God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Ní ọwọ́ Olúwa ni ago kan wà, ọtí wáìnì náà sì pọ́n, ó kún fún àdàlú, ó fún ọtí àdàlú tí a pò mọ́ òórùn dídùn tí ó tú jáde, àwọn ènìyàn búburú ayé gbogbo mú u pátápátá.
Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn rẹ títí láé; èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jakọbu.
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Asafu. Orin. Ní Juda ni a mọ Ọlọ́run; orúkọ rẹ̀ sì lágbára ní Israẹli
Àgọ́ rẹ̀ wà ní Salẹmu, ibùgbé rẹ̀ ni Sioni.
Níbẹ̀ ni ó ṣẹ́ ọfà, asà àti àwọn idà, ohun ìjà ogun. Sela.
Ní ìfibú rẹ, Ọlọ́run Jakọbu, àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀.
Ìwọ nìkan ni ó yẹ kí a bẹ̀rù. Ta ló lé dúró níwájú rẹ, nígbà tí ìwọ bá ń bínú?
nígbà tí, ìwọ Ọlọ́run, bá dìde láti ṣe ìdájọ́, láti gba àwọn ẹni ìnilára ilẹ̀ náà. Sela.
Lóòótọ́, ìbínú rẹ sí àwọn ènìyàn ń mú ìyìn wá fún ọ, ẹni tí ó yọ nínú ìbínú rẹ ní a dá nígbà tí ìwọ bá fi ìbínú ìyókù di ara rẹ ni àmùrè.
Jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì mú un ṣẹ; kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká mú ẹ̀bùn wá fún ẹni tí ó tọ́ láti bẹ̀rù.
Ó ké ẹ̀mí àwọn aládé kúrò; àwọn ọba ayé sì ń bẹ̀rù rẹ̀.
Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Ti Asafu. Saamu. Mó kígbe sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́; mo kígbe sí Ọlọ́run láti gbọ́ tèmi.
Nígbà tí mo wà nínú ìpọ́njú, mo wá Olúwa; ní òru ni mo na ọwọ́ mi jáde ní àìkáárẹ̀ ọkàn mí sì kọ̀ láti tù ú nínú.
Èmi rántí rẹ, Ọlọ́run, mo sì kẹ́dùn; mo ṣe àròyé, ẹ̀mí mi sì rẹ̀wẹ̀sì. Sela.
“Olúwa yóò ha kọ̀ títí láé? Ki yóò ha ṣe ojúrere rẹ̀ mọ́?
Ṣe ìfẹ́ rẹ̀ àti àánú rẹ̀ ti kú lọ láéláé? Ìlérí rẹ̀ ha kùnà títí ayé?
Ọlọ́run ha gbàgbé láti máa ṣàánú? Ní ìbínú rẹ̀, ó ha sé ojúrere rẹ̀ mọ́?” Sela.
Èmi wí pé, “Èyí ní ẹ̀dùn ọkàn mi, pé ọwọ́ ọ̀tún Ọ̀gá-ògo jùlọ ti yípadà”.
Èmi ó rántí iṣẹ́ Olúwa: bẹ́ẹ̀ ni, èmi ó rántí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ọjọ́ pípẹ́.
Èmi ṣàṣàrò lórí iṣẹ́ rẹ gbogbo, pẹ̀lú, ènìyàn sì máa sọ̀rọ̀ gbogbo iṣẹ́ agbára rẹ.
Ọlọ́run, ọ̀nà rẹ jẹ́ mímọ́. Ọlọ́run wo ni ó sì tóbi bí Ọlọ́run wa?
Ìwọ ni Ọlọ́run tó ń ṣe ìyanu; ìwọ fi agbára rẹ hàn nínú àwọn ènìyàn.
Pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ ni ìwọ ra àwọn ènìyàn padà, àwọn ọmọ Jakọbu àti Josẹfu. Sela.
Nígbà tí àwọn omi rí Ọlọ́run, nígbà tí àwọn omi rí ọ, ẹ̀rù bà wọ́n, nítòótọ́ ara ibú kò balẹ̀.
Àwọn ojú ọ̀run tú omi sílẹ̀, àwọsánmọ̀ fi àrá dáhùn; ọfà rẹ̀ ń tàn sẹ́yìn àti síwájú.