God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
O fi òpin sí ayé wọn nínú asán àti ọdún wọn nínú ìpayà.
Nígbàkígbà tí Ọlọ́run bá pa wọ́n, wọn yóò wá a kiri; wọn yóò fi ìtara yípadà sí i.
Wọ́n rántí pé Ọlọ́run ní àpáta wọn; wí pé Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ ni olùràpadà àpáta wọn.
Ṣùgbọ́n nígbà náà ni wọ́n yóò pọ́n ọn pẹ̀lú ẹnu wọ́n wọ́n fi ahọ́n wọ́n purọ́ fún un;
ọkàn wọn kò sòtítọ́ sí i, wọn kò jẹ́ olódodo sí májẹ̀mú rẹ̀.
Síbẹ̀ ó ṣàánú; ó dárí àìṣedéédéé wọn jì òun kò sì pa wọ́n run nígbà púpọ̀ ló ń yí ìbínú rẹ̀ padà kò sì ru ìbínú rẹ̀ sókè
Ó rántí pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n, afẹ́fẹ́ tó ń kọjá tí kò lè padà.
Nígbà gbogbo ní wọn ń ṣọ̀tẹ̀ sí i ní aginjù wọn mú un bínú nínú ilẹ̀ tí ó di ahoro!
Síwájú àti síwájú wọ́n dán Ọlọ́run wò; wọ́n mú ẹni mímọ́ Israẹli bínú.
Wọ́n kò rántí agbára rẹ̀: ní ọjọ́ tí ó rà wọ́n padà lọ́wọ́ àwọn aninilára,
ní ọjọ́ tí ó fi iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ hàn ní Ejibiti, àti iṣẹ́ àmì rẹ̀ ni ẹkùn Ṣoani
Ó mú kíkorò ìbínú rẹ̀ wá sí wọn lára, ìrunú àti ìkáàánú, àti ìpọ́njú, nípa rírán angẹli apanirun sí wọn.
Ó pèsè ipa fún ìbínú rẹ̀, òun kò gbà wọ́n lọ́wọ́ ikú, ṣùgbọ́n ó fi ẹ̀mí wọ́n fún àjàkálẹ̀-ààrùn.
Ṣùgbọ́n ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde bí ọ̀wọ́ ẹran; ó ṣọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú aginjù.
Ó dáàbò bò wọ́n dáradára, nítorí náà ni ẹ̀rù kò ṣe bà wọ́n ṣùgbọ́n òkun padé mọ́ àwọn ọ̀tá wọn.
Bákan náà ni ó mú wọn wá sí etí ilẹ̀ mímọ́ rẹ̀ òkè tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ti gbà
Ṣùgbọ́n wọn dán Ọlọ́run wò wọn sì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo; wọn kò pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
Wọ́n bí i nínú pẹ̀lú ibi gíga wọn; wọn rú owú rẹ̀ sókè nípa òrìṣà wọn.
Nígbà tí Ọlọ́run gbọ́ wọn, inú bí i gidigidi; ó kọ Israẹli pátápátá.
Ó kọ àgọ́ Ṣilo sílẹ̀, àgọ́ tí ó ti gbé kalẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn.
Ó rán àpótí ẹ̀rí, agbára rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn, dídán ògo rẹ̀ lọ sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá.
Ó fi àwọn ènìyàn rẹ̀ lé idà lọ́wọ́, ó sì bínú sí àwọn ohun ìní rẹ̀.
Olúwa sì jí gẹ́gẹ́ bí ẹni ojú oorun, gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ti i jí kúrò nínú ìraníyè ọtí.
Ó kọlu àwọn ọ̀tá rẹ̀ padà; ó fi wọn sínú ìtìjú ayérayé.
Nígbà náà ni ó kọ́ àgọ́ Josẹfu, kò sì yan ẹ̀yà Efraimu,