Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Sanctification

117 ẹsẹ · 28 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ọlọ́run sì súre fún ọjọ́ keje, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ní ọjọ́ náà ni ó sinmi kúrò nínú iṣẹ́ dídá ayé tí ó ti ń ṣe.

  2. “Ẹ ya àwọn àkọ́bí yín ọkùnrin sọ́tọ̀ fún mi. Èyí ti ó bá jẹ́ àkọ́bí láàrín àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ tèmi, ìbá à ṣe ènìyàn tàbí ẹranko.”

  3. Olúwa sì wí fún Mose pé, “Tọ àwọn ènìyàn lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ ni òní àti ni ọ̀la. Jẹ́ kí wọn kí ó fọ aṣọ wọn.

  4. Mose sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, ó yà wọ́n sí mímọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn.

  5. Ní ọjọ́ méje ni ìwọ yóò ṣe ètùtù sí pẹpẹ náà, ìwọ yóò sì sọ ọ́ di mímọ́. Nígbà náà ni pẹpẹ náà yóò jẹ́ mímọ́ jùlọ, àti ohunkóhun tí ó bá fi ọwọ́ kàn án yóò jẹ́ mímọ́.

  6. níbẹ̀ sì tún ni èmi yóò pàdé àwọn ọmọ Israẹli, a ó sì fi ògo mi ya àgọ́ náà sí mímọ́.

  7. Ìwọ yóò sì sọ wọ́n di mímọ́, nítorí kí wọn lè jẹ́ mímọ́ jùlọ, àti ohunkóhun tí ó bá fi ọwọ́ kàn wọn yóò di mímọ́.

  8. “Kí ìwọ kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ẹ̀yin gbọdọ̀ máa pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́. Èyí ni yóò jẹ́ àmì láàrín Èmi àti ẹ̀yin fún ìrandíran tó ń bọ̀, nítorí kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé Èmi ni Olúwa, ẹni tí ó yà yín sí mímọ́.

  9. Báwo ni ẹnikẹ́ni yóò ṣe mọ̀ pé inú rẹ dùn pẹ̀lú mi àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ àyàfi ti o bá bá wa lọ? Kí ni yóò lè yà mí àti àwọn ènìyàn rẹ kúrò lára gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé?”

  10. “Mú òróró ìtasórí, kí ó sì ta á sára àgọ́ náà àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀, yà pẹpẹ sí mímọ́ àti gbogbo ọ̀ṣọ́ rẹ̀, yóò sì jẹ́ mímọ́.

  11. Ta òróró sára pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, ya pẹpẹ náà sí mímọ́, yóò sì jẹ́ mímọ́ jùlọ.

  12. Ta òróró sára agbada náà àti ẹsẹ̀ rẹ, kí o sì yà wọ́n sí mímọ́.

  13. “Mú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ, kí o sì wẹ̀ wọ́n pẹ̀lú omi.

  14. Nígbà náà wọ Aaroni ní aṣọ mímọ́, ta òróró sí i ní orí, kí o sì yà á sí mímọ́, nítorí kí ó lè máa sìn mi bí àlùfáà.

  15. Mú àwọn ọmọ rẹ̀ kí o sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n.

  16. Ta òróró sí wọn ní orí gẹ́gẹ́ bí o ti ta òróró sí baba wọn ní orí, nítorí kì wọn lè máa sìn mi bí àlùfáà. Ìtasórí wọn yóò jẹ́ iṣẹ́ àlùfáà ti yóò máa lò fún gbogbo ìrandíran tó ń bọ̀.”

  17. Nígbà náà ni àwọsánmọ̀ bo àgọ́ àjọ, ògo Olúwa bo àgọ́ náà.

  18. Mose kò sì lè wọ inú àgọ́ àjọ, nítorí àwọsánmọ̀ wà ní orí àgọ́, ògo Olúwa sì ti kún inú àgọ́ náà.

  19. Ẹ máa kíyèsi àṣẹ mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́. Èmi ni Olúwa tí ó sọ yín di mímọ́.

  20. Olúwa sọ fún Mose wí pe, “Bá àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Aaroni sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹnikẹ́ni nínú wọn kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nítorí àwọn ènìyàn wọn tí ó kù.

  21. Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe àwọn tí ó súnmọ́ ọn bí ìyá rẹ̀, baba rẹ̀, ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí obìnrin, àti arákùnrin rẹ̀.

  22. Tàbí fún arábìnrin rẹ̀ tí kò ì tí ì wọ ilé ọkọ tí ó ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorí tí arábìnrin bẹ́ẹ̀, ó lè sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́.

  23. Nítorí tí ó jẹ́ olórí, òun kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ ba ara rẹ̀ jẹ́ láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

  24. “ ‘Àlùfáà kò gbọdọ̀ fá irun orí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ rẹ́ irùngbọ̀n rẹ̀. Kò gbọdọ̀ fi abẹ ya ara rẹ̀ láti fihàn pé òun wà ní ipò ọ̀fọ̀.

  25. Wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún Ọlọ́run, kí wọ́n má ba à sọ orúkọ Ọlọ́run wọn di àìmọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń fi iná sun ẹbọ sí Olúwa wọn, ti ó jẹ oúnjẹ Ọlọ́run wọn. Nítorí náà wọn gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́.