Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àrá rẹ̀ ni a gbọ́ nínú ìjì, ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ sí gbogbo ayé; ayé bẹ̀rù, wọ́n sì wárìrì.

  2. Ipa rẹ̀ gba Òkun, ọ̀nà rẹ̀ ń bẹ nínú Òkun, ọ̀nà la omi alágbára kọjá ipa rẹ̀ ń bẹ nínú líla omi alágbára kọjá, nítòótọ́ a kò rí ojú ẹsẹ̀ rẹ̀.

  3. Ó tọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran nípa ọwọ́ Mose àti Aaroni.

  4. Àwa kì yóò pa wọ́n mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ, ní fífi ìyìn Olúwa, àti ipa rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hàn fún ìran tí ń bọ̀.

  5. Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jakọbu o sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Israẹli, èyí tí ó pàṣẹ fún àwọn baba ńlá wa láti kọ́ àwọn ọmọ wọn,

  6. Nígbà náà ni wọ́n ò fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú Ọlọ́run wọn kò sì ní gbàgbé iṣẹ́ Ọlọ́run ṣùgbọ́n wọn ó pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.

  7. Kí wọn kí ó má ṣe dàbí àwọn baba ńlá wọn, ìran alágídí àti ọlọ́tẹ̀, ìran tí ọkàn wọn kò ṣọ òtítọ́ si olóore, àti ẹ̀mí ẹni tí kò bá Ọlọ́run dúró ṣinṣin.

  8. Wọn kò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́ wọn sì kọ̀ láti máa gbé nínú òfin rẹ̀.

  9. Wọ́n gbàgbé ohun tí ó ti ṣe, àwọn ìyanu tí ó ti fihàn wọ́n.

  10. Ó ṣe ìyanu níwájú àwọn baba wọn ní ilẹ̀ Ejibiti, ní agbègbè Ṣoani.

  11. Ó pín òkun ní yà, ó sì mú wọn kọjá Ó mù kí omi náà dúró bi odi gíga.

  12. Ní ọ̀sán, ó fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ ṣe amọ̀nà wọn àti ní gbogbo òru pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ iná.

  13. Wọ́n sì tún tẹ̀síwájú láti dẹ́ṣẹ̀ sí i ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo ní aginjù.

  14. Wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ dán Ọlọ́run wò nípa bíbéèrè fún oúnjẹ tí wọn bẹ̀bẹ̀ fún.

  15. Wọ́n sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, wí pé “Ọlọ́run ha lè tẹ́ tábìlì ní aginjù?

  16. Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde, odò sì sàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹ ó ha le pèsè ẹran fún àwọn ènìyàn rẹ̀?”

  17. Nígbà tí Olúwa gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi; iná rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sí Jakọbu, ìbínú rẹ̀ sì rú sí Israẹli,

  18. nítorí wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́, wọn kò sì gbẹ́kẹ̀lé ìgbàlà rẹ̀.

  19. Síbẹ̀ ó pàṣẹ fún ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀;

  20. Àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn angẹli; Ó fún wọn ní oúnjẹ ní àjẹyó,

  21. Ó mú afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn láti ọ̀run wá ó mú afẹ́fẹ́ gúúsù wá nípa agbára rẹ̀.

  22. Ó jẹ́ kí wọn jáde ní ibùdó wọn, yíká àgọ́ wọn.

  23. Wọ́n jẹ, wọ́n sì yó jọjọ nítorí ó ti fún wọn ní ohun tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún.

  24. ìbínú Ọlọ́run dìde sí wọn ó pa àwọn tí ó jùlọ nínú wọn, ó sì lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Israẹli bolẹ̀.

  25. Nínú gbogbo ìwọ̀nyí, wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ síwájú; nínú gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, wọ́n kò gbàgbọ́.