- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Ziba
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Dafidi sì béèrè pé, ọ̀kan nínú àwọn ẹni tí ń ṣe ìdílé Saulu kù síbẹ̀ bí? Kí èmi lè ṣe oore fún un nítorí Jonatani.
Ìránṣẹ́ kan sì ti wà ní ìdílé Saulu, orúkọ rẹ̀ sí ń jẹ́ Ṣiba, wọ́n sì pè é wá sọ́dọ̀ Dafidi, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ìwọ ni Ṣiba bí?” Ó sì dáhùn wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ni.”
Ọba sì wí pé, “Kò ha sí ọ̀kan nínú ìdílé Saulu síbẹ̀, kí èmi ṣe oore Ọlọ́run fún un?” Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Jonatani ní ọmọ kan síbẹ̀ tó ya arọ.”
Ọba sì wí fún un pé, “Níbo ni ó gbé wà?” Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Wò ó, òun wà ní ilé Makiri, ọmọ Ammieli, ní Lo-Debari.”
Dafidi ọba sì ránṣẹ́, ó sì mú un láti ilé Makiri ọmọ Ammieli láti Lo-Debari wá.
Mefiboṣeti ọmọ Jonatani ọmọ Saulu sì tọ Dafidi wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì bú ọlá fún un. Dafidi sì wí pé, “Mefiboṣeti!” Òun sì dáhùn wí pé, “Wò ó, ìránṣẹ́ rẹ!”
Dafidi sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù, nítorí pé nítòótọ́ èmi ó ṣe oore fún ọ nítorí Jonatani baba rẹ, èmi ó sì tún fi gbogbo ilé Saulu baba rẹ fún ọ, ìwọ ó sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.”
Mefiboṣeti sì tẹríba, ó sì wí pé, “Kí ni ìránṣẹ́ rẹ jásí, tí ìwọ ó fi máa wo òkú ajá bí èmi.”
Ọba sì pe Ṣiba ìránṣẹ́ Saulu, ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan tí í ṣe ti Saulu, àti gbogbo èyí tí í ṣe ti ìdílé rẹ̀ ni èmi fi fún ọmọ olúwa rẹ.
Ìwọ, àti àwọn ọmọ rẹ, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ ni yóò sì máa ro ilẹ̀ náà fún un, ìwọ ni yóò sì máa mú ìkórè wá, ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa rí oúnjẹ jẹ, ṣùgbọ́n Mefiboṣeti ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.” (Ṣiba sì ní ọmọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti ogún ìránṣẹ́kùnrin.)
Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí olúwa mi ọba ti pàṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni ìránṣẹ́ rẹ ó ṣe.” Ọba sì wí pé, “Ní ti Mefiboṣeti, yóò máa jẹun ní ibi oúnjẹ mi, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọba.”
Mefiboṣeti sì ní ọmọ kékeré kan, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mika. Gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilé Ṣiba ni ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún Mefiboṣeti.
Mefiboṣeti sì ń gbé ní Jerusalẹmu, òun a sì máa jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ ọba; òun sì yarọ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì.
Nígbà tí Dafidi sì fi díẹ̀ kọjá orí òkè náà, sì wò ó, Ṣiba ìránṣẹ́ Mefiboṣeti sì ń bọ̀ wá pàdé rẹ̀, òun àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì tí a ti dì ní gàárì, àti igba ìṣù àkàrà lórí wọn, àti ọgọ́rùn-ún síírí àjàrà gbígbẹ, àti ọgọ́rùn-ún èso ẹ̀rún, àti ìgò ọtí wáìnì kan.
Ọba sì wí fún Ṣiba pé, “Kí ni wọ̀nyí?” Ṣiba sì wí pé, “Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ̀nyí ni fún àwọn ará ilé ọba láti máa gùn àti àkàrà yìí, àti èso ẹ̀rún yìí ni fún àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin láti jẹ; àti ọtí wáìnì yìí ni fún àwọn aláàárẹ̀ ní ijù láti mu.”
Ọba sì wí pé, “Ọmọ olúwa rẹ dà?” Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Wò ó, ó jókòó ní Jerusalẹmu; nítorí tí ó wí pé, ‘Lónìí ni ìdílé Israẹli yóò mú ìjọba baba mi padà wá fún mi.’ ”
Ọba sì wí fún Ṣiba pé, “Wò ó, gbogbo nǹkan tí í ṣe ti Mefiboṣeti jẹ́ tìrẹ.” Ṣiba sì wí pé, “Mo túúbá, jẹ́ kí n rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ, olúwa mi ọba.”
Ẹgbẹ̀rún ọmọkùnrin sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nínú àwọn ọmọkùnrin Benjamini, Ṣiba ìránṣẹ́ ilé Saulu, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti ogún ìránṣẹ́ sì pẹ̀lú rẹ̀; wọ́n sì gòkè odò Jordani ṣáájú ọba.
Òun sì dáhùn wí pé, “Olúwa mi, ọba, ìránṣẹ́ mi ni ó tàn mí, nítorí ìránṣẹ́ rẹ wí fún un pé, ‘Di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún mi èmi ó gùn ún, èmi ó sì tọ ọba lọ.’ Nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ yarọ.
Ó sì sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí ìránṣẹ́ rẹ, fún olúwa mi ọba, ṣùgbọ́n bí angẹli Ọlọ́run ni olúwa mi ọba rí, nítorí náà ṣe èyí tí ó dára lójú rẹ.
Nítorí pé gbogbo ilé baba mi bí òkú ènìyàn ni wọ́n sá à rí níwájú olúwa mi ọba, ìwọ sì fi ipò fún ìránṣẹ́ rẹ láàrín àwọn tí ó ń jẹun ní ibi oúnjẹ. Nítorí náà àre kín ni èmi ní tí èmi yóò fi máa ké pe ọba síbẹ̀.”
Ọba sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń sọ ọ̀ràn ara rẹ fún mi èmi sá à ti wí pé, kí ìwọ àti Ṣiba pín ilẹ̀ náà.”