Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Redemption

144 ẹsẹ · 59 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà tí mo wá, èéṣe tí a kò fi rí ẹnìkan? Nígbà tí mo pè, èéṣe tí kò fi sí ẹnìkan láti dáhùn? Ọwọ́ mi a kúrú láti gbà ọ́? Èmi kò ha ní agbára láti gbà ọ́ bí? Nípa ìbáwí lásán, Èmi gbẹ omi òkun, Èmi yí àwọn odò sí aṣálẹ̀; àwọn ẹja wọn rà fún àìsí omi wọ́n sì kú fún òǹgbẹ.

  2. Àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá. Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin kíkọ; ayọ̀ ayérayé ni yóò sì bo orí wọn. Ayọ̀ àti inú dídùn yóò sì bà lé wọn ìbànújẹ́ àti ìtìjú yóò sì sá kúrò.

  3. Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Ọ̀fẹ́ ni a tà ọ́, láìsanwó ni a ó sì rà ọ́ padà.”

  4. Nínú gbogbo ìpọ́njú wọn, inú òun pẹ̀lú bàjẹ́ àti angẹli tí ó wà níwájú rẹ̀ gbà wọ́n là. Nínú ìfẹ́ àti àánú rẹ̀, ó rà wọ́n padà; ó gbé wọn sókè ó sì pọ̀n wọ́n ní gbogbo ọjọ́ ìgbà n nì.

  5. “Èmi yóò gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ìkà ènìyàn, Èmi yóò sì rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.”

  6. Olúwa, ìwọ gba ẹjọ́ mi rò, o ra ẹ̀mí mi padà.

  7. “Èmi yóò rà wọ́n padà kúrò lọ́wọ́ agbára isà òkú. Èmi yóò rà wọ́n padà lọ́wọ́ ikú, ikú, àjàkálẹ̀-ààrùn rẹ dà? Isà òkú, ìparun rẹ dà? “Èmi kò ní ṣàánú mọ́.

  8. Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ènìyàn kò ṣe wá sí ayé, kí ẹ lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, ṣùgbọ́n láti ṣe ìránṣẹ́ fún yín, àti láti fi ẹ̀mí rẹ ṣe ìràpadà ọ̀pọ̀ ènìyàn.”

  9. “Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli; nítorí tí ó ti bojú wò, tí ó sì ti dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè,

  10. “Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún ni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.

  11. Ẹ kíyèsára yin, àti sí gbogbo agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alábojútó rẹ̀, láti máa tọ́jú ìjọ Ọlọ́run, tí ó tí fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ rà.

  12. àwọn ẹni tí a ń dá láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, nípa ìdáǹdè tí ó wà nínú Kristi Jesu.

  13. Nísinsin yìí, bí àwa bá kú pẹ̀lú Kristi àwa gbàgbọ́ pé àwa yóò wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀.

  14. Nísinsin yìí, ẹ ti dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ọ̀gá yín àtijọ́, èyí tí í ṣe ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ẹrú ọ̀gá tuntun èyí ni òdodo.

  15. Ṣùgbọ́n báyìí, ẹ ti bọ́ kúrò lọ́wọ́ agbára ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ẹrú Ọlọ́run àwọn ìbùkún rẹ̀ sí yin ni ìwà mímọ́ àti ìyè tí kò nípẹ̀kun.

  16. Kì í ṣe àwọn nìkan, ṣùgbọ́n àwa tìkára wa pẹ̀lú, a ni àkóso ẹ̀mí, àní àwa tìkára wa ń kérora nínú ara wa, àwa ń dúró de ìsọdọmọ àní ìdáǹdè ara wa.

  17. Nítorí rẹ̀ ni ẹ̀yin ṣe wà nínú Kristi Jesu ẹni ti ó jásí ọgbọ́n fún wa láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run—èyí ń ni, òdodo, ìwà mímọ́ àti ìràpadà wa.

  18. nítorí a ti rà yín ni iye kan. Nítorí náà ẹ yìn Ọlọ́run lógo nínú ara yín, àti nínú ẹ̀mí yín, tì í ṣe ti Ọlọ́run.

  19. A sì ti rà yín ní iye kan, nítorí náà ẹ má ṣe di ẹrú ènìyàn.

  20. ó sì fi èdìdì rẹ̀ dì wá pẹ̀lú, ó sì tí fi Ẹ̀mí rẹ́ sí wa ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìdánilójú ohun tí ó ń bọ̀.

  21. ẹni tí ó fi òun tìkára rẹ̀ dípò ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó lè gbà wá kúrò nínú ayé búburú ìsinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run àti Baba wa,

  22. Kristi ti rà wá padà kúrò lọ́wọ́ ègún òfin, ẹni tí a fi ṣe ègún fún wa: nítorí tí a ti kọ ọ́ pé, “Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí a fi kọ́ sórí igi.”

  23. Ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kíkún náà dé, Ọlọ́run rán ọmọ rẹ̀ jáde wá, ẹni tí a bí nínú obìnrin tí a bí lábẹ́ òfin.

  24. Láti ra àwọn tí ń bẹ lábẹ́ òfin padà, kí àwa lè gba ìsọdọmọ.

  25. Nínú rẹ̀ ni àwa rí ìràpadà gba nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ àti ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run