Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Purification: By blood

13 ẹsẹ · 13 abala

Àwọn ẹsẹ nípa By blood

  1. Nígbà náà ni ó rán àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Israẹli, wọ́n sì rú ẹbọ sísun, wọ́n fi ọ̀dọ́ màlúù rú ẹbọ àlàáfíà si Olúwa.

  2. Mose bu ìlàjì ẹ̀jẹ̀ ẹran sínú abọ́, ó sì fi ìlàjì tókù wọn ara pẹpẹ.

  3. Nígbà náà ni ó sì mú ìwé májẹ̀mú, ó sì kà á sí àwọn ènìyàn. Wọ́n dáhùn pé, “Àwa yóò ṣe gbogbo ohun tí Olúwa wí. Àwa yóò sì gbọ́rọ̀.”

  4. Nígbà náà ni Mose gbé ẹ̀jẹ̀, ó sì wọn sí àwọn ènìyàn náà lára pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Olúwa ti ṣe pẹ̀lú yín ni ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.”

  5. Lẹ́yìn náà kí ó ri ààyè ẹyẹ pẹ̀lú igi kedari, òdòdó àti ẹ̀ka hísópù bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí a ti pa sínú omi náà.

  6. Ìgbà méje ni kí o wọ́n omi yìí sí ara ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́ kúrò nínú ààrùn ara náà kí ó ju ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ ní ìta gbangba.

  7. Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ọmọ màlúù, ṣùgbọ́n nípa ẹ̀jẹ̀ òun tìkára rẹ̀, o wọ Ibi Mímọ́ Jùlọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, lẹ́yìn tí ó ti rí ìdáǹdè àìnípẹ̀kun gbà fún wa.

  8. Nítorí bí ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ti akọ màlúù àti eérú ẹgbọrọ abo màlúù tí a fi wọ́n àwọn tí a ti sọ di aláìmọ́ ba ń sọ ni di mímọ́ fún ìwẹ̀nùmọ́ ara:

  9. mélòó mélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, ẹni, nípa Ẹ̀mí ayérayé, tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ sí Ọlọ́run láìní àbàwọ́n, yóò wẹ èérí ọkàn yín nù kúrò nínú òkú iṣẹ́ láti sin Ọlọ́run alààyè?

  10. Nítorí nígbà tí Mose ti sọ gbogbo àṣẹ nípa ti òfin fún gbogbo àwọn ènìyàn, ó mú ẹ̀jẹ̀ ọmọ màlúù àti ti ewúrẹ́, pẹ̀lú omi, àti òwú òdòdó, àti ewé hísópù ó sì fi wọ́n àti ìwé pàápàá àti gbogbo ènìyàn.

  11. Wí pé, “Èyí ní ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Ọlọ́run pàṣẹ fún yín.”

  12. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n àgọ́, àti gbogbo ohun èlò ìsìn.

  13. Ó sì fẹ́rẹ̀ jẹ́ ohun gbogbo ni a fi ẹ̀jẹ̀ wẹ̀nù gẹ́gẹ́ bí òfin; àti pé láìsí ìtàjẹ̀ sílẹ̀ kò sí ìdáríjì.