God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
nítorí oúnjẹ tí ó wà lórí tábìlì; nítorí ọrẹ ohun jíjẹ àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo; nítorí ọrẹ ọjọ́ ìsinmi, ti àyajọ́ oṣù tuntun àti àjọ̀dún tí a yàn; nítorí ọrẹ mímọ́; nítorí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún Israẹli; àti fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa.
“Àwa, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi àti àwọn ènìyàn náà ti dìbò láti pinnu ìgbà tí olúkúlùkù àwọn ìdílé yóò mú ọrẹ igi wá láti sun lọ́ríi pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa sí ilé Ọlọ́run wa, ní àkókò tí a yàn ní ọdọọdún. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin.
“Àwa tún gbà ojúṣe láti mú àkọ́so àwọn èso wa wá àti gbogbo èso igi wá ní ilé Olúwa.
“Gẹ́gẹ́ bí a sì ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin, àwa yóò mú àkọ́bí àwọn ọmọkùnrin wa, ti ohun ọ̀sìn wa, ti àwọn abo màlúù àti ti àwọn àgùntàn wa, wá sí ilé Ọlọ́run wa, fún àwọn àlùfáà tí ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀.
“Síwájú sí i, àwa yóò mú àkọ́so oúnjẹ ilẹ̀ wa ti ọrẹ oúnjẹ, ti gbogbo èso àwọn igi àti ti wáìnì tuntun wa àti ti òróró wá sí yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí ilé Ọlọ́run wa àti fún àwọn àlùfáà. Àwa yóò sì mú ìdámẹ́wàá ohun ọ̀gbìn wá fún àwọn ọmọ Lefi, nítorí àwọn ọmọ Lefi ni ó ń gba ìdámẹ́wàá ní gbogbo àwọn ìlú tí a ti ń ṣiṣẹ́.
Àlùfáà tí o ti ìdílé Aaroni wá ni yóò wá pẹ̀lú àwọn ọmọ Lefi nígbà tí wọ́n bá ń gba ìdámẹ́wàá, àwọn ọmọ Lefi yóò sì mú ìdámẹ́wàá ti ìdámẹ́wàá náà wá sí ilé Ọlọ́run, sí yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí inú ilé ìṣúra.
Àwọn ènìyàn Israẹli, àti àwọn ọmọ Lefi gbọdọ̀ mú ọrẹ oúnjẹ, wáìnì tuntun àti òróró wá sí yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí níbi tí a pa ohun èlò ibi mímọ́ mọ́ sí àti ibi tí àwọn àlùfáà tí ń ṣe ìránṣẹ́ lọ́wọ́, àwọn aṣọ́nà àti àwọn akọrin máa ń dúró sí. “Àwa kì yóò gbàgbé tàbí ṣe àìbìkítà nípa ilé Ọlọ́run wa.”
Seraiah ọmọ Hilkiah, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraioti, ọmọ Ahitubu, àwọn ni olórí tó ń bojútó ilé Ọlọ́run,
Ṣabbetai àti Josabadi, olórí méjì nínú àwọn ọmọ Lefi, àwọn tí ó jẹ́ alábojútó iṣẹ́ tí ó wà ní ẹ̀yìn àgbàlá ilé Ọlọ́run;
Olórí òṣìṣẹ́ àwọn ọmọ Lefi ní Jerusalẹmu ní Ussi ọmọ Bani, ọmọ Haṣabiah, ọmọ Mattaniah ọmọ Mika. Ussi jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìran Asafu tí wọ́n jẹ́ akọrin ojúṣe nínú ìjọ́sìn ní ilé Ọlọ́run.
Àti àwọn olórí àwọn ọmọ Lefi ni Haṣabiah, Ṣerebiah, Jeṣua ọmọ Kadmieli, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, tí wọ́n dúró ní ìdojúkojú wọn láti fi ìyìn àti láti dúpẹ́, apá kan ń dá èkejì lóhùn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Dafidi ènìyàn Ọlọ́run.
àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, Ṣemaiah, Asareeli, Milalai, Gilalai, Maai, Netaneli, Juda àti Hanani—pẹ̀lú ohun èlò orin bí àṣẹ Dafidi ènìyàn Ọlọ́run. Esra akọ̀wé ni ó ṣáájú wọn bí wọ́n ti ń tò lọ lọ́wọ̀ọ̀wọ́.
Àwọn ẹgbẹ́ akọrin méjèèjì tí wọ́n dúpẹ́ wà ní ààyè nínú ilé Ọlọ́run, èmi náà sì dúró ní ààyè mi pẹ̀lú ìdajì àwọn ìjòyè,
Ní ọjọ́ náà wọ́n rú ẹbọ ńlá, wọ́n ṣe àjọyọ̀ nítorí Ọlọ́run ti fún wọn ní ayọ̀ ńlá. Àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé sì yọ̀ pẹ̀lú. A lè gbọ́ ariwo ayọ̀ tí ó jáde láti Jerusalẹmu ní jìnnà réré.
Wọ́n ń ṣiṣẹ́ Ọlọ́run wọn àti iṣẹ́ ìyàsímímọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni fún àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà, wọ́n ń ṣe gẹ́gẹ́ bí Dafidi àti Solomoni ọmọ rẹ̀ ti pàṣẹ fún wọn.
Ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn ní ìgbà Dafidi àti Asafu, ni àwọn atọ́nisọ́nà ti wà fún àwọn akọrin àti fún orin ìyìn àti orin ọpẹ́ sí Ọlọ́run.
Ní ọjọ́ náà ni a ka ìwé Mose sókè sí etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn, nínú rẹ̀ ni a ti rí i tí a kọ ọ́ sílẹ̀ pé a kò gbọdọ̀ gba àwọn ará a Ammoni tàbí àwọn ará a Moabu sí àárín ìjọ ènìyàn Ọlọ́run láéláé.
Nítorí wọn kò mú oúnjẹ àti omi wá pàdé àwọn ọmọ Israẹli lọ́nà, dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n bẹ Balaamu ní ọ̀wẹ̀ láti gégùn ún lé wọn lórí. (Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa yí ègún náà padà sí ìbùkún.)
Ṣáájú èyí a ti fi Eliaṣibu àlùfáà ṣe alákòóso yàrá ìkó nǹkan ilé Ọlọ́run wa sí. Ó súnmọ́ Tobiah pẹ́kípẹ́kí.
Mo sì padà sí Jerusalẹmu. Níhìn-ín ni mo ti mọ̀ nípa onírúurú ohun búburú tí Eliaṣibu ti ṣe ní ti pípèsè yàrá fún Tobiah nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run.
Mo pàṣẹ kí wọn ya àwọn iyàrá náà sí mímọ́, mo sì kó àwọn ohun èlò ilé Ọlọ́run padà síbẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti tùràrí.
Nígbà náà ni mo bá àwọn ìjòyè wí, mo sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí a fi kọ ilé Ọlọ́run sílẹ̀?” Nígbà náà ni mo pè wọ́n jọ pọ̀, mo sì fi olúkúlùkù sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀.
Rántí ì mi fún èyí, Ọlọ́run mi, kí o má sì ṣe gbàgbé ohun tí mo fi òtítọ́ ṣe fún ilé Ọlọ́run mi yìí àti fún iṣẹ́ ẹ rẹ̀ gbogbo.
Ṣé àwọn baba ńlá yín kò ha ti ṣe nǹkan kan náà tí Ọlọ́run wa fi mú gbogbo àjálù yìí wá orí wa, àti sórí ìlú yìí? Báyìí, ẹ̀yin tún ń ru ìbínú sókè sí i sórí Israẹli nípa bíba ọjọ́ ìsinmi jẹ́.”
Nígbà náà ni mo pàṣẹ fún àwọn ọmọ Lefi pé kí wọn ya ara wọn sí mímọ́, kí wọn sì ṣọ́ ẹnu ibodè kí a lè pa ọjọ́ ìsinmi mọ́. Tún rántí mi fún èyí, Ọlọ́run mi, kí o sì fi àánú un rẹ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí i títóbi ìfẹ́ ẹ̀ rẹ.