Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Trust

109 ẹsẹ · 66 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Gaali ọmọ Ebedi àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá sí Ṣekemu, àwọn ará Ṣekemu sì gbẹ́kẹ̀lé wọn, wọ́n sì fi inú tán wọn.

  2. Saulu fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ wọ Dafidi, ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ìhámọ́ra ogun, ó sì fi ìbòrí idẹ kan bò ó ní orí.

  3. Dafidi si di idà rẹ̀ mọ́ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní rìn káàkiri nítorí wí pé kò mọ́ ọ lára. Ó sọ fún Saulu pé, “Èmi kò le wọ èyí lọ, kò mọ́ mi lára.” Ó sì bọ́ wọn kúrò.

  4. Ó sì wí fún Dafidi pé, “Ṣé ajá ni mí ni? Tí o fi tọ̀ mí wá pẹ̀lú ọ̀pá?” Filistini sì fi Dafidi bú pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀.

  5. Filistini náà sì wí Dafidi pé, “Wá níbí, èmi yóò fi ẹran-ara rẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run jẹ àti fún àwọn ẹranko tí ó wà nínú igbó!”

  6. Dafidi sì wí fún Filistini pé, “Ìwọ dojú ìjà kọ mí pẹ̀lú idà, ọ̀kọ̀ àti ọfà, ṣùgbọ́n èmi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ pẹ̀lú orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Israẹli tí ìwọ tí gàn.

  7. Dafidi sì banújẹ́ gidigidi, nítorí pé àwọn ènìyàn náà sì ń sọ̀rọ̀ láti sọ ọ́ lókùúta, nítorí ti inú gbogbo àwọn ènìyàn náà sì bàjẹ́, olúkúlùkù ọkùnrin nítorí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti nítorí ọmọ rẹ̀ obìnrin ṣùgbọ́n Dafidi mú ara rẹ̀ lọ́kàn le nínú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.

  8. Ọlọ́run mi, àpáta mi, nínú ẹni tí èmi ní ààbò, àti ìwo ìgbàlà mi, ibi ìsádi gíga mi. Àti ibi ìlùmọ̀ mi, Olùgbàlà mi; ìwọ ni ó ti gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá.

  9. “Lóòtítọ́ ilé mi kò rí bẹ́ẹ̀ níwájú Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó ti bá mi dá májẹ̀mú àìnípẹ̀kun, tí a túnṣe nínú ohun gbogbo, tí a sì pamọ́; nítorí pé gbogbo èyí ni ìgbàlà, àti gbogbo ìfẹ́ mi, ilé mi kò lè ṣe kí ó má dàgbà.

  10. Beni-Hadadi sì tún rán oníṣẹ́ mìíràn sí Ahabu wí pé, “Kí àwọn òrìṣà kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú bí eruku Samaria yóò tó fún ìkúnwọ́ fún gbogbo ènìyàn tí ń tẹ̀lé mi.”

  11. Hesekiah sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run Israẹli. Kò sì ṣí ẹnìkan tí ó dàbí tirẹ̀ lára gbogbo àwọn ọba Juda, bóyá kí ó tó jẹ tàbí lẹ́yìn rẹ̀.

  12. Wò ó, nísinsin yìí, ìwọ gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ejibiti, ẹ̀rún ọ̀pá pẹlẹbẹ ìyè fífọ́ yìí, èyí tí yóò wọ inú ọwọ́ ẹni tí ó sì bá fi ara tì í. Bẹ́ẹ̀ ni Farao ọba Ejibiti ṣe rí fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ wọn lé e.

  13. Ọlọ́run wa, ṣé ìwọ kò ní ṣe ìdájọ́ fún wọn? Nítorí àwa kò ní agbára láti dojúkọ àwọn ọ̀pọ̀ ogun ńlá yìí tí ń bọ̀ wá kó wa. Àwa kò mọ̀ ohun tó yẹ ká ṣe, ṣùgbọ́n ojú wa wà ní ọ̀dọ̀ rẹ.”

  14. Agbára ẹran-ara nìkan ni ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ṣùgbọ́n, Olúwa Ọlọ́run wa pẹ̀lú wa láti ràn wá lọ́wọ́ àti láti ja ìjà wa.” Àwọn ènìyàn sì ní ìgboyà láti ara ohun tí Hesekiah ọba Juda wí.

  15. Àbá ẹni tí a ó kèé kúrò, àti ìgbẹ́kẹ̀lé ẹni tí ó dàbí ilé aláǹtakùn.

  16. Bí ó tilẹ̀ pa mí, síbẹ̀ èmi ó máa gbẹ́kẹ̀lé e, èmi ó máa tẹnumọ́ ọ̀nà mi níwájú rẹ̀.

  17. Kí òun kí ó má ṣe gbẹ́kẹ̀lé asán, kí ó má sì ṣe tan ara rẹ̀ jẹ. Nítorí pé asán ní yóò jásí èrè rẹ̀.

  18. A ó fà á tu kúrò nínú àgọ́ tí ó gbẹ́kẹ̀lé, a ó sì mú un tọ ọba ẹ̀rù ńlá nì lọ.

  19. Fi ẹnu ko ọmọ náà ní ẹnu, kí ó má ba à bínú, kí ó má ba à pa yín run ní ọ̀nà yín, nítorí ìbínú rẹ̀ lè ru sókè ní ẹ̀ẹ̀kan. Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó fi í ṣe ibi ìsádi wọn.

  20. Ẹ rú ẹbọ òdodo kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

  21. Ṣùgbọ́n, jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó sádi ọ́ kí ó yọ̀; jẹ kí wọn máa kọrin fún ayọ̀ títí. Tan ààbò rẹ sórí wọn, àti àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ yóò máa yọ̀ nínú rẹ.

  22. Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀lé ọ, nítorí, Olúwa, kò kọ àwọn tó ń wá a sílẹ̀.

  23. Fún adarí orin. Ti Dafidi. Ìgbẹ́kẹ̀lé mi wà nínú Olúwa. Báwo ní ẹ̀yin ó ṣe sọ fún ọkàn mi pé, “Fò gẹ́gẹ́ bi ẹyẹ lọ si orí òkè rẹ.

  24. Ṣùgbọ́n mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà; ọkàn mi ń yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.

  25. Bí mo tilẹ̀ ń rìn láàrín àfonífojì òjìji ikú, èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan, nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi; ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ, wọ́n ń tù mí nínú.