Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Purification

100 ẹsẹ · 13 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Yóò sì fi omi wẹ ara rẹ̀ ní ibi mímọ́ kan, yóò sì wọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wá ṣí iwájú, yóò sì rú ẹbọ sísun ti ara rẹ̀ àti ẹbọ sísun ti àwọn ènìyàn láti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti fún àwọn ènìyàn.

  2. “Ẹni tí ó tú ewúrẹ́ ìpààrọ̀ náà sílẹ̀ yóò sì fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì wẹ ara rẹ̀ nínú omi, lẹ́yìn èyí ó lè wá sí ibùdó.

  3. Ẹni tí ó sun wọ́n yóò sì fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì wẹ ara rẹ̀, lẹ́yìn èyí ni ó tó le wọ ibùdó.

  4. “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohun tí ó kú sílẹ̀ fúnra rẹ̀, tàbí èyí tí ẹranko búburú pa kálẹ̀ yálà onílé tàbí àlejò, ó ní láti fọ aṣọ rẹ̀. Kí ó sì fi omi wẹ ara rẹ̀, yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di àṣálẹ́ lẹ́yìn èyí ni yóò tó di mímọ́.

  5. “Sọ fún wọn pé, ‘Fún àwọn ìran tí ń bọ̀. Bí ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ yín tí kò mọ́ bá wá sí ibi ọrẹ mímọ́ tí àwọn ara Israẹli ti yà sọ́tọ̀ fún Olúwa, kí ẹ yọ ẹni náà kúrò nínú iṣẹ́ àlùfáà ní iwájú mi. Èmi ni Olúwa.

  6. “Yọ àwọn ọmọ Lefi kúrò láàrín àwọn ọmọ Israẹli yòókù, kí o sì wẹ̀ wọ́n mọ́.

  7. Báyìí ni kí o ṣe wẹ̀ wọ́n mọ́. Wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ sí wọn lára, mú kí wọn ó fá irun ara wọn, kí wọn ó fọ aṣọ wọn, kí wọn ó ba à lè wẹ ara wọn mọ́ nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀.

  8. Àwọn ọmọ Lefi wẹ ara wọn mọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. Aaroni sì mú wọn wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì níwájú Olúwa, Aaroni sì ṣe ètùtù fún wọn láti wẹ̀ wọ́n mọ́.

  9. Lẹ́yìn náà, àlùfáà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi lẹ́yìn náà ó lè wá sínú àgọ́. Ṣùgbọ́n yóò jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

  10. Ẹni tí ó sun ún náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ pẹ̀lú omi, òun náà yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

  11. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú ẹnìkan tí kò sì wẹ ara rẹ̀ mọ́, ó ba àgọ́ Olúwa jẹ́. A ó ké irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ọmọ Israẹli. Nítorí pé a kò tí ì wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ lé e lórí, ó jẹ́ aláìmọ́, àìmọ́ rẹ̀ sì wà lára rẹ̀.

  12. “Fún aláìmọ́ ènìyàn, mú eérú díẹ̀ lára eérú ọrẹ ìwẹ̀nùmọ́ sínú ìgò, kí o sì da omi tó ń sàn lé e lórí.

  13. Nígbà náà, ọkùnrin tí a yà sí mímọ́ yóò mú hísópù díẹ̀ yóò rì í sínú omi yóò sì fi wọ́n àgọ́ àti gbogbo ohun èlò tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ àti àwọn ènìyàn tí ó wà níbẹ̀. O gbọdọ̀ tún fi wọ́n ẹnikẹ́ni tí ó fi ọwọ́ kan egungun òkú ènìyàn tàbí isà òkú, tàbí ẹni tí ó kú ikú ara rẹ̀, tàbí ẹni tí ó kú ikú àti ọ̀run wá.

  14. Ọkùnrin tí ó mọ́ ni kí ó bu omi wọ́n àwọn ènìyàn aláìmọ́ ní ọjọ́ kẹta àti ọjọ́ keje, ní ọjọ́ keje ó gbọdọ̀ wẹ ara rẹ̀ mọ́. Ẹni tí a wẹ̀mọ́ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ pẹ̀lú omi, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà yóò mọ́.

  15. Ṣùgbọ́n bí ẹni tí ó bá jẹ́ aláìmọ́ kò bá wẹ ara rẹ̀ mọ́, a gbọdọ̀ gé e kúrò nínú ìjọ ènìyàn, nítorí wí pé ó ti ba àgọ́ Olúwa jẹ́. A kò tí ì fi omi ìwẹ̀nùmọ́ sí ara rẹ̀, ó sì jẹ́ aláìmọ́.

  16. Èyí jẹ́ ìlànà láéláé fún wọn. “Ọkùnrin tí ó wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ àti ẹnikẹ́ni tí ó fi ọwọ́ kan omi ìwẹ̀nùmọ́ yóò di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

  17. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti pa ènìyàn tàbí fọwọ́ kan ẹni tí a pa gbọdọ̀ dúró ní ìta ibùdó àgọ́ fún ọjọ́ méje. Ní ọjọ́ kẹta àti ọjọ́ keje ẹ gbọdọ̀ ya ara yín àti ẹni tí ẹ kó lẹ́rú sí mímọ́.

  18. Kí ẹ̀yin kí ó ya aṣọ yín sí mímọ́ àti gbogbo ohun tí a fi awọ ṣe àti gbogbo iṣẹ́ irun ewúrẹ́ àti ohun tí a fi igi ṣe.”

  19. Eleasari àlùfáà sì wí fún àwọn olórí ogun náà pé, “Èyí ní ìlànà òfin tí Olúwa fi lélẹ̀ ní àṣẹ fún Mose.

  20. Kìkì i wúrà, fàdákà, idẹ, irin, idẹ àti òjé.

  21. Ohunkóhun tí ó lè la iná ni kí ẹ̀yin ó mú la iná, nígbà náà ni yóò jẹ́ mímọ́. Ṣùgbọ́n ẹ yóò fi omi ìyàsímímọ́ sọ ọ́ di mímọ́. Àti gbogbo ohun tí kò lè la iná kọjá ni kí a mú la inú omi.

  22. Ní ọjọ́ keje, ẹ fọ aṣọ yín, ẹ̀yin yóò sì mọ́, nígbà náà ní ẹ̀yin yóò lè wọ inú ibùdó àjọ.”

  23. Nígbà náà ni gbogbo àwọn àgbàgbà ìlú tí ó wà nítòsí yóò wẹ ọwọ́ wọn lórí ẹgbọrọ abo màlúù tí a ti kan ọrùn rẹ̀ ní àfonífojì,

  24. Ó ṣe ọpọ́n mẹ́wàá fún fífọ nǹkan, ó sì gbé márùn-ún ka ìhà gúúsù àti márùn-ún ní àríwá. Nínú wọn ni ó ti ń fọ àwọn nǹkan tí wọ́n ń lò fún ẹbọ sísun ṣùgbọ́n, àwọn àlùfáà ní ó ń lo Òkun fún fífọ nǹkan.

  25. Èmí ó wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì yí pẹpẹ rẹ ká Olúwa.