Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Sanitation

289 ẹsẹ · 10 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nínú gbogbo ẹranko tí ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn, àwọn tí ń fi èékánná wọn rìn jẹ́ aláìmọ́ fún yín, ẹni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

  2. Ẹni tí ó bá gbé òkú wọn gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Wọ̀nyí jẹ́ àìmọ́ fún yín.

  3. “ ‘Nínú gbogbo ẹranko tí ń rìn lórí ilẹ̀ ìwọ̀nyí ni ó jẹ́ àìmọ́ fún yín: Asé, eku àti oríṣìíríṣìí aláǹgbá,

  4. Ọmọnílé, alágẹmọ, aláǹgbá, ìgbín àti ọ̀gà.

  5. Nínú gbogbo ohun tí ń rìn lórí ilẹ̀, ìwọ̀nyí jẹ́ àìmọ́ fún yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

  6. Bí ọ̀kan nínú wọn bá kú tí wọ́n sì bọ́ sórí nǹkan kan, bí ó ti wù kí irú ohun náà wúlò tó, yóò di aláìmọ́ yálà aṣọ ni a fi ṣe é ni tàbí igi, irun aṣọ tàbí àpò, ẹ sọ ọ́ sínú omi yóò jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́ lẹ́yìn náà ni yóò tó di mímọ́.

  7. Bí èyíkéyìí nínú wọn bá bọ́ sínú ìkòkò amọ̀, gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀ ti di àìmọ́. Ẹ gbọdọ̀ fọ ìkòkò náà.

  8. Bí omi inú ìkòkò náà bá dà sórí èyíkéyìí nínú oúnjẹ tí ẹ̀ ń jẹ oúnjẹ náà di aláìmọ́. Gbogbo ohun mímu tí a lè mú jáde láti inú rẹ̀ di àìmọ́.

  9. Gbogbo ohun tí èyíkéyìí nínú òkú wọn bá já lé lórí di àìmọ́. Yálà ààrò ni tàbí ìkòkò ìdáná wọn gbọdọ̀ di fífọ́. Wọ́n jẹ́ àìmọ́. Ẹ sì gbọdọ̀ kà wọ́n sí àìmọ́.

  10. Bí òkú wọn bá bọ́ sínú omi tàbí kànga tó ní omi nínú, omi náà kò di aláìmọ́ ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá yọ òkú wọn jáde tí ó fi ọwọ́ kàn án yóò di aláìmọ́.

  11. Bí òkú ẹranko wọ̀nyí bá bọ́ sórí ohun ọ̀gbìn tí ẹ fẹ́ gbìn wọ́n sì jẹ́ mímọ́.

  12. Ṣùgbọ́n bí ẹ bá ti da omi sí ohun ọ̀gbìn náà tí òkú wọn sì bọ́ sí orí rẹ̀ àìmọ́ ni èyí fún un yín.

  13. “ ‘Bí ẹran kan bá kú nínú àwọn tí ẹ lè jẹ, ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú rẹ̀ yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

  14. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ èyíkéyìí nínú òkú ẹranko náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé òkú ẹranko yóò fọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wà ní àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

  15. “ ‘Ìríra ni gbogbo ohun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ jẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n.

  16. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ń rìn ká orí ilẹ̀ yálà ó ń fàyàfà tàbí ó ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn, tàbí ó ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹsẹ̀ rìn ìríra ni èyí.

  17. Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fi ohun kan tí ń rákò, sọ ara yín di ìríra, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fi wọ́n sọ ara yín di aláìmọ́, tí ẹ̀yin yóò fi ti ipa wọn di eléèérí.

  18. “ ‘Àwọn wọ̀nyí ni ìlànà fún ẹranko, ẹyẹ, gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi àti àwọn ẹ̀dá tí ó ń rìn lórí ilẹ̀.

  19. Ẹ gbọdọ̀ mọ ìyàtọ̀ láàrín àìmọ́ àti mímọ́ láàrín ẹ̀dá alààyè, tí ẹ le jẹ àti èyí tí ẹ kò le jẹ.’ ”

  20. “Sọ fún àwọn ará Israẹli pé: ‘Obìnrin tí ó bá lóyún tí ó sì bí ọmọkùnrin, yóò wà láìmọ́ fún ọjọ́ méje bí ìgbà tí ó wà ní ipò àìmọ́ lákokò nǹkan oṣù rẹ̀.

  21. Ní ọjọ́ kẹjọ ni kí ẹ kọ ọmọ náà ní ilà.

  22. Obìnrin náà yóò sì dúró fún ọjọ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n láti di mímọ́ kúrò nínú ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ kan ohunkóhun tí ó jẹ́ mímọ́ tàbí kí ó lọ sí ibi mímọ́ Olúwa títí di ọjọ́ tí ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ yóò kọjá.

  23. Bí ó bá ṣe obìnrin ni ó bí, fún ọ̀sẹ̀ méjì ni obìnrin náà yóò fi wà ní ipò àìmọ́, gẹ́gẹ́ bí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀. Ó sì gbọdọ̀ dúró ní ọjọ́ mẹ́rìndínláàádọ́rin láti di mímọ́ kúrò nínú ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

  24. “Bí ẹnikẹ́ni bá ní ìwú, èélá tàbí àmì dídán kan ní ara rẹ̀, èyí tí ó le di ààrùn awọ ara tí ó le ràn ká. Ẹ gbọdọ̀ mú un tọ́ Aaroni àlùfáà lọ tàbí sí ọ̀dọ̀ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó jẹ́ àlùfáà.

  25. Àlùfáà náà ni ó gbọdọ̀ yẹ egbò ara rẹ̀ wò: bí irun egbò náà bá di funfun tí egbò náà sì dàbí i pé ó jinlẹ̀ kọjá awọ ara: èyí jẹ́ ààrùn ara tí ó le è ràn, bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò kí ó sọ ọ́ di mí mọ̀ pé aláìmọ́ ni ẹni náà.