Skip to content
2 Kronika 34:18-33

2 Kronika 34:18-33

18
Nígbà náà Ṣafani akọ̀wé sì sọ fún ọba, “Hilkiah àlùfáà ti fún mi ní ìwé.” Ṣafani sì kà níwájú ọba.
19
Nígbà tí ọba sì gbọ́ ọ̀rọ̀ òfin, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya.
20
Ó sì pa àṣẹ yìí fún Hilkiah, Ahikamu ọmọ Ṣafani, Abdoni ọmọ Mika, Ṣafani akọ̀wé àti Asaiah ìránṣẹ́ ọba.
21
“Ẹ lọ kí ẹ lọ béèrè lọ́wọ́ Olúwa fún mi nípa àwọn ìyókù Israẹli àti Juda nípa ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé yìí tí a ti rí. Títóbi ni ìbínú Olúwa tí ó ti jáde sí orí wa nítorí àwọn baba wa kò ti pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́, wọn kò sì tí ì ṣe gẹ́gẹ́ bí i gbogbo èyí tí a kọ sínú ìwé yìí.”
22
Hilkiah àti àwọn ènìyàn tí ọba yàn tọ Hulda wòlíì obìnrin láti ba sọ̀rọ̀, ẹni tí ó jẹ́ aya Ṣallumu ọmọ Tokhati tí a tún ń pè ní Tikfa, ọmọ Harhasi, olùtọ́jú ibi ìkáṣọsí. Ó sì ń gbé ní Jerusalẹmu, ní ìhà kejì.
23
Ó sì wí fún wọn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli ti sọ, sọ fún àwọn ọkùnrin tí ó rán ọ sí mi pé,
24
‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Èmi yóò sì mú ibi wá sí ìhín yìí àti àwọn ènìyàn rẹ̀ gbogbo àní ègún tí a kọ sínú ìwé tí wọ́n ti kà níwájú ọba Juda.”
25
Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀ wọ́n sì ti sun tùràrí sí ọlọ́run mìíràn wọ́n sì ti mú mi bínú pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ti fi ọwọ́ wọn ṣe, ìbínú yóò tú jáde wá sórí ibí yìí, a kì yóò sì paná rẹ̀.’
26
Sọ fún ọba Juda, ẹni tí ó rán yín láti béèrè lọ́wọ́ Olúwa, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa ti sọ, Ọlọ́run Israẹli, sọ nípa ọ̀rọ̀ wọ́n nì tí ìwọ gbọ́.
27
Nítorí ọkàn rẹ̀ dúró, ìwọ sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Olúwa nígbà tí ó gbọ́ ohun tí ó sọ lórí ibí yìí àti ènìyàn rẹ, nítorí ìwọ rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú mi tí o sì fa aṣọ rẹ ya, tí o sì lọ níwájú mi. Èmi ti gbọ́ tìrẹ ni Olúwa wí.
28
Nísinsin yìí, Èmi ó kó ọ jọ pọ̀ sọ́dọ̀ àwọn baba rẹ, a ó sì sin ọ́ ní àlàáfíà. Ojú rẹ kò sì ní rí gbogbo ibi tí èmi ó mú wá sórí ibí yìí àti lórí àwọn tí ń gbé ibẹ̀.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n mú ìdáhùn rẹ̀ padà sí ọ̀dọ̀ ọba.
29
Nígbà náà ni ọba sì pe gbogbo àwọn àgbàgbà Juda jọ àti Jerusalẹmu.
30
Ó gòkè lọ sí ilé Olúwa pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Juda, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu, àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi—gbogbo àwọn ènìyàn láti ibi kéékèèké sí ńlá. Ó kà á sí etí ìgbọ́ ọ wọn, gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé májẹ̀mú, tí a ti rí nínú ilé Olúwa.
31
Ọba sì dúró ní ipò rẹ̀ ó sì tún májẹ̀mú dá níwájú Olúwa, láti tẹ̀lé Olúwa àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, àti ẹ̀rí rẹ̀ àti àṣẹ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀ àti gbogbo àyà rẹ̀ àti láti pa ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tí a kọ sí inú ìwé yìí.
32
Nígbà náà, ó sì mú kí gbogbo ènìyàn ní Jerusalẹmu àti Benjamini dúró nínú ẹ̀rí fún ara wọn, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ṣe èyí gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú Ọlọ́run, Ọlọ́run baba ńlá wọn.
33
Josiah sì kó gbogbo ohun ìríra kúrò nínú gbogbo ìlú tí ń ṣe ti àwọn tí ó wà ní Israẹli, ó sì mú kí gbogbo àwọn tí ó wà ní Israẹli sin Olúwa Ọlọ́run wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe wà láyè wọn, kò yà kúrò láti máa tọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn lẹ́yìn.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options