Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Providence of God: Danger of denying

19 ẹsẹ · 41 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Danger of denying

  1. Nítorí ó sọ pé: “ ‘Pẹ̀lú agbára ọwọ́ mi ni mo fi ṣe èyí àti pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀n mi, nítorí mo ní òye. Mo mú ààlà àwọn orílẹ̀-èdè kúrò, mo sì ti kó ìṣúra wọn. Gẹ́gẹ́ bí alágbára kan, mo borí àwọn ọba wọn.

  2. Bí ènìyàn ti í tọwọ́ bọ ìtẹ́ ẹyẹ, bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ mi tẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè. Bí ènìyàn ti í kó ẹyin tí a kọ̀sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni mo kó àwọn orílẹ̀-èdè kò sí èyí tí ó fi apá lu apá, tàbí kí ó ya ẹnu láti dún.’ ”

  3. Ǹjẹ́ àáké le gbé ara rẹ̀ sókè kọjá ẹni tí ó ń fì í, tàbí kí ayùn fọ́nnu sí ẹni tí ó ń lò ó? Àfi bí ẹni pé ọ̀pá ó na ẹni tí ó gbé e sókè, tàbí kí kùmọ̀ lu èyí tí kì í ṣe igi.

  4. Nítorí náà, ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, yóò rán ààrùn ìrẹ̀dànù sórí àwọn akíkanjú jagunjagun, lábẹ́ ògo rẹ̀ ni iná kan yóò ti sọ gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun.

  5. Ìmọ́lẹ̀ Israẹli yóò di iná, Ẹni Mímọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ ọ̀wọ́-iná, ní ọjọ́ kan ṣoṣo yóò jó yóò sì run àti ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n.

  6. “Ọmọ ènìyàn, sọ fún ọmọ-aládé Tire pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Nítorí tí ọkàn rẹ gbé sókè sí mi, ìwọ wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run; Èmi jókòó sí orí ìtẹ́ òrìṣà, ní àárín gbùngbùn Òkun.” Ṣùgbọ́n ènìyàn ni ọ́, kì i ṣe òrìṣà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ rò pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run.

  7. Ìwọ gbọ́n ju Daniẹli lọ bí? Ṣé kò sí àṣírí kan tí ó pamọ́ fún ọ?

  8. Pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ, ìwọ tí jèrè ọrọ̀ fún ara rẹ, àti àkójọpọ̀ wúrà àti fàdákà, nínú àwọn ilé ìṣúra rẹ.

  9. Nípa ọgbọ́n rẹ ńlá àti nípa òwò rẹ, ìwọ ti sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ̀, àti nítorí ọrọ̀ rẹ di púpọ̀, ọkàn rẹ gbé sókè, nítorí ọrọ̀ rẹ.

  10. “ ‘Nítorí náà èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Nítorí pé ìwọ rò pé o gbọ́n, pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run.

  11. Èmi yóò mú kí àwọn àjèjì dìde sí ọ, ẹlẹ́rù nínú àwọn orílẹ̀-èdè; wọn yóò yọ idà wọn sí ọ, ẹwà rẹ àti ọgbọ́n rẹ, wọn yóò sì ba dídán rẹ̀ jẹ́.

  12. Wọn yóò mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá sínú ihò, ìwọ yóò sì kú ikú gbígbóná, àwọn tí a pa ní àárín Òkun.

  13. Ṣé ìwọ yóò wá wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run,” ní ojú àwọn tí ó pa ọ́? Ìwọ yóò jẹ́ ènìyàn, kì í ṣe Ọlọ́run, ní ọwọ́ àwọn ti yóò pa ọ́.

  14. Ìwọ yóò kú ikú aláìkọlà, ní ọwọ́ àwọn àjèjì. Èmi ni ó ti sọ ọ́, ní Olúwa Olódùmarè wí.’ ”

  15. Lẹ́yìn oṣù kejìlá, bí ọba ṣe ń rìn káàkiri lórí òrùlé ààfin ìjọba Babeli,

  16. ó sọ pé, “Èyí ha kọ́ ni Babeli ńlá tí mo kọ́ gẹ́gẹ́ bí ilé ọba, nípa agbára à mi àti fún ògo ọláńlá à mi?”

  17. Bí ọba ṣe ń sọ ọ̀rọ̀ náà lọ́wọ́ ohùn kan wá láti ọ̀run, “Ìwọ Nebukadnessari ọba, ìwọ ni a ti pàṣẹ nípa rẹ̀, a ti gba ìjọba à rẹ kúrò ní ọwọ́ ọ̀ rẹ.

  18. Nítorí pé kò tí ì mọ̀ pé èmi ni àti ẹni tó fún un ní ọkà, ọtí wáìnì tuntun àti òróró ẹni tí ó fún un ní fàdákà àti wúrà lọ́pọ̀lọ́pọ̀, èyí tí wọ́n lò fún Baali.

  19. “Nítorí náà, èmi yóò mú ọkà mi kúrò nígbà tó bá pọ́n, èmi yóò sì mú wáìnì mi kúrò ní àsìkò rẹ̀. Èmi yóò sì gba irun àgùntàn àti ọ̀gbọ̀ mi padà ti mo ti fi fún un láti bo ìhòhò rẹ̀.