- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Sin (1)
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Inú Olúwa sì bàjẹ́ gidigidi nítorí pé ó dá ènìyàn sí ayé, ọkàn rẹ̀ sì gbọgbẹ́.
Nítorí náà, Olúwa wí pé, “Èmi yóò pa ènìyàn tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀, ènìyàn àti ẹranko, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, nítorí inú mi bàjẹ́ pé mo ti dá wọn.”
Aaroni yóò sì gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé orí ààyè ewúrẹ́ náà, yóò sì jẹ́wọ́ gbogbo ìwà búburú àti ìṣọ̀tẹ̀ àwọn ara Israẹli lé e lórí. Gbogbo ìrékọjá wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni yóò sì gbé ka orí ewúrẹ́ náà. Yóò sì rán an lọ sí ijù láti ọwọ́ ẹni tí a yàn fún iṣẹ́ náà.
Wọ́n dìde ní àárọ̀ ọjọ́ kejì wọ́n sì gòkè lọ sí ìlú orí òkè, wọ́n wí pé, “Àwa ti ṣẹ̀, àwa yóò lọ sí ibi tí Olúwa ṣèlérí fún wa.”
Rí i dájú pé kò sí ọkùnrin tàbí obìnrin, ìdílé tàbí ẹ̀yà láàrín yín lónìí tí ọkàn an rẹ̀ yóò yí kúrò lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa láti lọ àti láti sin àwọn ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè náà; rí i dájú pé kò sí gbòǹgbò tí ó ń mú irú èso kíkan bẹ́ẹ̀ jáde láàrín yín.
Àyà Dafidi sì gbọgbẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí ó ka àwọn ènìyàn náà tán. Dafidi sì wí fún Olúwa pé, “Èmi ṣẹ̀ gidigidi ní èyí tí èmi ṣe, ṣùgbọ́n, èmi bẹ̀ ọ, Olúwa, fi ẹ̀ṣẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ jì ní, nítorí pé èmi hùwà aṣiwèrè gidigidi!”
Dafidi sì wí fún Olúwa nígbà tí ó rí angẹli tí ń kọlu àwọn ènìyàn pé, “Wò ó, èmi ti ṣẹ̀, èmi sì ti hùwà búburú ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn wọ̀nyí, kín ni wọ́n ha ṣe? Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ, èmi bẹ̀ ọ́, kí ó wà lára mi àti ìdílé baba mi.”
Lẹ́yìn nǹkan yìí, Jeroboamu kò padà kúrò nínú ọ̀nà búburú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó tún yan àwọn àlùfáà sí i fún àwọn ibi gíga nínú gbogbo àwọn ènìyàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ di àlùfáà, a yà á sọ́tọ̀ fún ibi gíga wọ̀nyí.
Èyí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jeroboamu, èyí tí ó yọrí sí ìṣubú rẹ̀, a sì pa á run kúrò lórí ilẹ̀.
Dafidi sì wí fún Ọlọ́run pé, “Èmi ha kọ́ ni mo pàṣẹ àti ka àwọn jagunjagun ènìyàn? Èmi ni ẹni náà tí ó dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe ohun búburú pàápàá, ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti àgùntàn wọ̀nyí, kí ni wọ́n ṣe? Èmí bẹ̀ ọ́ Olúwa Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára mi àti àwọn ìdílé baba mi, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí àjàkálẹ̀-ààrùn yìí kí ó dúró lórí àwọn ènìyàn rẹ.”
Àwọn baba wa jẹ́ aláìṣòótọ́; wọ́n sì ṣe ohun àìtọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa, wọ́n sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Wọ́n sì yí ojú wọn padà kúrò ní ibùgbé Olúwa, wọ́n sì pa ẹ̀yìn wọn dà sí i.
Nígbà náà ni gbogbo àwọn tí ó wárìrì sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Israẹli kó ara wọn jọ yí mi ká nítorí àìṣòótọ́ àwọn ìgbèkùn yìí. Èmi sì jókòó níbẹ̀ ní ìjayà títí di àkókò ìrúbọ àṣálẹ́.
Ní ìgbà tí ó di àkókò ìrúbọ àṣálẹ́, mo dìde kúrò nínú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn mi, pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti agbádá mi yíya ní ọrùn mi, mo kúnlẹ̀ lórí eékún mi méjèèjì, mo sì tẹ́ ọwọ́ mi méjèèjì sí Olúwa Ọlọ́run mi.
Mo sì gbàdúrà: “Ojú tì mí gidigidi, tí n kò fi lè gbé ojú mi sókè sí ọ̀dọ̀ rẹ, Ọlọ́run mi, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wá di púpọ̀ ní orí wa, ẹ̀bi wa sì ga kan àwọn ọ̀run.
Láti ọjọ́ àwọn baba wá ni ẹ̀bi wa ti pọ̀ jọjọ títí di ìsinsin yìí. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, àwa àti àwọn ọba wa àti àwọn àlùfáà wa ni a ti sọ di ẹni idà, ẹni ìgbèkùn, ìkógun àti ẹni ẹ̀sín lọ́wọ́ àwọn àjèjì ọba, bí ó ti rí lónìí.
“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, Ọlọ́run wa, kí ni àwa yóò wí lẹ́yìn èyí? Nítorí tí àwa kọ àṣẹ rẹ sílẹ̀
èyí tí ìwọ ti pa fún wa láti ẹnu àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ, nígbà ti ìwọ wí pé, ‘Ilẹ̀ náà ti ẹ̀yin ń wọ̀ lọ láti gbà n nì jẹ́ ilẹ̀ aláìmọ́ tó kún fún ẹ̀gbin àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, nípa ṣíṣe ohun ìríra àti híhu ìwà èérí ti kún ún láti ìkángun kan dé èkejì.
Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ọmọbìnrin yín fún àwọn ọmọkùnrin wọn ní ìyàwó tàbí kí ẹ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín ní ìyàwó. Ẹ má ṣe dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn nígbàkígbà kí ẹ̀yin kí ó sì le lágbára, kí ẹ sì le máa jẹ ire ilẹ̀ náà, kí ẹ sì le fi í sílẹ̀ fún àwọn ọmọ yín gẹ́gẹ́ bí ogún ayérayé.’
“Ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wa jẹ́ àyọríṣí iṣẹ́ búburú wa àti ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ńlá wa, síbẹ̀, Ọlọ́run wa, ìjìyà ti ìwọ fún wa kéré si ìjìyà tí ó yẹ fún ẹ̀ṣẹ̀ ti a dá, ìwọ sì fún wa ní àwọn ènìyàn tó ṣẹ́kù bí èyí.
Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwa tún yẹ̀ kúrò nínú àṣẹ rẹ, kí a sì máa ṣe ìgbéyàwó papọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọn ti ṣe onírúurú ohun ìríra báyìí? Ṣe ìwọ kò ní bínú sí wa láti pa wá run tí kì yóò sẹ́ ku ẹnikẹ́ni tí yóò là?
Ìwọ Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, ìwọ jẹ́ olódodo! Àwa ìgbèkùn tí ó ṣẹ́kù bí ó ti rí lónìí. Àwa dúró níwájú rẹ nínú ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nítorí èyí ẹnikẹ́ni nínú wa kò lè dúró níwájú rẹ”.
Jẹ́ kí etí rẹ kí ó ṣí sílẹ̀, kí ojú ù rẹ kí ó sì ṣí sílẹ̀ láti gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà ní iwájú rẹ ní ọ̀sán àti ní òru fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ènìyàn Israẹli. Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwa ọmọ Israẹli àti tèmi àti ti ilé baba mi, tí a ti ṣẹ̀ sí ọ.
Àwa ti ṣe búburú sí ọ. A kò sì pa àṣẹ ìlànà àti òfin tí ìwọ fún Mose ìránṣẹ́ rẹ mọ́.
“Rántí ìlànà tí o fún Mose ìránṣẹ́ rẹ, wí pé, ‘Bí ìwọ bá jẹ́ aláìṣòótọ́, èmi yóò fọ́n yín ká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè.
Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá yípadà sí mi, tí ẹ bá sì pa àṣẹ mi mọ́, nígbà náà bí àwọn ènìyàn yín tí a kó ní ìgbèkùn tilẹ̀ wà ní jìnnà réré ìpẹ̀kun ọ̀run, èmi yóò kó wọn jọ láti ibẹ̀, èmi yóò sì mú wọn wá, sí ibi tí èmi ti yàn bí i ibùgbé fún orúkọ mi.’