Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Mo bá wọn wí mo sì gégùn ún lé wọn lórí. Mo lu àwọn ènìyàn díẹ̀ nínú wọn mo sì fa irun orí wọn tu. Mo mú kí wọn búra ní orúkọ Ọlọ́run, kí wọn wí pé, “Ẹ̀yin kì yóò fi àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín ní ìyàwó tàbí fún ẹ̀yin tìkára yín.

  2. Kì í ha á ṣe àwọn ìgbéyàwó bí irú èyí ni ọba Solomoni fi dá ẹ̀ṣẹ̀? Láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, kò sí ọba kan bí i tirẹ̀. Ọlọ́run rẹ̀ fẹ́ràn rẹ̀, Ọlọ́run sì fi jẹ ọba lórí i gbogbo Israẹli, ṣùgbọ́n àwọn obìnrin àjèjì ti sọ ọ́ sínú òfin ẹ̀ṣẹ̀.

  3. Ǹjẹ́ ó ha yẹ kí àwa tún gbọ́ báyìí pé ẹ̀yin náà tún ń ṣe àwọn nǹkan tí ó burú jọjọ wọ̀nyí tí ẹ sì ń ṣe aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wa nípa fífẹ́ àwọn obìnrin àjèjì?”

  4. Rántí wọn, Ọlọ́run mi, nítorí wọ́n ti ba iṣẹ́ àlùfáà jẹ́ pẹ̀lú májẹ̀mú iṣẹ́ àlùfáà àti ti àwọn Lefi.

  5. Mo sì tún pèsè fún ọrẹ, igi—pákó ní àkókò tí a yàn àti fún àwọn èso àkọ́so. Rántí mi fún rere, Ọlọ́run mi.

  6. Ọkùnrin kan wà ní ilẹ̀ Usi, orúkọ ẹni tí í jẹ́ Jobu; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́, ó dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó kórìíra ìwà búburú.

  7. Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ àsè wọn pé yíká, ni Jobu ránṣẹ́ lọ í yà wọ́n sí mímọ́, ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì rú ẹbọ sísun níwọ̀n iye gbogbo wọn; nítorí tí Jobu wí pé: bóyá àwọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣọpẹ́ fún Ọlọ́run lọ́kàn wọn. Bẹ́ẹ̀ ní Jobu máa ń ṣe nígbà gbogbo.

  8. Ǹjẹ́ ó di ọjọ́ kan, nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run wá í pé níwájú Olúwa, Satani sì wá pẹ̀lú wọn.

  9. Olúwa sì bi Satani wí pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Nígbà náà ní Satani dá Olúwa lóhùn wí pé, “Ní ìlọsíwá-sẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀.”

  10. Olúwa sì sọ fún Satani pé, “Ìwọ ha kíyèsi Jobu ìránṣẹ́ mi, pé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí í ṣe olóòtítọ́, tí ó sì dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti ó sì kórìíra ìwà búburú.”

  11. Nígbà náà ni Satani dá Olúwa lóhùn wí pé, “Jobu ha bẹ̀rù Ọlọ́run ní asán bí?”

  12. “Ìwọ kò ha ti ṣọgbà yìí ká, àti yí ilé rẹ̀ àti yí ohun tí ó ní ká, ní ìhà gbogbo? Ìwọ bùsi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì ń pọ̀ si ní ilẹ̀.

  13. Ǹjẹ́, nawọ́ rẹ nísinsin yìí, kí ó sì fi tọ́ ohun gbogbo tí ó ni; bí kì yóò sì bọ́hùn ni ojú rẹ.”

  14. Olúwa sì dá Satani lóhùn wí pé, “Kíyèsi i, ohun gbogbo tí ó ní ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ, kìkì òun tìkára rẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ rẹ kàn.” Bẹ́ẹ̀ ni Satani jáde lọ kúrò níwájú Olúwa.

  15. Bí ó ti ń sọ ní ẹnu; ẹnìkan dé pẹ̀lú tí ó sì wí pé, “Iná ńlá Ọlọ́run ti ọ̀run bọ́ sí ilẹ̀, ó sì jó àwọn àgùntàn àti àwọn ìránṣẹ́; èmi nìkan ṣoṣo ní ó sálà láti ròyìn fún ọ.”

  16. wí pé, “Ní ìhòhò ní mo ti inú ìyá mi jáde wá, ni ìhòhò ní èmi yóò sì tún padà lọ. Olúwa fi fún ni, Olúwa sì gbà á lọ, ìbùkún ni fún orúkọ Olúwa.”

  17. Nínú gbogbo èyí Jobu kò ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi òmùgọ̀ pe Ọlọ́run lẹ́jọ́.

  18. Ó sì tún di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run wá síwájú Olúwa, Satani sì wá pẹ̀lú wọn láti pe níwájú Olúwa.

  19. Olúwa sì bi Satani pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Satani sì dá Olúwa lóhùn pé, “Láti lọ síwá sẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀.”

  20. Olúwa sì wí fún Satani pé, “Ìwọ ha kíyèsi Jobu ìránṣẹ́ mi, pé, kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí ń ṣe olóòtítọ́ tí ó sì dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì kórìíra ìwà búburú, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di ìwà òtítọ́ rẹ̀ mu ṣinṣin, bí ìwọ tilẹ̀ ti dẹ mí sí i láti run ún láìnídìí.”

  21. Satani sì dá Olúwa lóhùn wí pé, “Awọ fún awọ; àní ohun gbogbo tí ènìyàn ní, òun ni yóò fi ra ẹ̀mí rẹ̀.

  22. Ṣùgbọ́n nawọ́ rẹ nísinsin yìí, kí ó tọ́ egungun rẹ̀ àti ara rẹ̀, bí kì yóò sì bọ́hùn ní ojú rẹ.”

  23. Olúwa sì wí fún Satani pé, “Wò ó, ó ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n dá ẹ̀mí rẹ̀ sí.”

  24. Bẹ́ẹ̀ ni Satani jáde lọ kúrò níwájú Olúwa, ó sì sọ Jobu ní oówo kíkankíkan láti àtẹ́lẹsẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀.

  25. Nígbà náà ni aya rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ di ìwà òtítọ́ mú síbẹ̀! Bú Ọlọ́run, kí ó sì kú!”