Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Wicked

724 ẹsẹ · 18 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Aláìgbọ́n a máa ní inú dídùn sí ìwà búburú, ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa ní inú dídùn sí ọgbọ́n.

  2. Ohun tí ènìyàn búburú bẹ̀rù yóò dé bá a; olódodo yóò rí ohun tí ó fẹ́ gbà.

  3. Nígbà tí ìjì bá ti jà kọjá, ènìyàn búburú a kọjá lọ, ṣùgbọ́n olódodo yóò dúró ṣinṣin láéláé.

  4. Ìrètí olódodo ni ayọ̀, ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú jásí òfo.

  5. Ọ̀nà Olúwa jẹ́ ààbò fún olódodo, ṣùgbọ́n ìparun ni ó jẹ́ fún àwọn tí ń ṣe ibi.

  6. A kì yóò fa olódodo tu láéláé, ṣùgbọ́n ènìyàn búburú kì yóò dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.

  7. Ètè olódodo mọ ohun ìtẹ́wọ́gbà, ṣùgbọ́n ètè ènìyàn búburú kò mọ̀ ju èké lọ.

  8. Òtítọ́ inú ẹni dídúró ṣinṣin ń ṣe amọ̀nà rẹ̀, ṣùgbọ́n aláìṣòótọ́ yóò parun nípasẹ̀ àìṣòótọ́ wọn.

  9. Òdodo aláìlẹ́gàn ṣe ọ̀nà tààrà fún wọn, ṣùgbọ́n ìwà búburú ènìyàn búburú yóò fà á lulẹ̀.

  10. Òdodo ẹni ìdúró ṣinṣin gbà wọ́n là, ṣùgbọ́n ìdẹ̀kùn ètè búburú mú aláìṣòótọ́.

  11. A gba olódodo kúrò lọ́wọ́ ibi dípò o rẹ̀, ibi wá sórí ènìyàn búburú.

  12. Nígbà tí olódodo ń gbèrú, ìlú a yọ̀; nígbà tí ènìyàn búburú parun, ariwo ayọ̀ gba ìlú kan.

  13. Nípasẹ̀ ìbùkún, olódodo a gbé ìlú ga: ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹnu ènìyàn búburú, a pa ìlú run.

  14. Ènìyàn búburú gba èrè ìtànjẹ ṣùgbọ́n ẹni tó fúnrúgbìn òdodo yóò gba èrè tó dájú.

  15. Olódodo tòótọ́ rí ìyè ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa ibi lé e sí ibi ikú ara rẹ̀.

  16. Olúwa kórìíra àwọn ènìyàn ọlọ́kàn búburú ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn tí ọ̀nà wọn kò lábùkù.

  17. Mọ èyí dájú pé, ènìyàn búburú kì yóò lọ láìjìyà, ṣùgbọ́n àwọn olódodo yóò lọ láìjìyà.

  18. Ìfẹ́ inú olódodo yóò yọrí sí ohun rere ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú yóò yọrí sí ìbínú.

  19. Bí àwọn olódodo bá gba ìpín wọn lórí ilẹ̀ ayé mélòó mélòó ni ènìyàn búburú àti àwọn tó dẹ́ṣẹ̀!

  20. A kò lè fi ẹsẹ̀ ènìyàn múlẹ̀ nípa ìwà búburú ṣùgbọ́n a kò le è fa olódodo tu.

  21. Èrò àwọn olódodo tọ́, ṣùgbọ́n ìgbìmọ̀ ènìyàn búburú jẹ́ ẹ̀tàn.

  22. Ọ̀rọ̀ ènìyàn búburú lúgọ de ẹ̀jẹ̀ ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ àwọn olódodo gbà wọ́n là.

  23. A ṣí àwọn ènìyàn búburú ní ìdí, wọn kò sì sí mọ́; ṣùgbọ́n ilé olódodo dúró ṣinṣin.

  24. A mú ènìyàn búburú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ṣùgbọ́n olódodo bọ́ kúrò lọ́wọ́ ìdààmú.

  25. Ibi kì í ṣubú lu olódodo rárá ṣùgbọ́n ènìyàn búburú gba ìpín ìyọnu tiwọn.