Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Silas

51 ẹsẹ · 7 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà tí ó sì béèrè iná, ó bẹ́ wọ inú ilé, ó ń wárìrì, ó wólẹ̀ níwájú Paulu àti Sila.

  2. Ó sì mú wọn jáde, ó ní, “Alàgbà, kín ni ki èmi ṣe ki n lè là?”

  3. Wọ́n sì wí fún un pé, “Gbá Jesu Kristi Olúwa gbọ́, a ó sì gbà ọ́ là, ìwọ àti àwọn ará ilé rẹ pẹ̀lú.”

  4. Wọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ Olúwa fún un, àti fún gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀.

  5. Ó sì mú wọn ní wákàtí náà lóru, ó wẹ ọgbẹ́ wọn; a sì bamitiisi rẹ̀, àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ lójúkan náà.

  6. Ó sì mú wọn wá sí ilé rẹ̀, ó sì gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú wọn, ó sì yọ̀ gidigidi pẹ̀lú gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, nítorí ó gba Ọlọ́run gbọ́.

  7. Ṣùgbọ́n nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn onídàájọ́ rán àwọn ọlọ́pàá pé, “Tú àwọn ènìyàn náà sílẹ̀.”

  8. Onítúbú sì sọ ọ̀rọ̀ náà fún Paulu, wí pé, “Àwọn onídàájọ́ ránṣẹ́ pé kí á da ìwọ àti Sila sílẹ̀. Ǹjẹ́ nísinsin yìí ẹ jáde kí ẹ sì máa lọ ní àlàáfíà.”

  9. Ṣùgbọ́n Paulu wí fún wọn pé, “Wọ́n lù wá ni gbangba, wọ́n sì sọ wá sínú túbú ni àìjẹ̀bi, àwa ẹni tí ì ṣe ara Romu. Ṣe nísinsin yìí wọ́n fẹ́ tì wá jáde níkọ̀kọ̀? Rara! Ṣùgbọ́n kí àwọn tìkára wọn wá mú wa jáde!”

  10. Àwọn ọlọ́pàá sì sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn onídàájọ́: ẹ̀rù sì bà wọ́n, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ará Romu ni Paulu àti Sila.

  11. Wọ́n sì wá, wọ́n ṣìpẹ̀ lọ́dọ̀ wọ́n, wọn sì mú wọn jáde, wọ́n sì bẹ̀ wọ́n pé, ki wọn jáde kúrò ni ìlú náà.

  12. Paulu àti Sila sì jáde nínú túbú, wọ́n sì wọ ilé Lidia lọ, nígbà tí wọn sì tí rí àwọn arákùnrin, wọ́n tù wọ́n nínú, wọn sì jáde kúrò.

  13. A sì yí nínú wọn lọ́kàn padà, wọ́n sì darapọ̀ mọ́ Paulu àti Sila, bákan náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn olùfọkànsìn Helleni àti nínú àwọn obìnrin ọlọ́lá, kì í ṣe díẹ̀.

  14. Ṣùgbọ́n àwọn Júù jowú, wọn sì fa àwọn jàgídíjàgan nínú àwọn ọmọ ènìyàn mọ́ra, wọ́n ko ẹgbẹ́ jọ, wọ́n sì ń dá ìlú rú; wọ́n sì kọlu ilé Jasoni, wọ́n ń fẹ́ láti mú Paulu àti Sila jáde tọ àwọn ènìyàn lọ.

  15. Nígbà tí wọn kò sì rí wọn, wọ́n wọ́ Jasoni, àti àwọn arákùnrin kan tọ àwọn olórí ìlú lọ, wọ́n ń kígbe pé, “Àwọn wọ̀nyí tí o tí dorí ayé kodò títí de ìhín yìí pẹ̀lú.

  16. Àwọn ẹni tí Jasoni gbà sí ọ̀dọ̀: gbogbo àwọn wọ̀nyí ni o sí ń hùwà lòdì sí àṣẹ Kesari, wí pé, ọba mìíràn kan wà tí í ṣe Jesu.”

  17. Àwọn ènìyàn àti àwọn olórí ìlú kò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ nǹkan wọ̀nyí.

  18. Nígbà tí wọ́n sì gbà onídùúró lọ́wọ́ Jasoni àti àwọn ìyókù, wọ́n fi wọ́n sílẹ̀ lọ.

  19. Lọ́gán àwọn arákùnrin sì rán Paulu àti Sila lọ ṣí Berea lóru. Nígbà tí wọ́n sí dé ibẹ̀, wọ́n wọ inú Sinagọgu àwọn Júù lọ.

  20. Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rán Paulu jáde lọ́gán láti lọ títí de etí Òkun, ṣùgbọ́n Sila àti Timotiu dúró ní Berea.

  21. Àwọn tí ó sin Paulu wá sì mú un lọ títí dé Ateni; nígbà tí wọ́n sì gba àṣẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wá fún Sila àti Timotiu pé, ki wọn ó yára tọ òun wá, wọ́n lọ.

  22. Nígbà tí Sila àti Timotiu sì tí Makedonia wá, ọ̀rọ̀ náà ká Paulu lára, ó ń fihàn fún àwọn Júù pé, Jesu ni Kristi náà.

  23. Nítorí pé Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí a tí wàásù rẹ̀ láàrín yín nípasẹ̀ èmí àti Silfanu àti Timotiu, kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n nínú rẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ ní.

  24. Paulu, Sila àti Timotiu, A kọ ọ́ sí ìjọ tí ó wà ní ìlú Tẹsalonika, àwọn ẹni tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run Baba àti ti Olúwa Jesu Kristi: Kí ìbùkún àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jesu Kristi kí ó jẹ́ tiyín.

  25. Paulu, Sila àti Timotiu, Sí ìjọ Tẹsalonika, nínú Ọlọ́run Baba wa àti Jesu Kristi Olúwa: