Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Women: Rules for dress of Christian
Àwọn ẹsẹ nípa Rules for dress of Christian
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí àwọn obìnrin fi aṣọ ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ṣe ara wọn ní ọ̀ṣọ́, ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti pẹ̀lú ìwà àìrékọjá; kì í ṣe pẹ̀lú irun dídì, tàbí wúrà, tàbí peali, tàbí aṣọ olówó iyebíye,
bí kò ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ rere, èyí tí ó yẹ fún àwọn obìnrin tó jẹ́wọ́ pé wọ́n sin Ọlọ́run.
Kí ọ̀ṣọ́ yín má ṣe jẹ́ ọ̀ṣọ́ òde, tí irun dídì, àti wúrà lílò, tàbí ti aṣọ wíwọ̀;
ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni tí ó fi ara sin ní ọkàn, nínú ọ̀ṣọ́ àìdíbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí tútù, èyí tí i ṣe iyebíye níwájú Ọlọ́run.