Fò sí àkóónú

Aaron

331 ẹsẹ · 9 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Aaron

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Lẹ́yìn èyí àwọn ọmọ Lefi lọ sínú àgọ́ ìpàdé láti lọ máa ṣiṣẹ́ wọn lábẹ́ àbojútó Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n ṣe fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  2. Àwọn díẹ̀ nínú wọn kò lè ṣe àjọ ìrékọjá lọ́jọ́ náà nítorí pé wọ́n di aláìmọ́ nítorí òkú ènìyàn. Nítorí èyí wọ́n wá sọ́dọ̀ Mose àti Aaroni lọ́jọ́ náà.

  3. “Àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ni kí ó máa fun fèrè. Èyí yóò jẹ́ ìlànà láéláé fún yín àti fún ìran tó ń bọ̀.

  4. Miriamu àti Aaroni sọ̀rọ̀-òdì sí Mose nítorí pé ó fẹ́ obìnrin ará Etiopia.

  5. Lẹ́ẹ̀kan náà ni Olúwa sọ fún Mose, Aaroni àti Miriamu pé, “Ẹ̀yin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, jáde wá sínú àgọ́ ìpàdé.” Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì jáde síta.

  6. Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú ọ̀wọ́n ìkùùkuu, ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, ó ké sí Aaroni àti Miriamu. Àwọn méjèèjì sì bọ́ síwájú,

  7. Nígbà tí ìkùùkuu kúrò lórí àgọ́ lójijì ni Miriamu di adẹ́tẹ̀, ó funfun bí i yìnyín. Aaroni sì padà wo Miriamu ó sì rí i pé ó ti di adẹ́tẹ̀,

  8. Aaroni sì wí fún Mose pé, “Jọ̀wọ́ olúwa mi, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀, èyí tí a fi ìwà òmùgọ̀ dá sí wa lọ́rùn.

  9. Wọ́n padà wá bá Mose àti Aaroni àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní ijù Kadeṣi Parani. Wọ́n mú ìròyìn wá fún wọn àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn, wọ́n fi èso ilẹ̀ náà hàn wọ́n.

  10. Gbogbo ọmọ Israẹli sì kùn sí Mose àti Aaroni, gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sì wí fún wọn pé, “Àwa ìbá kúkú ti kú ní ilẹ̀ Ejibiti. Tàbí kí a kúkú kú sínú aginjù yìí.

  11. Nígbà náà ni Mose àti Aaroni dojúbolẹ̀ níwájú gbogbo ìjọ ọmọ Israẹli.

  12. Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé,

  13. Àwọn tó sì rí i níbi tó ti ń ṣá igi wọ́n sì mú un wá sí ọ̀dọ̀ Mose àti Aaroni àti síwájú gbogbo ìjọ ènìyàn,

  14. Wọ́n kó ara wọn jọ láti tako Mose àti Aaroni, wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ ti kọjá ààyè yín, ó tó gẹ́ẹ́! Mímọ́ ni gbogbo ènìyàn, kò sí ẹni tí kò mọ́ láàrín wọn, Olúwa sì wà pẹ̀lú wọn, nítorí kí wá ni ẹ̀yin ṣe gbé ara yín ga ju ìjọ ènìyàn Olúwa lọ?”

  15. Olúwa ni ìwọ àti gbogbo ẹlẹgbẹ́ rẹ takò. Ta a ni Aaroni jẹ́ tí ẹ̀yin ó fi kùn sí i?”

  16. Mose sọ fún Kora pé, “Ìwọ àti ọmọ lẹ́yìn rẹ gbọdọ̀ fi ara hàn níwájú Olúwa lọ́la—gbogbo yín, ìwọ, àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ àti Aaroni.

  17. Kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín mú àwo tùràrí, kí ó sì fi tùràrí sínú rẹ̀, kí gbogbo rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta lé nígba (250) àwo tùràrí kí ẹ sì ko wá síwájú Olúwa. Ìwọ àti Aaroni yóò mú àwo tùràrí wá pẹ̀lú.”

  18. Nígbà náà ni oníkálùkù wọn mú àwo tùràrí, wọ́n fi iná àti tùràrí sí i nínú, wọ́n sì dúró sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, àwọn pẹ̀lú Mose àti Aaroni.

  19. Olúwa sì sọ fún Mose àti Aaroni pé,

  20. “Sọ fún Eleasari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà, pé kí ó mú àwọn àwo tùràrí jáde kúrò nínú iná nítorí pé wọ́n jẹ́ mímọ́, kí ó sì tan iná náà káàkiri sí ibi tó jìnnà.

  21. gẹ́gẹ́ bí Olúwa ṣe sọ láti ẹnu Mose. Èyí yóò jẹ́ ohun ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, àlejò yàtọ̀ sí irú-ọmọ Aaroni kò gbọdọ̀ jó tùràrí níwájú Olúwa, ẹni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóò dàbí Kora àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀.

  22. Ní ọjọ́ kejì gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli kùn sí Mose àti Aaroni pé, “Ẹ ti pa àwọn ènìyàn Olúwa.”

  23. Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn péjọ lòdì sí Mose àti Aaroni, níwájú àgọ́ ìpàdé, lójijì ni ìkùùkuu bolẹ̀, ògo Olúwa sì fi ara hàn.

  24. Nígbà náà ni Mose àti Aaroni lọ síwájú àgọ́ ìpàdé,

  25. Mose sì sọ fún Aaroni pé, “Mú àwo tùràrí, kí o fi iná sí i lórí pẹpẹ, fi tùràrí sínú rẹ̀, kí o sì tètè mu lọ sí àárín ìjọ ènìyàn láti ṣe ètùtù fún wọn nítorí pé ìbínú Olúwa ti jáde, àjàkálẹ̀-ààrùn sì ti bẹ̀rẹ̀.”