Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Rebellion Against God

148 ẹsẹ · 63 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Èmi yóò sì tú yín ká sínú àwọn orílẹ̀-èdè, Èmi yóò sì yọ idà tì yín lẹ́yìn, ilẹ̀ yín yóò sì di ahoro, àwọn ìlú yín ni a ó sì parun.

  2. Ilẹ̀ náà yóò ní ìsinmi fún gbogbo ìgbà tí ẹ fi wà ní ilẹ̀ àjèjì tí ẹ kò fi lò ó. Ilẹ̀ náà yóò sinmi láti fi dípò ọdún tí ẹ kọ̀ láti fún un.

  3. Níwọ́n ìgbà tí ẹ kò lò ó, ilẹ̀ náà yóò ní ìsinmi tí kò ní lákòókò ìsinmi rẹ̀ lákokò tí ẹ fi ń gbé orí rẹ̀.

  4. “ ‘Èmi yóò jẹ́ kí ó burú fún àwọn tí ó wà ní ilẹ̀ ìgbèkùn dé bi pé ìró ewé tí ń mì lásán yóò máa lé wọn sá. Ẹ ó máa sá bí ẹni tí ń sá fún idà. Ẹ ó sì ṣubú láìsí ọ̀tá láyìíká yín.

  5. Wọn yóò máa ṣubú lu ara wọn, bí ẹni tí ń sá fún idà nígbà tí kò sí ẹni tí ń lé yín. Ẹ̀yin kì yóò sì ní agbára láti dúró níwájú ọ̀tá yín.

  6. Ẹ̀yin yóò ṣègbé láàrín àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà. Ilẹ̀ ọ̀tá yín yóò sì jẹ yín run.

  7. Àwọn tí ó ṣẹ́kù nínú yín ni yóò ṣòfò dànù ní ilẹ̀ ọ̀tá yín torí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ti àwọn baba ńlá yín.

  8. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa. Kí ẹ sì má bẹ̀rù àwọn ènìyàn ìlú náà, nítorí pé a ó gbé wọn mì, ààbò wọn ti fi wọ́n sílẹ̀, Olúwa sì wà pẹ̀lú àwa, ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn.”

  9. Olúwa ni ìwọ àti gbogbo ẹlẹgbẹ́ rẹ takò. Ta a ni Aaroni jẹ́ tí ẹ̀yin ó fi kùn sí i?”

  10. Ṣùgbọ́n bí Olúwa bá ṣe ohun tuntun, tí ilẹ̀ sì la ẹnu, tó gbé wọn mì, àwọn pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ní, tí wọ́n sì wọ inú ibojì wọn lọ láààyè, nígbà náà ni ẹ̀yin ó mọ̀ pé àwọn ènìyàn yìí ti kẹ́gàn Olúwa.”

  11. wọ́n bá Mose jà wọ́n sì wí pé, “Ìbá kúkú sàn kí a kú nígbà tí àwọn arákùnrin ti kú níwájú Olúwa!

  12. Òun àti Aaroni pe àwọn ènìyàn jọ sí ojú kan níwájú àpáta, Mose sì sọ fún wọn, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀, àwa kì yóò lè mú omi jáde láti inú àpáta yìí wá bí?”

  13. Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé, “Nítorí pé ẹ̀yin kò gbà mí gbọ́ tó láti bu ọlá fún mi níwájú àwọn ọmọ Israẹli, ìwọ kò ní kó àwọn ìjọ ènìyàn yìí dé ilẹ̀ tí mo fún wọn.”

  14. “Aaroni yóò kú. Kò ní wọ ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí ẹ̀yin méjèèjì ṣe àìgbọ́ràn sí òfin mi níbi omi Meriba.

  15. Ẹ rántí, ẹ má sì ṣe gbàgbé bí ẹ̀yin ti mú Olúwa Ọlọ́run yín bínú ní aginjù. Láti ọjọ́ ti ẹ tí kúrò ní Ejibiti ni ẹ̀yin ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa títí tí ẹ̀yin fi dé ìhín yìí.

  16. Nígbà tí Olúwa ran an yín jáde ní Kadeṣi-Barnea, Ó wí pé, “Ẹ gòkè lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín.” Ṣùgbọ́n ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí òfin Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ kò gbẹ́kẹ̀lé e, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́ tirẹ̀.

  17. Láti ìgbà tí mo ti mọ̀ yín ni ẹ ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa.

  18. Bí ìwọ bá gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ ní kíkún kí o sì kíyèsára láti tẹ̀lé gbogbo ohun tí ó pàṣẹ tí mo fi fún ọ lónìí, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbé ọ lékè ju gbogbo orílẹ̀-èdè ayé lọ.

  19. Gbogbo ìbùkún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ bí o bá gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.

  20. Ìbùkún ni fún ọ ni ìlú, ìbùkún ni fún ọ ní oko.

  21. Ìbùkún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èso ilẹ̀ rẹ, àti irú ohun ọ̀sìn rẹ àti ìbísí i màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ.

  22. Ìbùkún ni fún agbọ̀n rẹ àti fún ọpọ́n ipò ìyẹ̀fun rẹ.

  23. Ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá wọlé, ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde.

  24. Olúwa yóò gbà fún ọ pé gbogbo ọ̀tá tí ó dìde sí ọ yóò bì ṣubú níwájú rẹ. Wọn yóò tọ̀ ọ́ wá ní ọ̀nà kan ṣùgbọ́n wọn yóò sá fún ọ ní ọ̀nà méje.

  25. Olúwa yóò rán ìbùkún sí ọ àti sí ohun gbogbo tí o bá dáwọ́ rẹ lé. Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún un fún ọ nínú ilẹ̀ tí ó ń fi fún ọ.