Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Sanitation

289 ẹsẹ · 10 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Kí ó pàṣẹ pé kí wọ́n fọ ohunkóhun tí ó bàjẹ́ náà kí ó sì wà ní ìpamọ́ fún ọjọ́ méje mìíràn.

  2. Lẹ́yìn tí ẹ bá ti fọ ohun tí ẹ̀tẹ̀ náà mú tan, kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí ẹ̀tẹ̀ náà kò bá yí àwọn aṣọ náà padà, bí kò tilẹ̀ tí ì ràn, àìmọ́ ni ó jẹ́. Ẹ fi iná sun un, yálà ẹ̀gbẹ́ kan tàbí òmíràn ni ẹ̀tẹ̀ náà dé.

  3. Bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò ti ẹ̀tẹ̀ náà bá ti kúrò níbẹ̀, lẹ́yìn tí a ti fọ ohunkóhun tí ó mú, kí ó ya ibi tí ó bàjẹ́ kúrò lára aṣọ náà, awọ náà, aṣọ híhun náà tàbí aṣọ títa náà.

  4. Ṣùgbọ́n bí ó bá tún ń farahàn níbi aṣọ náà, lára aṣọ títa náà, lára aṣọ híhun náà tàbí lára ohun èlò awọ náà, èyí fihàn pé ó ń ràn ká. Gbogbo ohun tí ẹ̀tẹ̀ náà bá wà lára rẹ̀ ni kí ẹ fi iná sun.

  5. Aṣọ náà, aṣọ títa náà, aṣọ híhun náà tàbí ohun èlò awọ náà tí a ti fọ̀ tí ó sì mọ́ lọ́wọ́ ẹ̀tẹ̀ náà ni kí a tún fọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Yóò sì di mímọ́.”

  6. Èyí ni òfin ààrùn, nínú aṣọ bubusu, ti aṣọ ọ̀gbọ̀, ti aṣọ títa, ti aṣọ híhun tàbí ti ohun èlò awọ, láti fihàn bóyá wọ́n wà ní mímọ́ tàbí àìmọ́.

  7. “Èyí ni àwọn ìlànà fún ẹni tí ààrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú ní àkókò ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, bí a bá mú un tọ àlùfáà wá.

  8. Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò ní ẹ̀yìn ibùdó bí ara rẹ̀ bá ti yá kúrò nínú ààrùn ẹ̀tẹ̀ náà.

  9. “Ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, fá gbogbo irun rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, lẹ́yìn èyí ó ti di mímọ́. Lẹ́yìn náà ó le wá sínú ibùdó ṣùgbọ́n kí ó wà lẹ́yìn àgọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ méje.

  10. Kí ó fá gbogbo irun rẹ̀ ní ọjọ́ keje: irun orí rẹ̀, irùngbọ̀n rẹ̀, irun ìpéǹpéjú rẹ̀, àti gbogbo irun rẹ̀ tókù. Kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì mọ́.

  11. “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kenaani tí mo fi fún yín ní ìní, tí mo sì fi ààrùn ẹ̀tẹ̀ sínú ilé kan ní ilẹ̀ ìní yín.

  12. Kí ẹni tí ó ní ilé náà lọ sọ fún àlùfáà pé, ‘Èmi tí rí ohun tí ó jọ ààrùn ẹ̀tẹ̀ ní ilé mi.’

  13. Àlùfáà yóò pàṣẹ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun má ṣe wà nínú ilé náà, kí ó tó lọ yẹ ẹ̀tẹ̀ náà wò, kí ohunkóhun nínú ilé náà má bá à di àìmọ́. Lẹ́yìn èyí àlùfáà yóò wọlé lọ láti yẹ ilé náà wò.

  14. Yóò yẹ ààrùn náà wò, bí ààrùn náà bá ti wà lára ògiri ilé náà nípa àmì àwọ̀ ewé tàbí àmì pupa tí ó sì jinlẹ̀, ju ara ògiri lọ.

  15. Àlùfáà yóò jáde kúrò nínú ilé náà, yóò sì ti ìlẹ̀kùn ilé náà pa fún ọjọ́ méje.

  16. Àlùfáà yóò padà wá yẹ ilé náà wò ní ọjọ́ keje. Bí ààrùn náà bá ti tàn ká ara ògiri.

  17. Àlùfáà yóò pàṣẹ kí a yọ àwọn òkúta tí ààrùn náà ti bàjẹ́ kúrò kí a sì kó wọn dànù sí ibi tí a kà sí àìmọ́ lẹ́yìn ìlú.

  18. Yóò sì mú kí wọ́n ha ògiri inú ilé náà yíká. Gbogbo ohun tí wọ́n fi rẹ́ ilé náà tí ó ti ha ni kí wọ́n kó dànù sí ibi tí a kà sí àìmọ́ lẹ́yìn ìlú náà.

  19. Òkúta mìíràn ni kí wọ́n fi dípò àwọn tí a ti yọ dànù, kí wọ́n sì rẹ́ ilé náà pẹ̀lú àwọn ohun ìrẹ́lé tuntun.

  20. “Bí ààrùn yìí bá tún farahàn lẹ́yìn tí a ti yọ àwọn òkúta wọ̀nyí tí a sì ti ha ilé náà ti a sì tún rẹ́ ẹ.

  21. Àlùfáà yóò tún lọ yẹ̀ ẹ́ wò bí ààrùn náà bá tún gbilẹ̀ sí i nínú ilé náà: ẹ̀tẹ̀ apanirun ni èyí, ilé náà jẹ́ aláìmọ́.

  22. Wíwó ni kí a wó o, gbogbo òkúta ilé náà, àwọn igi àti gbogbo ohun tí a fi rẹ́ ẹ ni kí a kó jáde nínú ìlú sí ibi tí a kà sí àìmọ́.

  23. “Ẹni tí ó bá wọ inú ilé náà lẹ́yìn tí a ti tì í, yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

  24. Ẹni tí ó bá sùn nínú ilé náà tàbí tí ó bá jẹun nínú rẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀.

  25. “Bí àlùfáà bá wá yẹ̀ ẹ́ wò tí ààrùn náà kò gbilẹ̀ mọ́ lẹ́yìn tí a ti rẹ́ ilé náà: kí àlùfáà pe ilé náà ní mímọ́, torí pé ààrùn náà ti lọ.