Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà tí mo fi àwọsánmọ̀ ṣe aṣọ rẹ̀, tí mo sì fi òkùnkùn biribiri ṣe ọ̀já ìgbà inú rẹ̀.

  2. Nígbà tí mo ti pàṣẹ ìpinnu mi fún un, tí mo sì ṣe bèbè àti ìlẹ̀kùn.

  3. tí mo ti fi pamọ́ de ìgbà ìyọnu, dé ọjọ́ ogun àti ìjà?

  4. Ta ni ó ń pèsè ohun jíjẹ fún ẹyẹ ìwò, nígbà tí àwọn ọmọ rẹ ń ké pe Ọlọ́run, tí wọ́n sì máa ń fò kiri nítorí àìní ohun jíjẹ?

  5. èyí tí mo fi aginjù ṣe ilé fún, àti ilẹ̀ iyọ̀ ní ibùgbé rẹ̀.

  6. nítorí pé Ọlọ́run kò fún un ní ọgbọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi ìpín òye fún un.

  7. Olúwa dá Jobu lóhùn sí pẹ̀lú, ó sì wí pé,

  8. “Ẹni tí ń bá Olódùmarè wíjọ́ yóò ha kọ ní ẹ̀kọ́? Ẹni tí ń bá Ọlọ́run wí jẹ́ kí ó dáhùn!”

  9. Nígbà náà ni Jobu dá Olúwa lóhùn wá ó sì wí pé,

  10. “Kíyèsi i, ẹ̀gbin ni èmi—ohun kí ni èmi ó dà? Èmi ó fi ọwọ́ mi le ẹnu mi.

  11. Nígbà náà ní Olúwa dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àyíká wá, ó sì wí pé,

  12. “Di àmùrè gírí ní ẹgbẹ́ rẹ bí ọkùnrin, èmi ó bi ọ léèrè, kí ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.

  13. “Ìwọ ha fẹ́ mú ìdájọ́ mi di asán? Ìwọ ó sì dá mi lẹ́bi, kí ìwọ lè ṣe olódodo.

  14. Ìwọ ni apá bí Ọlọ́run tàbí ìwọ lè fi ohùn sán àrá bí òun?

  15. Nígbà náà ní èmi ó yìn ọ́ pé, ọwọ́ ọ̀tún ara rẹ lè gbà ọ́ là.

  16. “Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi Behemoti, tí mo dá pẹ̀lú rẹ, òun a máa jẹ koríko bí ọ̀dá màlúù.

  17. Òun ni olórí nínú àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run; síbẹ̀ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ fi idà rẹ̀ lé e lọ́wọ́.

  18. Kò sí ẹni aláyà lílé tí ó lè ru sókè. Ǹjẹ́ ta ni ó lè dúró níwájú mi.

  19. Ta ni ó kọ́kọ́ ṣe fún mi, tí èmi ìbá fi san án fún un? Ohunkóhun ti ń bẹ lábẹ́ ọ̀run gbogbo, tèmi ni.

  20. “Èmi kì yóò fi ẹ̀yà ara Lefitani, tàbí ipá rẹ, tàbí ìhámọ́ra rẹ tí ó ní ẹwà pamọ́.

  21. Nígbà náà ní Jobu dá Olúwa lóhùn, ó sì wí pé,

  22. “Èmi mọ̀ pé, ìwọ lè e ṣe ohun gbogbo, àti pé, kò si ìrò inú tí a lè fa sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ.

  23. “Ìwọ wí pé, ‘Gbọ́ tèmi báyìí, èmi ó sì sọ; èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, ìwọ yóò sì dá mi lóhùn.’

  24. Etí mi sì ti gbọ́ nípa rẹ, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ojú mi ti rí ọ.

  25. Bẹ́ẹ̀ ó sì rí, lẹ́yìn ìgbà tí Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Jobu, Olúwa sì wí fún Elifasi, ará Temani pé, mo bínú sí ọ, àti sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ méjèèjì, nítorí pé ẹ̀yin kò sọ̀rọ̀, ní ti èmi, ohun tí ó tọ́, bí Jobu ìránṣẹ́ mi ti sọ.