Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Women

304 ẹsẹ · 47 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Pẹ̀lú ọwọ́ àwọn obìnrin aláàánú ni wọ́n ṣe ọmọ wọn jẹ tí ó di oúnjẹ fún wọn nígbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run.

  2. Wọ́n ti fipá bá àwọn obìnrin wa lòpọ̀ ní Sioni, àti àwọn wúńdíá ti o wa ní ìlú Juda.

  3. “Nísinsin yìí, ọmọ ènìyàn, dojúkọ àwọn ọmọbìnrin ènìyàn rẹ tí wọ́n ń sọtẹ́lẹ̀ láti inú èrò ọkàn wọn, sọtẹ́lẹ̀ sí wọn

  4. wí pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí. Ègbé ni fún ẹ̀yin obìnrin tí ẹ ń rán ìfúnpá òògùn sí ìgbọ̀nwọ́ àwọn ènìyàn, tí ẹ ń ṣe ìbòjú oríṣìíríṣìí fún orí oníkálùkù ènìyàn láti ṣọdẹ ọkàn wọn. Ẹ̀yin yóò wa dẹkùn fún ọkàn àwọn ènìyàn mi bí? Ẹ̀yin yóò sì gba ọkàn ti ó tọ̀ yín wá là bí?

  5. Nítorí ẹ̀kúnwọ́ ọkà barle àti òkèlè oúnjẹ. Ẹ ti pa àwọn tí kò yẹ kí ẹ pa, ẹ sì fi àwọn tí kò yẹ kó wà láààyè sílẹ̀ nípa irọ́ tí ẹ ń pa fún àwọn ènìyàn mi, èyí tí àwọn náà ń fetí sí.

  6. “ ‘Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí. Mo lòdì sí ìfúnpá òògùn tí ẹ fi ń ṣọdẹ ọkàn ènìyàn káàkiri bí ẹyẹ, Èmi yóò ya á kúrò lápá yín, Èmi yóò sì dá ọkàn àwọn ènìyàn tí ẹ ń ṣọdẹ sílẹ̀.

  7. Èmi yóò ya àwọn ìbòjú yín, láti gba àwọn ènìyàn mi lọ́wọ́ yín, wọn kò sì ní jẹ́ ìjẹ fún yín mọ́. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.

  8. Nítorí pé ẹ̀yin ti ba ọkàn àwọn olódodo jẹ́ pẹ̀lú irọ́ yín, nígbà tí Èmi kò mú ìbànújẹ́ bá wọn, àti nítorí ẹ̀yin ti mú ọkàn àwọn ènìyàn búburú le, kí wọ́n má ba à kúrò nínú ọ̀nà ibi wọn dé bi tí wọn yóò fi gba ẹ̀mí wọn là,

  9. nítorí èyí, ẹ̀yin kò ní í ríran èké, ẹ̀yin kò sì ní fọ àfọ̀ṣẹ mọ́. Èmi yóò gba àwọn ènìyàn mi lọ́wọ́ yín. Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’ ”

  10. Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ní Heliopolisi àti Bubasiti yóò ti ipa idà ṣubú wọn yóò sì kó àwọn ìlú wọn ní ìgbèkùn.

  11. Ojú ọjọ́ yóò ṣókùnkùn ní Tafanesi nígbà tí mo bá já àjàgà Ejibiti kúrò; níbẹ̀ agbára iyì rẹ̀ yóò dópin wọn yóò fi ìkùùkuu bò ó àwọn abúlé rẹ ní wọn yóò lọ sí ìgbèkùn.

  12. Kíyèsi gbogbo àwọn jagunjagun! Obìnrin ni gbogbo wọn. Ojú ibodè rẹ ní a ó ṣí sílẹ̀ gbagada, fún àwọn ọ̀tá rẹ; iná yóò jó ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn ibodè rẹ.

  13. Nítorí oore rẹ̀ tí tóbi tó, ẹwà rẹ̀ sì tí pọ̀! Ọkà yóò mú ọ̀dọ́mọkùnrin dárayá, àti ọtí wáìnì tuntun yóò mú àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.

  14. Nígbà tí kò tì í ní agbára láti san án, nígbà náà ni olúwa rẹ̀ pàṣẹ pé kí a ta òun àti ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní láti fi san gbèsè náà.

  15. Ọ̀pọ̀ obìnrin tí ó wá láti Galili pẹ̀lú Jesu láti tọ́jú rẹ̀ wọn ń wò ó láti òkèèrè.

  16. Nínú àwọn obìnrin ti ó wà níbẹ̀ ni Maria Magdalene, àti Maria ìyá Jakọbu àti Josẹfu, àti ìyá àwọn ọmọ Sebede méjèèjì wà níbẹ̀ pẹ̀lú.

  17. Àwọn obìnrin kan wà níbẹ̀ pẹ̀lú, tí wọ́n ń wò ó láti òkèèrè. Maria Magdalene wà lára àwọn obìnrin náà, àti Maria ìyá Jakọbu kékeré àti ti Jose, àti Salome.

  18. Àwọn wọ̀nyí, nígbà tí ó wà ní Galili máa ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n a sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún un àti ọ̀pọ̀ obìnrin mìíràn tí wọ́n sì bá a gòkè wá sí Jerusalẹmu.

  19. Josẹfu sì ti ra aṣọ ọ̀gbọ̀ wá. Ó sọ òkú Jesu kalẹ̀: ó sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ náà dì í. Ó sì tẹ́ ẹ sí inú ibojì, tí wọ́n gbẹ́ sí ara àpáta. Ó wá yí òkúta dí ẹnu ibojì náà.

  20. Maria Magdalene àti Maria ìyá Jose ń wò ó bi Josẹfu ti n tẹ́ Jesu sí ibojì.

  21. Nígbà tí ọjọ́ ìsinmi sì kọjá, Maria Magdalene, Maria ìyá Jakọbu, àti Salome mú òróró olóòórùn dídùn wá kí wọn bá à le fi kun Jesu lára.

  22. Ní kùtùkùtù ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, wọ́n wá sí ibi ibojì nígbà tí oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí yọ,

  23. wọn sì ń bi ara wọn léèrè pé, “Ta ni yóò yí òkúta náà kúrò ní ẹnu ibojì fún wa?”

  24. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn sì wò ó, wọ́n rí i pé a ti yí òkúta tí ó tóbi gidigidi náà kúrò.

  25. Nígbà tí wọ́n sì wo inú ibojì náà, wọ́n rí ọ̀dọ́mọkùnrin kàn tí ó wọ aṣọ funfun, ó jókòó ní apá ọ̀tún, ẹnu sì yà wọn.