Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Providence of God: The wicked made to promote the designs

10 ẹsẹ · 41 abala

Àwọn ẹsẹ nípa The wicked made to promote the designs

  1. “Ègbé ni fún àwọn ará Asiria, ọ̀gọ ìbínú mi, ní ọwọ́ ẹni tí kùmọ̀ ìbínú mi wà!

  2. Mo rán an sí orílẹ̀-èdè aláìní Ọlọ́run, mo dojú rẹ̀ kọ àwọn ènìyàn tí ó mú mi bínú láti já ẹrù gbà, àti láti kó ìkógun láti tẹ̀ mọ́lẹ̀ bí amọ̀ ní ojú òpópó.

  3. Ṣùgbọ́n, èyí kì í ṣe ohun tí ó fẹ́ ṣe, èyí kọ́ ni ohun tí ó ní lọ́kàn; èrò rẹ̀ ni láti parun, láti fi òpin sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè.

  4. ‘Kì í ha ṣe pé ọba ni gbogbo àwọn aláṣẹ mi?’ ni Olúwa wí.

  5. ‘Kì í ha ṣe pé Kalno dàbí i Karkemiṣi? Hamati kò ha dàbí i Arpadi, àti Samaria bí i Damasku?

  6. Gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ti gbá ìjọba àwọn òrìṣà mú, ìjọba tí ère rẹ̀ pọ̀ ju ti Jerusalẹmu àti Samaria lọ.

  7. Èmi kì yóò a bá Jerusalẹmu wí àti àwọn ère rẹ̀?’ ” Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣe sí Samaria àti àwọn ère rẹ̀?

  8. Nígbà tí Olúwa ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ sí òkè Sioni àti Jerusalẹmu, yóò sọ wí pé, “Èmi yóò fi ìyà jẹ ọba Asiria nítorí gààrù àyà rẹ̀ àti ìgbéraga ojú rẹ̀.

  9. “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ará, mo mọ̀ pé nípa àìmọ̀ ni ẹ̀yin fi ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àwọn olórí yín pẹ̀lú ti ṣe.

  10. Ṣùgbọ́n báyìí ni Ọlọ́run ti ṣe ìmúṣẹ àwọn ohun tí ó ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu gbogbo àwọn wòlíì pé, Kristi rẹ̀ yóò jìyà.