- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Offerings
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ sísun.
Àlùfáà yóò sì ti ìka rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, yóò sì fi sí orí ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, yóò sì da ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ.
Kí ó yọ gbogbo ọ̀rá rẹ̀ bó ti yọ ọ̀rá lára ọ̀dọ́-àgùntàn ọrẹ àlàáfíà, àlùfáà yóò sì sun ún ní orí pẹpẹ, lórí ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀, a ó sì dáríjì í.
Kí ó ṣe àtúnṣe nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀ nínú ti àwọn ohun mímọ́, kí ó sì fi ìdámárùn-ún kún iye rẹ̀, kí ó sì kó gbogbo rẹ̀ fún àlùfáà. Àlùfáà yóò sì fi àgbò ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà ṣe ètùtù fún, a ó sì dáríjì í.
“Bí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe ohun tí kó yẹ ko ṣe sí ọ̀kan nínú òfin Olúwa, bí kò tilẹ̀ mọ̀, ó jẹ̀bi, yóò sì ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀
kí ó mú àgbò kan láti inú agbo ẹran wá sọ́dọ̀ àlùfáà, fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àgbò tí kò lábùkù tí ó sì níye lórí bí iye owó ibi mímọ́. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà, fún àṣìṣe tí ó ṣe láìmọ̀, a ó sì dáríjì í.
Ẹbọ ẹ̀bi ni, ó ti jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀ sí Olúwa.”
Fún ìtánràn rẹ̀, ó gbọdọ̀ mú àgbò kan láti inú agbo ẹran wá fún àlùfáà, àní síwájú Olúwa, ẹbọ ẹ̀bi, àgbò aláìlábùkù, tó sì níye lórí bí iye owó ibi mímọ́.
“Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ‘Wọ̀nyí ni ìlànà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí ẹ sì pa ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ níwájú Olúwa, níbi tí ẹ ti ń pa ẹran ẹbọ sísun, ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.
“ ‘Wọ̀nyí ni àwọn ìlànà fún rírú ẹbọ ẹ̀bi, tí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.
“ ‘Wọ̀nyí ni àwọn ìlànà fún ọrẹ àlàáfíà tí ẹnikẹ́ni bá gbé wá síwájú Olúwa.
“ ‘Bí ẹni náà bá gbé e wá gẹ́gẹ́ bí àfihàn ọkàn ọpẹ́, pẹ̀lú ẹbọ ọpẹ́ yìí, ó gbọdọ̀ mú àkàrà aláìwú tí a fi òróró pò wá àti àkàrà aláìwú fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a dà òróró sí àti àkàrà tí a fi ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò ṣe.
Pẹ̀lú ọrẹ àlàáfíà rẹ̀, kí ó tún mú àkàrà wíwú wá fún ọpẹ́,
kí ó mú ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú oríṣìíríṣìí ọrẹ àlàáfíà rẹ wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún Olúwa, ó jẹ́ tí àlùfáà tí ó wọ́n ẹ̀jẹ̀ ọrẹ àlàáfíà.
Ẹran ọrẹ àlàáfíà ti ọpẹ́ yìí ni wọ́n gbọdọ̀ jẹ ní ọjọ́ gan an tí wọ́n rú ẹbọ, kò gbọdọ̀ ṣẹ́ ẹran kankan kù di àárọ̀ ọjọ́ kejì.
“ ‘Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé ó mú ọrẹ wá, nítorí ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ tàbí kí ó jẹ́ ọrẹ àtinúwá, wọn yóò jẹ ẹbọ náà ní ọjọ́ tí wọ́n rú ẹbọ yìí, ṣùgbọ́n wọ́n lè jẹ èyí tó ṣẹ́kù ní ọjọ́ kejì.
Gbogbo ẹran tó bá ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta ní ẹ gbọdọ̀ sun.
Bí ẹ bá jẹ ọ̀kankan nínú ẹran ọrẹ àlàáfíà ní ọjọ́ kẹta, kò ni jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. A kò ní í kà á sí fún ẹni tó rú ẹbọ náà, nítorí pé ó jẹ́ àìmọ́, ẹnikẹ́ni tó bá sì jẹ ẹ́, ni a ó di ẹ̀bi rẹ̀ rù.
Pẹ̀lú ọwọ́ ara rẹ̀ ni kí ó fi mú ọrẹ tí a fi iná sun wá fún Olúwa, kí ó mú ọ̀rá àti igẹ̀, kí ó sì fi igẹ̀ yìí níwájú Olúwa bí ọrẹ fífì.
Kí o sì sọ fún àwọn ará Israẹli pé, ‘Ẹ mú òbúkọ kan wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọmọ màlúù àti ọ̀dọ́-àgùntàn kan, kí méjèèjì jẹ́ ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù fún ẹbọ sísun,
àti akọ màlúù kan àti àgbò kan fún ẹbọ àlàáfíà àti ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi òróró pò láti fi rú ẹbọ ní iwájú Olúwa. Nítorí pé Olúwa yóò farahàn yín ní òní.’ ”
Aaroni mú ẹbọ tó jẹ́ ti àwọn ènìyàn wá. Ó mú òbúkọ èyí tó dúró fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn ó sì pa á, ó fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ti àkọ́kọ́.
Ó mú ẹbọ sísun wá, ó sì rú u gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí a fi lélẹ̀.
Ó tún mu ẹbọ ohun jíjẹ wá, ó bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú rẹ̀, ó sì sun ún lórí pẹpẹ ní àfikún ẹbọ sísun tí àárọ̀.
Ó pa akọ màlúù àti àgbò bí ẹbọ àlàáfíà fún àwọn ènìyàn. Àwọn ọmọ Aaroni sì mú ẹ̀jẹ̀ ẹran náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì wọn yí pẹpẹ náà ká.