Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Olùgbàlà wa, ẹni tí ó ń fi ojoojúmọ́ gba ẹrù wa rù. Sela.

  2. Ọlọ́run wa jẹ́ Ọlọ́run tó ń gbàlà àti sí Olúwa Olódùmarè ni ó ń gbà wá lọ́wọ́ ikú.

  3. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò tẹ orí àwọn ọ̀tá rẹ̀, àti agbárí onírun àwọn tó ń tẹ̀síwájú nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn

  4. Olúwa wí pé, “Èmi ó mú wọn wá láti Baṣani; èmi ó mú wọn wá láti ibú omi Òkun,

  5. Wọ́n ti rí ìrìn rẹ, Ọlọ́run, ìrìn Ọlọ́run mi àti ọba mi ní ibi mímọ́ rẹ̀.

  6. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa ní ẹgbẹgbẹ́; àní fún Olúwa ẹ̀yin tí ó ti orísun Israẹli wá.

  7. Pàṣẹ agbára rẹ, Ọlọ́run; fi agbára rẹ hàn wá, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe ní ìṣáájú.

  8. Nítorí tẹmpili rẹ ni Jerusalẹmu àwọn ọba yóò mú ẹ̀bùn wá fún ọ.

  9. Bá àwọn ẹranko búburú wí, tí ń gbé láàrín eèsún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akọ màlúù pẹ̀lú àwọn ọmọ màlúù títí olúkúlùkù yóò fi foríbalẹ̀ pẹ̀lú ìwọ̀n fàdákà: tú àwọn ènìyàn tí ń ṣe inú dídùn sí ogun ká.

  10. Àwọn ọmọ-aládé yóò wá láti Ejibiti; Etiopia yóò na ọwọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run.

  11. Kọrin sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ìjọba ayé, kọrin ìyìn sí Olúwa, Sela.

  12. Sí ẹni tí ń gun ọ̀run dé ọ̀run àtijọ́ lókè, tó ń fọhùn rẹ̀, ohùn ńlá.

  13. Kéde agbára Ọlọ́run, ọláńlá rẹ̀ wà lórí Israẹli, tí agbára rẹ̀ wà lójú ọ̀run.

  14. Ìwọ ní ẹ̀rù, Ọlọ́run, ní ibi mímọ́ rẹ; Ọlọ́run Israẹli fi agbára àti okun fún àwọn ènìyàn rẹ. Olùbùkún ní Ọlọ́run!

  15. Fún adarí orin. Tí ohùn “Àwọn Lílì.” Ti Dafidi. Gbà mí, Ọlọ́run, nítorí omi ti kún dé ọrùn mi.

  16. Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́; ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú, nígbà tí èmi dúró de Ọlọ́run mi.

  17. Ìwọ mọ òmùgọ̀ mi, Ọlọ́run; ẹ̀bi mi kò pamọ́ lójú rẹ.

  18. Má ṣe dójútì àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ nítorí mi, Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun; má ṣe jẹ́ kí àwọn tó ń wá ọ dààmú nítorí mi, Ọlọ́run Israẹli.

  19. Nítorí rẹ ni mo ń ru ẹ̀gàn, ìtìjú sì bo ojú mi.

  20. nítorí ìtara ilé rẹ jẹ mí run, àti ẹ̀gàn àwọn tí ń gàn ọ́ ṣubú lù mí.

  21. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni ìwọ ni èmi ń gbàdúrà mi sí Olúwa, ní ìgbà ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, nínú ìfẹ́ títóbi rẹ, dá mi lóhùn pẹ̀lú ìgbàlà rẹ tí ó dájú.

  22. Dá mí lóhùn, Olúwa, nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ; nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ yípadà sí mi.

  23. Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ: yára dá mi lóhùn, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú.

  24. Ìwọ ti mọ ẹ̀gàn mi, ìtìjú mi àti àìlọ́lá; gbogbo àwọn ọ̀tá mi wà níwájú rẹ.

  25. Tú ìbínú rẹ jáde sí wọn; kí ìbínú gbígbóná rẹ bò wọ́n mọ́lẹ̀.