God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóò ṣègbé ìwọ ti pa gbogbo wọn run; tí ń ṣe àgbèrè kiri kúrò lọ́dọ̀ rẹ.
Ṣùgbọ́n ní ti èmi, ó dára láti súnmọ́ Ọlọ́run. Èmi ti fi Olúwa Olódùmarè ṣe ààbò mi; kí èmi ó lè máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ.
Maskili ti Asafu. Ọlọ́run, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ wá sílẹ̀ títí láé? Èéṣe tí ìbínú rẹ̀ fi dìde sí àwọn àgùntàn pápá rẹ?
Rántí àwọn ènìyàn tí ìwọ ti rà nígbà àtijọ́, ẹ̀yà ilẹ̀ ìní rẹ, tí ìwọ ti rà padà. Òkè Sioni, níbi tí ìwọ ń gbé.
Yí ẹsẹ̀ rẹ padà sí ìparun ayérayé wọn, gbogbo ìparun yìí tí ọ̀tá ti mú wá sí ibi mímọ́.
Àwọn ọ̀tá rẹ ń bú ramúramù láàrín ènìyàn rẹ, wọ́n ń gbé àsíá wọn sókè fún àmì.
Wọ́n sun ibi mímọ́ rẹ lulẹ̀ wọ́n ba ibùgbé orúkọ rẹ jẹ́.
Wọ́n wí ní ọkàn wọn. “Àwa ó run wọ́n pátápátá!” Wọ́n sun gbogbo ibi ìjọ́sìn Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà.
Àwọn ọ̀tá yóò ti kùn sí ọ pẹ́ tó, Ọlọ́run? Àwọn ọ̀tá yóò ha ba orúkọ rẹ jẹ́ títí láé?
Èéṣe tí ìwọ fi dá ọwọ́ rẹ dúró, ọwọ́ ọ̀tún rẹ? Mú un kúrò nínú ìṣẹ́po aṣọ rẹ kí o sì run wọ́n!
Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run ni ọba mi láti ìgbà pípẹ́; Ó mú ìgbàlà wá sórí ilẹ̀ ayé.
Ìwọ ni ó la òkun sílẹ̀ nípa agbára rẹ; ìwọ fọ́ orí ẹ̀mí búburú nínú omi.
Ìwọ ya orísun omi àti ìṣàn omi; Ìwọ mú kí odò tó ń sàn gbẹ.
Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ ni òru pẹ̀lú; ìwọ yà oòrùn àti òṣùpá.
Ìwọ pààlà etí ayé; Ìwọ dá ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù.
Rántí bí àwọn ọ̀tá ń kẹ́gàn rẹ, Olúwa bí àwọn aṣiwèrè ènìyàn ti ń ba orúkọ rẹ jẹ́.
Má ṣe fi ẹ̀mí àdàbà rẹ fún ẹranko igbó búburú; má ṣe gbàgbé ẹ̀mí àwọn ènìyàn rẹ tí a ń pọ́n lójú títí láé.
Má ṣe jẹ́ kí àwọn aninilára padà sẹ́yìn nínú ìtìjú jẹ́ kí àwọn aláìní àti tálákà yin orúkọ rẹ.
Dìde, Ọlọ́run, gba ẹjọ́ ara rẹ rò; rántí bí àwọn aṣiwèrè ti ń kẹ́gàn rẹ ní gbogbo ọjọ́.
Má ṣe gbàgbé ohùn àwọn ọ̀tá rẹ, bíbú àwọn ọ̀tá rẹ, tí ó ń pọ̀ sí i nígbà gbogbo.
Fún adarí orin. Tí ohùn, “Má ṣe parun.” Saamu ti Asafu. Orin. A fi ìyìn fún ọ, Ọlọ́run, a yìn ọ́, nítorí orúkọ rẹ súnmọ́ tòsí; àwọn ènìyàn ń sọ ti ìyanu rẹ.
Ìwọ wí pé, “Mo yan àkókò ìyàsọ́tọ̀; Èmi ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ òdodo.
Nígbà tí ayé àti àwọn ènìyàn ibẹ̀ wárìrì, Èmi ni mo di òpó rẹ̀ mú ṣinṣin.
Èmí wí fún àwọn agbéraga pé, ẹ má ṣe gbéraga mọ́; àti sí ènìyàn búburú; ẹ má ṣe gbé ìwo yín sókè.
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni olùdájọ́; Ó ń rẹ ẹnìkan sílẹ̀, ó sì ń gbé ẹlòmíràn ga.