Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Strangers in Israel

65 ẹsẹ · 33 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Ní ti àwọn àlejò tí kì í ṣe Israẹli ènìyàn rẹ, ṣùgbọ́n tí ó ti ilẹ̀ òkèèrè jáde wá nítorí orúkọ rẹ,

  2. nítorí tí àwọn ènìyàn yóò gbọ́ orúkọ ńlá rẹ, àti ọwọ́ agbára rẹ, àti nínà apá rẹ, nígbà tí ó bá sì wá, tí ó sì gbàdúrà sí ìhà ilé yìí,

  3. nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, ní ibùgbé rẹ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí àlejò náà yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ, kí gbogbo ènìyàn ní ayé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọn kí ó sì máa bẹ̀rù rẹ, gẹ́gẹ́ bí Israẹli, ènìyàn rẹ ti ṣe, kí wọn kí ó sì le mọ̀ pé orúkọ rẹ ni a fi pe ilé yìí tí mo kọ́.

  4. Gbogbo ènìyàn tí ó kù nínú àwọn ará Amori ará Hiti, Peresi, Hifi àti Jebusi, àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ará Israẹli,

  5. Hiramu sì rán àwọn ènìyàn rẹ̀, àwọn atukọ̀ tí ó mọ Òkun, pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Solomoni.

  6. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi pàṣẹ láti kó àwọn àjèjì tí ń gbé ní Israẹli jọ, àti wí pé lára wọn ni ó ti yan àwọn agbẹ́-òkúta láti gbé òkúta dáradára láti fi kọ́lé Ọlọ́run.

  7. Solomoni ka iye àwọn àjèjì tí ó wà ní Israẹli lẹ́yìn kíka iye wọn tí baba a rẹ̀ Dafidi ti ṣe; a sì ka iye wọn sí ọ̀kẹ́ mẹ́jọ ó dín egbèjìlélọ́gbọ̀n (153,600).

  8. Ó sì yan ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin (70,000) nínú wọn láti ru ẹrù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) láti ṣe àgọ́ òkúta lórí òkè, àti egbèjìdínlógún (3,600) alábojútó láti kó àwọn ènìyàn ṣiṣẹ́.

  9. Gbogbo àwọn ènìyàn tí ó kúrò láti ara àwọn ará Hiti, ará Amori, ará Peresi, ará Hifi àti ará Jebusi àwọn ènìyàn wọ̀nyí wọn kì í ṣe àwọn ará Israẹli,

  10. Wọ́n pa àwọn opó àti àlejò, wọ́n sì pa àwọn ọmọ aláìní baba.

  11. Olúwa ń dá ààbò bo àwọn àlejò ó sì ń dá àwọn aláìní baba àti opó sí ṣùgbọ́n ó ba ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú jẹ́.

  12. Nínú rẹ wọn ti hùwà sí baba àti ìyá pẹ̀lú ìfojú tínrín; nínú rẹ wọn ti ni àwọn àlejò lára, wọn sì hùwàkiwà sí aláìní baba àti opó.

  13. Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, tí lo ìwà ìninilára, wọn sì já olè, wọn sì ni àwọn tálákà àti aláìní lára; nítòótọ́, wọn tí ní àlejò lára láìnídìí. Kò sì ṣí ìdájọ́ òdodo.

  14. Nítorí òun ni àlàáfíà wa, ẹni tí o ti ṣe méjèèjì ni ọ̀kan, tí ó sì ti wó ògiri ìkélé ti ìkórìíra èyí tí ń bẹ láàrín yín.

  15. Sì fi àgbàlá tí ń bẹ lóde tẹmpili sílẹ̀, má sì ṣe wọ́n ọ́n; nítorí tí a fi fún àwọn aláìkọlà: ìlú mímọ́ náà ni wọn ó sì tẹ̀ mọ́lẹ̀ ní oṣù méjìlélógójì (42).