Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Power of Christ

62 ẹsẹ · 34 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ìwọ yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn ìwọ yóò sì rún wọn wómúwómú bí ìkòkò amọ̀.”

  2. Àwọn ènìyàn rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtinúwá ní ọjọ́ ìjáde ogun rẹ, nínú ẹwà mímọ́, láti inú òwúrọ̀ wá ìwọ ni ìrì ẹwà rẹ.

  3. ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní, pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnu fún àwọn aláìní ayé. Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀, pẹ̀lú èémí ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà.

  4. Ta nì eléyìí tí ó Edomu wá, ti òun ti aṣọ àrẹpọ́n láti Bosra wá? Ta nì eléyìí, tí ó ní ògo nínú aṣọ rẹ̀, tí ó ń yan bọ̀ wá nínú ọláńlá agbára rẹ̀? “Èmi ni ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ nínú òdodo tí ó ní ipa láti gbàlà.”

  5. “Èmi nìkan ti dá tẹ ìfúntí wáìnì; láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹnikẹ́ni kò sì wà pẹ̀lú mi. Mo tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ ní ìbínú mi mo sì tẹ̀ wọ́n rẹ́ ní ìrunú mi ẹ̀jẹ̀ wọn sì fọ́n sí aṣọ mi, mo sì da àbàwọ́n sí gbogbo aṣọ mi.

  6. Nígbà tí Jesu sì parí sísọ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu ya àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn sí ẹ̀kọ́ rẹ̀,

  7. nítorí ó ń kọ́ wọn bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí i ti olùkọ́ òfin wọn.

  8. Ṣùgbọ́n ẹnu yà àwọn ọkùnrin náà, wọ́n sì béèrè pé, “Irú ènìyàn wo ni èyí? Kódà ìjì líle àti rírú omi Òkun gbọ́ tirẹ̀?”

  9. Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé Ọmọ Ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì ni.” Ó sì wí fún arọ náà pé, “Dìde, sì gbé àkéte rẹ, kí o sì máa lọ ilé rẹ.”

  10. Jesu sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí ọ̀dọ̀; ó fún wọn ní àṣẹ láti lé ẹ̀mí àìmọ́ jáde àti láti ṣe ìwòsàn ààrùn àti àìsàn gbogbo.

  11. Nígbà náà ni Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Gbogbo agbára ni ọ̀run àti ní ayé ni a ti fi fún mi.

  12. “Nígbà náà ni gbogbo ayé yóò sì rí i tí èmi Ọmọ Ènìyàn yóò máa bọ̀ wá láti inú àwọsánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.

  13. Àmì wọ̀nyí yóò sì máa bá àwọn tí ó gbàgbọ́ lọ. Ní orúkọ mi ni wọ́n yóò máa lé ẹ̀mí èṣù jáde. Wọn yóò máa fi èdè tuntun sọ̀rọ̀.

  14. Wọn yóò sì gbé ejò lọ́wọ́, bí wọ́n bá sì jẹ májèlé kò nípa wọ́n lára rárá. Wọ́n yóò gbé ọwọ́ lé àwọn aláìsàn, ara wọn yóò sì dá.”

  15. Ẹnu sì yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀: nítorí tàṣẹtàṣẹ ni ọ̀rọ̀ rẹ̀.

  16. Ní ọjọ́ kan, bí ó sì ti ń kọ́ni, àwọn Farisi àti àwọn amòfin jókòó pẹ̀lú rẹ̀, àwọn tí ó ti àwọn ìletò Galili gbogbo, àti Judea, àti Jerusalẹmu wá: agbára Olúwa sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ láti mú wọn láradá.

  17. Àwọn àádọ́rin náà sì fi ayọ̀ padà, wí pé, “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù tilẹ̀ foríbalẹ̀ fún wa ní orúkọ rẹ.”

  18. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo; lẹ́yìn rẹ̀ a kò sì dá ohun kan nínú ohun tí a ti dá.

  19. Òun sì wà ní ayé, àti pé, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a sì ti dá ayé, ṣùgbọ́n ayé kò sì mọ̀ ọ́n.

  20. Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wó tẹmpili yìí palẹ̀, Èmi ó sì tún un kọ ní ọjọ́ mẹ́ta.”

  21. Nígbà náà ní àwọn Júù wí pé, “Ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta ni a fi kọ́ tẹmpili yìí, ìwọ ó ha sì tún un kọ ní ọjọ́ mẹ́ta?”

  22. Ṣùgbọ́n òun ń sọ ti tẹmpili ara rẹ̀.

  23. Baba fẹ́ Ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo lé e lọ́wọ́.

  24. Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsin yìí, èmi náà sì ń ṣiṣẹ́.”

  25. Nítorí èyí ni àwọn Júù túbọ̀ ń wá ọ̀nà láti pa á, kì í ṣe nítorí pé ó ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó wí pẹ̀lú pé, Baba òun ni Ọlọ́run jẹ́, ó ń mú ara rẹ̀ bá Ọlọ́run dọ́gba.