Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí ẹni tí ìwọ ti lù, àti ìrora àwọn tí ó ti ṣèṣe.

  2. Fi ẹ̀sùn kún ẹ̀sùn wọn; Má ṣe jẹ́ kí wọn pín nínú ìgbàlà rẹ.

  3. Ṣùgbọ́n tálákà àti ẹni-ìkáàánú ni èmí, Ọlọ́run, jẹ́ kí ìgbàlà rẹ gbé mi lékè.

  4. Èmi yóò fi orin gbé orúkọ Ọlọ́run ga èmi yóò fi ọpẹ́ gbé orúkọ rẹ̀ ga.

  5. Eléyìí tẹ́ Olúwa lọ́rùn ju ọ̀dá màlúù lọ ju akọ màlúù pẹ̀lú ìwo rẹ̀ àti bàtà rẹ̀.

  6. Àwọn òtòṣì yóò rí, wọn yóò sì yọ̀: ẹ̀yin yóò wá Ọlọ́run, ọkàn yín yóò sì wà láààyè!

  7. Olúwa, gbọ́ ti aláìní, kì ó sì kọ àwọn ìgbèkùn sílẹ̀.

  8. Kí ọ̀run àti ayé yìn ín, òkun àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀,

  9. nítorí tí Ọlọ́run yóò gba Sioni là yóò sì tún àwọn ìlú Juda wọ̀nyí kọ́. Kí wọn ó lè máa gbé ibẹ̀, kí wọn ó lè máa ní ní ilẹ̀ ìní;

  10. àwọn ọmọ ọmọ ọ̀dọ̀ ni yóò máa jogún rẹ̀, àwọn tí ó fẹ́ orúkọ rẹ ni yóò máa gbé inú rẹ̀.

  11. Fún adarí orin. Ti Dafidi. Ẹ̀bẹ̀. Yára, Ọlọ́run, láti gbà mí là, Olúwa, wá kánkán láti ràn mí lọ́wọ́.

  12. Ṣùgbọ́n kí àwọn tí ó ń wá ọ ó máa yọ̀ kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa rẹ, kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà rẹ máa wí pé, “Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!”

  13. Ṣùgbọ́n mo jẹ́ òtòṣì àti aláìní; wa kánkán sí ọ̀dọ̀ mi, Ọlọ́run. Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àti olùdáǹdè mi; Olúwa, má ṣe dúró pẹ́.

  14. Nínú rẹ, Olúwa, ni mo ní ààbò; má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.

  15. Gbà mí kí o sì tú mi sílẹ̀ nínú òdodo rẹ; dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbà mí.

  16. Jẹ́ àpáta ààbò mi, níbi tí èmi lè máa lọ, pa àṣẹ láti gbà mí, nítorí ìwọ ni àpáta àti odi agbára mi.

  17. Gbà mí, Ọlọ́run mi, lọ́wọ́ àwọn olùṣe búburú, ní ọwọ́ aláìṣòdodo àti ìkà ọkùnrin.

  18. Nítorí ìwọ jẹ́ ìrètí mi, Olúwa Olódùmarè, ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi láti ìgbà èwe.

  19. Mo gbẹ́kẹ̀lé ọ láti ìgbà ìbí mi; Ìwọ mú mi jáde láti inú ìyá mi wá èmi ó máa yìn ọ́ títí láé.

  20. Mo di àmì fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.

  21. Ìyìn rẹ̀ kún ẹnu mi, ó ń sọ ti ọlá rẹ ní ọjọ́ gbogbo.

  22. Wọ́n wí pé, “Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀; lépa rẹ̀ kí ẹ sì mu, nítorí kò sí ẹni tí yóò gbà á.”

  23. Má ṣe jìnnà sí mi, Ọlọ́run; wa kánkán, Ọlọ́run mi, láti ràn mí lọ́wọ́.

  24. Ṣùgbọ́n ní tèmi, ìgbà gbogbo ní ìrètí mi; èmi ó yìn ọ́ síwájú àti síwájú sí i.

  25. Ẹnu mi yóò sọ nípa ti òdodo rẹ, ti ìgbàlà rẹ, ni gbogbo ọjọ́, lóòtítọ́, èmi kò mọ iye rẹ̀.