Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Meekness

109 ẹsẹ · 29 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹ̀yin ará mi, ẹ kìlọ̀ fún àwọn ọ̀lẹ ti ó wà láàrín yín, ẹ gba àwọn tí ẹ̀rù ń bà ní ìyànjú, ẹ tọ́jú àwọn aláìlera pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kí ẹ sì ní sùúrù pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.

  2. Ẹ rí i pé kò sí ẹni tí ó fi búburú san búburú, ṣùgbọ́n ẹ máa lépa èyí tí í ṣe rere láàrín ara yín àti sí ènìyàn gbogbo.

  3. Kí Olúwa máa tọ́ ọkàn yín ṣọ́nà sí ìfẹ́ Ọlọ́run àti sínú sùúrù Kristi.

  4. Ǹjẹ́ alábojútó yẹ kí ó jẹ́ aláìlẹ́gàn, ọkọ aya kan, olùṣọ̀ràn, aláìrékọjá, oníwà rere, olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, ẹni tí ó lè ṣe olùkọ́.

  5. Kí ó má jẹ́ ọ̀mùtí, tàbí oníjàgídíjàgan, tàbí olójúkòkòrò, bí kò ṣe onísùúrù, kí ó má jẹ́ oníjà, tàbí olùfẹ́ owó.

  6. Ṣùgbọ́n ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, sá fún nǹkan wọ̀nyí; kí ó sì máa lépa òdodo, ìwà-bí-Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́ sùúrù, ìwà tútù.

  7. Máa ja ìjà rere ti ìgbàgbọ́, di ìyè àìnípẹ̀kun mú nínú èyí tí a pè ọ sí, ti ìwọ sì ṣe ìjẹ́wọ́ rere níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀.

  8. Ìránṣẹ́, Olúwa kò sì gbọdọ̀ jà; bí kò ṣe kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí ènìyàn gbogbo ẹni tí ó lè kọ́ni, àti onísùúrù.

  9. Ẹni tí yóò máa kọ́ àwọn alátakò pẹ̀lú ìwà tútù, ní ìrètí pé Ọlọ́run lè fún wọn ní ìrònúpìwàdà sí ìmọ̀ òtítọ́,

  10. Kọ́ àwọn àgbà ọkùnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti ní ìrònú àti láti jẹ́ ẹni àpọ́nlé àti ẹni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Wọn gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó jinlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, nínú ìfẹ́ àti nínú ìpamọ́ra.

  11. Kọ́ àwọn ẹrú láti ṣe ìgbọ́ràn sí àwọn olówó wọn nínú ohun gbogbo, láti máa gbìyànjú láti tẹ́ wọn lọ́rùn, wọn kò gbọdọ̀ gbó olówó wọn lẹ́nu,

  12. Rán àwọn ènìyàn náà létí láti máa tẹríba fún ìjọba àti àwọn aláṣẹ. Kí wọn ṣe ìgbọ́ràn nígbà gbogbo, kí wọn sì múra fún iṣẹ́ rere gbogbo.

  13. Wọn kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ ẹnikẹ́ni ní ibi, kí wọn jẹ́ ẹni àlàáfíà àti ẹni pẹ̀lẹ́, kí wọn sì máa fi ìwà tútù gbogbo hàn sí gbogbo ènìyàn.

  14. Nítorí ẹ̀yin kò le ṣe aláìní sùúrù, nítorí ìgbà tí ẹ̀yin bá ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tan kí ẹ̀yin le gba ìlérí náà.

  15. Ẹ máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú ènìyàn gbogbo, àti ìwà mímọ́, láìsí èyí yìí kò sí ẹni tí yóò rí Olúwa.

  16. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí sùúrù kí ó ṣiṣẹ́ àṣepé, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ pípé àti aláìlábùkù tí kò ṣe aláìní ohunkóhun.

  17. Kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́; jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn kí ó máa yára láti gbọ́, kí ó lọ́ra láti fọhùn, kí ó si lọ́ra láti bínú;

  18. Nítorí náà, ẹ lépa láti borí gbogbo èérí àti ìwà búburú tí ó gbilẹ̀ yíká, kí ẹ sì fi ọkàn tútù gba ọ̀rọ̀ náà tí a gbìn, tí ó lè gba ọkàn yín là.

  19. Ta ni ó gbọ́n tí ó sì ní ìmọ̀ nínú yín? Ẹ jẹ́ kí ó fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn nípa ìwà rere, nípa ìwà tútù ti ọgbọ́n.

  20. Ṣùgbọ́n ọgbọ́n tí ó ti òkè wá jẹ́ mímọ́ ní àkọ́kọ́, ti àlàáfíà, àti ti ìrẹ̀lẹ̀, kì í sì í ṣòro láti bẹ̀, ó kún fún àánú àti fún èso rere, kì í ṣe ojúsàájú, a sì máa sọ òtítọ́.

  21. Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ àlàáfíà a sì máa gbin èso àlàáfíà ní àlàáfíà.

  22. Ẹ̀yin ọmọ ọ̀dọ̀, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọ̀gá yín pẹ̀lú ìbẹ̀rù gbogbo, kì í ṣe fún àwọn ẹni rere àti oníwà tútù nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn òǹrorò pẹ̀lú.

  23. Nítorí pé èyí ní ìgbóríyìn fún, bí ènìyàn bá fi ara da ìrora, ìjìyà lọ́nà àìtọ́, nítorí ọkàn rere sí Ọlọ́run.

  24. Ṣùgbọ́n ògo kín ni ó jẹ́, nígbà tí ẹ ba ṣẹ̀ tí a sì lù yín, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á? Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá ń ṣe rere tí ẹ sì ń jìyà, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á, ẹ̀yín ní ọpẹ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

  25. Sí èyí ni a pè yín: nítorí Kristi pẹ̀lú jìyà fún un yin, ó fi àpẹẹrẹ sílẹ̀ fún un yín, kí ẹ̀yin lè máa tọ ipasẹ̀ rẹ̀: