Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Sanitation: Penalties concerning

10 ẹsẹ · 10 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Penalties concerning

  1. Ṣùgbọ́n bí o kò bá gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì rọra máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mò ń fún ọ lónìí, gbogbo ègún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ.

  2. Olúwa yóò fi àjàkálẹ̀-ààrùn bá ọ jà títí tí yóò fi pa ọ́ run kúrò ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.

  3. Olúwa yóò kọlù ọ́ pẹ̀lú ààrùn ìgbẹ́, pẹ̀lú ibà àti àìsàn wíwú, pẹ̀lú ìjóni ńlá àti idà, pẹ̀lú ìrẹ̀dànù àti ìmúwòdù tí yóò yọ ọ́ lẹ́nu títí ìwọ yóò fi parun.

  4. Olúwa yóò bá ọ jà pẹ̀lú oówo, Ejibiti àti pẹ̀lú kókó, ojú egbò kíkẹ̀ àti ìhúnra.

  5. Olúwa yóò lu eékún àti ẹsẹ̀ rẹ pẹ̀lú oówo dídùn tí kò le san tán láti àtẹ̀lé méjèèjì rẹ lọ sí òkè orí rẹ.

  6. Gbogbo ègún yìí yóò wá sórí rẹ, wọn yóò lé ọ wọn yóò sì bá ọ títí tí ìwọ yóò fi parun, nítorí ìwọ kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ, ìwọ kò sì kíyèsi àṣẹ àti òfin tí ó fi fún ọ.

  7. Olúwa yóò sọ ìyọnu rẹ di ìyanu, àti ìyọnu irú-ọmọ ọ̀ rẹ, àní àwọn ìyọnu ńlá èyí tí yóò pẹ́, àti ààrùn búburú èyí tí yóò pẹ́.

  8. Olúwa yóò mú gbogbo ààrùn Ejibiti tí ó mú ẹ̀rù bà ọ́ wá padà bá ọ, wọn yóò sì lẹ̀ mọ́ ọ.

  9. Olúwa yóò tún mú onírúurú àìsàn àti ìpọ́njú tí a kò kọ sínú ìwé òfin yìí wá sórí rẹ, títí ìwọ yóò fi run.

  10. Ìwọ tí ó dàbí àìmoye bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò ṣẹ́ku kékeré níye, nítorí tí o kò ṣe ìgbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.