Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Trust: Woe and curse of false

6 ẹsẹ · 66 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Woe and curse of false

  1. “Ègbé ni àwọn ọmọ fún orílẹ̀-èdè alágídí,” ni Olúwa wí, “Fún àwọn tí ó gbé ètò jáde tí kì í ṣe tèmi, tí wọ́n ń gbìmọ̀ pọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa Ẹ̀mí mi, tí wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀;

  2. tí wọ́n lọ sí Ejibiti láìṣe fún mi, tí ó ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Farao fún ààbò, sí òjìji Ejibiti fún ibi ìsádi.

  3. Ègbé ni fún àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti fún ìrànlọ́wọ́, tí wọn gbẹ́kẹ̀lé ẹṣin tí wọ́n fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́-ẹṣin wọn àti agbára ńlá àwọn ẹlẹ́ṣin wọn, ṣùgbọ́n tiwọn kò bojú wo Ẹni Mímọ́ Israẹli n nì, tàbí kí wọn wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Olúwa.

  4. Síbẹ̀síbẹ̀ òun pẹ̀lú jẹ́ ọlọ́gbọ́n ó sì lè mú ìparun wá; òun kì í kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ. Òun yóò dìde sí ilé àwọn ìkà, àti sí àwọn tí ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún aṣebi.

  5. Ṣùgbọ́n ènìyàn lásán ni àwọn ará Ejibiti wọn kì í ṣe Ọlọ́run; ẹran-ara ni àwọn ẹṣin wọn, kì í ṣe ẹ̀mí. Nígbà tí Olúwa bá na ọwọ́ rẹ̀ jáde, ẹni náà tí ó ń ṣèrànwọ́ yóò kọsẹ̀, ẹni náà tí à ń ràn lọ́wọ́ yóò ṣubú; àwọn méjèèjì yóò sì jùmọ̀ parun.

  6. Báyìí ni Olúwa wí: “Ègbé ni fún àwọn tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú ènìyàn, tí ó fi agbára rẹ̀ sínú ẹran-ara, àti tí ọkàn rẹ̀ kò sí lọ́dọ̀ Olúwa.