Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Burnt Offering

46 ẹsẹ · 49 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ọ̀dọ́-àgùntàn kan ni ìwọ yóò fi rú ẹbọ ní òwúrọ̀ àti ọ̀dọ́-àgùntàn èkejì ní àṣálẹ́.

  2. Pẹ̀lú ọ̀dọ́-àgùntàn ti àkọ́kọ́ rú ẹbọ ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun dídára tí a fi ìdámẹ́rin hínì òróró lára olifi tí a gún, àti ìdámẹ́rin hínì wáìnì bí ẹbọ mímu.

  3. Ọ̀dọ́-àgùntàn kejì ni kí ìwọ kí ó pa rú ẹbọ ní àṣálẹ́ ìwọ yóò sì ṣe sí í gẹ́gẹ́ bí ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu bí ti òwúrọ̀ fún òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná ṣe ni sí Olúwa.

  4. “Fún ìrandíran tó ń bọ̀, ni ẹ ó máa ṣe ẹbọ sísun nígbà gbogbo ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ níwájú Olúwa. Níbẹ̀ èmi yóò pàdé yín, èmi yóò sì bá a yín sọ̀rọ̀;

  5. Lẹ́yìn èyí ó pa ẹran tó wà fún ẹbọ sísun. Àwọn ọmọ Aaroni sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó sì wọn yí pẹpẹ náà ká.

  6. Wọ́n sì ń mú ẹbọ sísun náà fún un ní ègé kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú orí rẹ̀, ó sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ.

  7. Ó fọ nǹkan inú rẹ̀ àti ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sun wọ́n lórí ẹbọ sísun tó wà lórí pẹpẹ.

  8. Ni ọjọ́ kejì, wọ́n rú ẹbọ sí Olúwa, wọ́n sì rú ẹbọ sísun sí i: ẹgbẹ̀rún (1,000) kan akọ màlúù, ẹgbẹ̀rin (1,000) kan àgbò, àti ẹgbẹ̀rin kan akọ ọ̀dọ́-àgùntàn. Lápapọ̀ pẹ̀lú ọrẹ mímu àti àwọn ẹbọ mìíràn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún gbogbo Israẹli.

  9. Wọ́n jẹ wọ́n sì mu pẹ̀lú ayọ̀ kíkún ní iwájú Olúwa ní ọjọ́ náà. Nígbà náà wọ́n yan Solomoni ọmọ Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba lẹ́ẹ̀kejì wọ́n fi àmì òróró yàn án níwájú Olúwa láti ṣe olórí àti Sadoku láti ṣe àlùfáà.

  10. Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni jókòó lórí ìtẹ́ Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọba ní ipò baba a rẹ̀ Dafidi. O ṣe àṣeyọrí, gbogbo Israẹli sì gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu.

  11. Èmí kò fẹ́ kí ó mú akọ màlúù láti inú ilé tí o kọ́ fún un, tàbí kí o mú òbúkọ láti inú agbo ẹran rẹ̀

  12. nítorí gbogbo ẹran igbó ni tèmi àti ẹran ọ̀sìn lórí ẹgbẹ̀rún (1,000) òkè.

  13. Èmi mọ gbogbo ẹyẹ ní orí àwọn òkè ńlá àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà ní orí ilẹ̀ ni tèmi.

  14. Bí ebi tilẹ̀ ń pa mí, èmi kì yóò sọ fún ọ, nítorí ayé ni tèmi àti ohun gbogbo tí ó wa ní inú rẹ̀.

  15. Ǹjẹ́ èmi yóò ha jẹ ẹran akọ màlúù tàbí mú ẹ̀jẹ̀ òbúkọ?

  16. “ ‘Èyí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: Tẹ̀síwájú kí ẹ kó ẹbọ sísun yín àti àwọn ẹbọ yòókù papọ̀ kí ẹ̀yin kí ó sì jẹ ẹran wọ́n fúnra yín.

  17. Ní tòsí nígbà tí mo mú àwọn baba ńlá yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti tí mo sì bá wọn sọ̀rọ̀. N kò pàṣẹ fún wọn lórí ẹbọ sísun lásán.

  18. Mo pàṣẹ fún wọn báyìí pé; gbọ́ tèmi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ènìyàn mi. Máa rìn ní ojú ọ̀nà tí mo pàṣẹ fún yín, kí ó lè dára fún yín.

  19. Nígbà tí o wí ni ìṣáájú pé, “Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọrẹ àti ẹbọ sísun, àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ni inú dídùn si wọn” (àwọn èyí tí a ń rú gẹ́gẹ́ bí òfin).

  20. Nígbà náà ni ó wí pé, “Kíyèsi i, mo de láti ṣe ìfẹ́ rẹ Ọlọ́run.” Ó mú ti ìṣáájú kúrò, kí a lè fi ìdí èkejì múlẹ̀.

  21. Nípa ìfẹ́ náà ni a ti sọ wá di mímọ́ nípa ẹbọ ti Jesu Kristi fi ara rẹ̀ rú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.