Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbọ́ nítòótọ́ ó ti gbọ́ ohùn mi nínú àdúrà.

  2. Ìyìn ni fún Ọlọ́run ẹni tí kò kọ àdúrà mi tàbí mú ìfẹ́ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi!

  3. Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu. Orin. Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa kí ó sì bùkún fún wa, kí ó sì jẹ́ kí ojú rẹ̀ tàn yí wa ká,

  4. kí ọ̀nà rẹ le di mí mọ̀ ní ayé, ìgbàlà rẹ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

  5. Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run; kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́!

  6. Kí orílẹ̀-èdè kí ó yọ̀, kí ó sì kọrin fún ayọ̀, nítorí ìwọ fi òdodo darí àwọn ènìyàn, ìwọ sì jẹ ọba àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé.

  7. Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run; kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́. Sela.

  8. Nígbà náà ní ilẹ̀ yóò mú ìkórè rẹ̀ wá, Ọlọ́run, Ọlọ́run wa, yóò bùkún fún wa.

  9. Ọlọ́run yóò bùkún fún wa, àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì máa bẹ̀rù rẹ̀.

  10. Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Orin. Kí Ọlọ́run kí ó dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó fọ́nká; kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó sá níwájú rẹ̀.

  11. Bí ìjì ti ń fẹ́ èéfín lọ, kí ó fẹ́ wọn lọ; bí ìda ti í yọ́ níwájú iná, kí olùṣe búburú ṣègbé níwájú Ọlọ́run.

  12. Ṣùgbọ́n kí inú olódodo kí ó dùn kí ó sì kún fún ayọ̀ níwájú Ọlọ́run; kí inú wọn kí ó dùn, kí ó sì kún fún ayọ̀.

  13. Ẹ kọrin sí Ọlọ́run, ẹ kọrin ìyìn sí i, ẹ la ọ̀nà fún ẹni tí ń rékọjá ní aginjù. Olúwa ni orúkọ rẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀.

  14. Baba àwọn aláìní baba àti onídàájọ́ àwọn opó ni Ọlọ́run ní ibùgbé rẹ̀ mímọ́

  15. Ọlọ́run gbé aláìlera kalẹ̀ nínú ìdílé, ó darí àwọn ẹlẹ́wọ̀n pẹ̀lú orin, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ní ń gbé nínú ilẹ̀ gbígbẹ.

  16. Nígbà tí ìwọ bá jáde lónìí níwájú àwọn ènìyàn rẹ, Ọlọ́run, tí ń kọjá lọ láàrín aginjù, Sela.

  17. Ilẹ̀ mì títí, àwọn ọ̀run ń rọ òjò jáde, níwájú Ọlọ́run, ẹni Sinai, níwájú Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli.

  18. Ìwọ fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò, Ọlọ́run; ìwọ tu ilẹ̀ ìní rẹ̀ lára nígbà tí ó rẹ̀ ẹ́ tan.

  19. Àwọn ènìyàn rẹ tẹ̀dó síbẹ̀ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní rẹ, Ọlọ́run, ìwọ pèsè fún àwọn aláìní.

  20. Olúwa ti pàṣẹ ọ̀rọ̀, púpọ̀ ní ogun àwọn ẹni tí ó ń ròyìn rẹ̀.

  21. Nígbà tí Olódùmarè fọ́n àwọn ọba ká ní ilẹ̀ náà, ó dàbí òjò dídi ní Salmoni.

  22. Òkè Baṣani jẹ́ òkè Ọlọ́run; òkè tí ó ní orí púpọ̀ ni òkè Baṣani.

  23. Kí ló dé tí ẹ̀yin fi ń ṣe ìlara, ẹ̀yin òkè wúwo, òkè tí Ọlọ́run ti fẹ́ láti jẹ ọba níbi tí Olúwa fúnra rẹ̀ yóò máa gbé títí láé?

  24. Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ni kẹ̀kẹ́ ogun Ọlọ́run ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún; Olúwa ń bẹ láàrín wọn, ní Sinai ni ibi mímọ́ rẹ̀.

  25. Ìwọ ti gòkè sí ibi gíga ìwọ ti di ìgbèkùn ní ìgbèkùn lọ; ìwọ ti gba ẹ̀bùn fún ènìyàn: nítòótọ́, fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ pẹ̀lú, kí Olúwa Ọlọ́run lè máa bá wọn gbé.