àwọn ọ̀tá rẹ ti ń gbé ohùn wọn sókè.
Pẹ̀lú àrékérekè ni wọn dìtẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ; wọn sí dìtẹ̀ mọ́ àwọn tí o fẹ́.
Wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan; wọ́n ṣe àdéhùn láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ
tí ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a gbà ní ìní àní pápá oko tútù Ọlọ́run.”
Ìwọ Ọlọ́run, ṣe wọ́n bí ààjà, bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́.
bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ẹ̀fúùfù líle rẹ lépa wọn dẹ́rùbà wọn lójú pẹ̀lú ìjì rẹ.