Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ó fi ìmọ́lẹ̀ bo ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì ó sì rán an sí ẹni olódì.

  2. Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀, kí ẹ sì gbọ́ ìró ohùn rẹ̀, àti èyí tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde wá.

  3. Ó ṣe ìlànà rẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ọ̀run gbogbo, mọ̀nàmọ́ná rẹ̀ ni ó sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ dé òpin ilẹ̀ ayé.

  4. Lẹ́yìn mọ̀nàmọ́ná ohùn kan fọ̀ ramúramù; ó sì fi ohùn ọláńlá rẹ̀ sán àrá. Òhun kì yóò sì dá àrá dúró, nígbà tí ó bá ń gbọ́ ohùn rẹ̀.

  5. Ọlọ́run fi ohùn rẹ̀ sán àrá ní ọ̀nà ìyanu; ohùn ńlá ńlá ni í ṣe tí àwa kò le mọ̀.

  6. Nítorí tí ó wí fún yìnyín pé, ‘Ìwọ rọ̀ sílẹ̀ ayé,’ àti pẹ̀lú fún ọwọ́ òjò, ‘Fún òjò ńlá agbára rẹ̀.’

  7. Ó fi èdìdì di ọwọ́ gbogbo ènìyàn kí gbogbo wọn kí ó lè mọ iṣẹ́ rẹ̀, ó sì tún dá olúkúlùkù ènìyàn dúró lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀.

  8. Nípa ẹ̀mí Ọlọ́run a fi ìdí omi fún ni, ibú omi á sì súnkì.

  9. Pẹ̀lúpẹ̀lú ó fi omi púpọ̀ mú àwọsánmọ̀ wúwo, a sì tú àwọsánmọ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ká ara wọn.

  10. Àwọn wọ̀nyí yí káàkiri nípa ìlànà rẹ̀, kí wọn kí ó lè ṣe ohunkóhun tí ó pàṣẹ fún wọn lórí ilẹ̀ ayé.

  11. Ó mú àwọsánmọ̀ wá, ìbá ṣe fún ìkìlọ̀, tàbí omi wá sí ayé láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.

  12. “Jobu, dẹtí sílẹ̀ sí èyí; dúró jẹ́ẹ́ kí o sì ro iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run.

  13. Ṣe ìwọ mọ àkókò ìgbà tí Ọlọ́run ṣe wọ́n lọ́jọ̀, tí ó sì mú ìmọ́lẹ̀ àwọsánmọ̀ rẹ̀ dán?

  14. Ṣé ìwọ mọ ìgbà tí àwọsánmọ̀ í fò lọ, iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀?

  15. Ìwọ ẹni ti aṣọ rẹ̀ ti máa n gbóná, nígbà tí ó fi atẹ́gùn ìhà gúúsù mú ayé dákẹ́.

  16. Ìwọ ha ba tẹ́ pẹpẹ ojú ọ̀run, tí ó dúró ṣinṣin, tí ó sì dàbí dígí tí ó yọ̀ dà?

  17. “Kọ́ wa ní èyí tí a lè wí fún un; nítorí pé àwa kò le wádìí ọ̀rọ̀ náà nítorí òkùnkùn wa.

  18. A ó ha wí fún un pé, èmi fẹ́ sọ̀rọ̀? Tàbí ẹnìkan lè wí pé, ìfẹ́ mi ni pé kí a gbé mi mì?

  19. Wúrà dídán ti inú ìhà àríwá jáde wá; lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ọláńlá ẹ̀rù ńlá wa.

  20. Nípa ti Olódùmarè àwa kò le wádìí rẹ̀, ó rékọjá ní ipá; nínú ìdájọ́ àti títí bi òun kì í ba ẹ̀tọ́ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òtítọ́ jẹ́.

  21. Nítorí náà ènìyàn ha máa bẹ̀rù rẹ̀, òun kì í ṣe ojú sájú ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́n ní ayé?”

  22. Nígbà náà ní Olúwa dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àjàyíká wá, ó sì wí pé,

  23. Di ẹ̀gbẹ́ ara rẹ ní àmùrè bí ọkùnrin nísinsin yìí, nítorí pé èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ kí o sì dá mi lóhùn.

  24. “Níbo ni ìwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀? Wí bí ìwọ bá mòye.

  25. nígbà náà àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ jùmọ̀ kọrin pọ̀, tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run hó ìhó ayọ̀?