Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Redemption: Wait for the completion of
Àwọn ẹsẹ nípa Wait for the completion of
Kì í ṣe àwọn nìkan, ṣùgbọ́n àwa tìkára wa pẹ̀lú, a ni àkóso ẹ̀mí, àní àwa tìkára wa ń kérora nínú ara wa, àwa ń dúró de ìsọdọmọ àní ìdáǹdè ara wa.
Nítorí ìlú ìbílẹ̀ wá ń bẹ̀ ní ọ̀run, láti ibi ti àwa pẹ̀lú gbé ń fojúsọ́nà fún Olùgbàlà, Jesu Kristi Olúwa.
Ẹni tí yóò sọ ara ìrẹ̀lẹ̀ wa di ọ̀tún kí ó lè bá ara ògo rẹ̀ mu, nípa agbára tí ó mú kí ó ṣe é ṣe fún un láti tẹ orí ohun gbogbo bá fún ara rẹ̀.
Nítorí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tó mú ìgbàlà wà ti fi ara hàn fún gbogbo ènìyàn.
Ó ń kọ́ wa láti sẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ayé, kí a sì máa wà ní àìrékọjá, ní òdodo àti ní ìwà-bí-Ọlọ́run ní ayé ìsinsin yìí,
bí a ti ń wọ́nà fún ìrètí tó ní bùkún, èyí ń ní ìfarahàn ògo Ọlọ́run wa tí ó tóbi àti Olùgbàlà wa Jesu Kristi.