Fò sí àkóónú

Abraham

277 ẹsẹ · 14 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Abram

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Abraham

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa, ẹni tí ó ra Abrahamu padà sọ sí ilé Jakọbu: “Ojú kì yóò ti Jakọbu mọ́; ojú wọn kì yóò sì rẹ̀wẹ̀sì mọ́.

  2. “Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ Israẹli, ìránṣẹ́ mi, Jakọbu, ẹni tí mo ti yàn, ẹ̀yin ìran Abrahamu, ọ̀rẹ́ mi,

  3. ẹ wo Abrahamu baba yín, àti Sara, ẹni tó bí i yín. Nígbà tí mo pè é, òun nìkan ni, Èmi sì bùkún un, mo sì ṣọ́ ọ di ọ̀pọ̀lọpọ̀.

  4. Ṣùgbọ́n ìwọ ni baba wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Abrahamu kò mọ̀ wá tàbí Israẹli mọ ẹni tí à á ṣe; ìwọ, Olúwa ni Baba wa, Olùràpadà wa láti ìgbà n nì ni orúkọ rẹ.

  5. Nígbà náà ni èmi ó kọ ọmọ lẹ́yìn Jakọbu àti Dafidi ìránṣẹ́ mi tí èmi kò sì ní yan ọ̀kan nínú ọmọkùnrin rẹ̀ láti jẹ́ alákòóso lórí àwọn ọmọ Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu; nítorí èmi ó mú ìkólọ wọn padà; èmi ó sì ṣàánú fún wọn.’ ”

  6. “Ọmọ ènìyàn, àwọn ènìyàn tí ó ń gbé nínú ìparun ní ilẹ̀ Israẹli ń wí pé, ‘Abrahamu jẹ́ ọkùnrin kan, síbẹ̀ o gba ilẹ̀ ìní náà. Ṣùgbọ́n àwa pọ̀, lóòótọ́ a ti fi ilẹ̀ náà fún wa gẹ́gẹ́ bí ìní wa.’

  7. Ìwọ yóò fi òtítọ́ hàn sí Jakọbu ìwọ yóò sì fi àánú hàn sí Abrahamu, bí ìwọ ṣe búra fún àwọn baba wa láti ọjọ́ ìgbàanì.

  8. Ìwé ìran Jesu Kristi, ẹni tí í ṣe ọmọ Dafidi, ọmọ Abrahamu:

  9. Abrahamu ni baba Isaaki; Isaaki ni baba Jakọbu; Jakọbu ni baba Juda àti àwọn arákùnrin rẹ̀,

  10. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo wọ́n jẹ́ ìran mẹ́rìnlá láti orí Abrahamu dé orí Dafidi, ìran mẹ́rìnlá á láti orí Dafidi títí dé ìkólọ sí Babeli, àti ìran mẹ́rìnlá láti ìkólọ títí dé orí Kristi.

  11. Kí ẹ má sì ṣe rò nínú ara yin pé, ‘Àwa ní Abrahamu ní baba.’ Èmi wí fún yín, Ọlọ́run lè mu àwọn ọmọ jáde láti inú àwọn òkúta wọ̀nyí wá fún Abrahamu.

  12. Mo sì wí fún yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò ti ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn wá, wọ́n á sì bá Abrahamu àti Isaaki àti Jakọbu jẹun ní ìjọba ọ̀run.

  13. ‘Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu.’ Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run òkú, ṣùgbọ́n tí àwọn alààyè.”

  14. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa bóyá àjíǹde yóò wà. Àbí ẹ̀yin kò ì tí ka ìwé Eksodu, nípa Mose àti pápá tí ń jó? Ọlọ́run sọ fún Mose pé, ‘Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu.’

  15. sí Abrahamu àti àwọn ìran rẹ̀ láéláé, baba wa, àti bí ó ti sọ fún àwọn baba wa.”

  16. ìbúra tí ó ti bú fún Abrahamu baba wa,

  17. Nítorí náà kí ẹ̀yin kí ó so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, kí ẹ má sì ṣe sí í wí nínú ara yín pé, ‘Àwa ní Abrahamu ní baba.’ Kí èmi kí ó wí fún un yín, Ọlọ́run lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu nínú òkúta wọ̀nyí.

  18. Tí í ṣe ọmọ Jakọbu, tí í ṣe ọmọ Isaaki, tí í ṣe ọmọ Abrahamu, tí í ṣe ọmọ Tẹra, tí í ṣe ọmọ Nahori,

  19. Kò sì yẹ kí a tú obìnrin yìí tí í ṣe ọmọbìnrin Abrahamu sílẹ̀ ní ìdè yìí ní ọjọ́ ìsinmi, ẹni tí Satani ti dè, sá à wò ó láti ọdún méjìdínlógún yìí wá?”

  20. “Níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò wà, nígbà tí ẹ̀yin ó rí Abrahamu, àti Isaaki, àti Jakọbu, àti gbogbo àwọn wòlíì, ní ìjọba Ọlọ́run, tí a ó sì ti ẹ̀yin sóde.

  21. “Ó sì ṣe, alágbe kú, a sì ti ọwọ́ àwọn angẹli gbé e lọ sí oókan àyà Abrahamu: ọlọ́rọ̀ náà sì kú pẹ̀lú, a sì sin ín;

  22. Ní ipò òkú ni ó gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ń bẹ nínú ìjìyà oró, ó sì rí Abrahamu ní òkèrè, àti Lasaru ní oókan àyà rẹ̀.

  23. Ó sì ké, ó wí pé, ‘Baba Abrahamu, ṣàánú fún mi, kí o sì rán Lasaru, kí ó tẹ orí ìka rẹ̀ bọ omi, kí ó sì fi tù mí ní ahọ́n; nítorí èmi ń joró nínú ọ̀wọ́n iná yìí.’

  24. “Ṣùgbọ́n Abrahamu wí pé, ‘Ọmọ, rántí pé, nígbà ayé rẹ, ìwọ ti gba ohun rere tìrẹ, àti Lasaru ohun búburú, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ara rọ̀ ọ́, ìwọ sì ń joró.

  25. “Abrahamu sì wí fún un pé, ‘Wọ́n ní Mose àti àwọn wòlíì; kí wọn kí ó gbọ́ tiwọn.’