Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Redemption: A subject for praise
Àwọn ẹsẹ nípa A subject for praise
Èmi ti gbá gbogbo ìkùnà rẹ dànù bí i kurukuru, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ bí ìrì òwúrọ̀. Padà sọ́dọ̀ mi, nítorí mo ti rà ọ́ padà.”
Kọrin fáyọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí Olúwa ló ti ṣe èyí; kígbe sókè, ìwọ ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀. Bú sí orin, ẹ̀yin òkè ńlá, ẹ̀yin igbó àti gbogbo igi yín, nítorí Olúwa ti ra Jakọbu padà, ó ti fi ògo rẹ̀ hàn ní Israẹli.
Àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá. Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin kíkọ; ayọ̀ ayérayé ni yóò sì bo orí wọn. Ayọ̀ àti inú dídùn yóò sì bà lé wọn ìbànújẹ́ àti ìtìjú yóò sì sá kúrò.