Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Meekness

109 ẹsẹ · 29 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. (Mose sì jẹ́ ọlọ́kàn tútù ju gbogbo ènìyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé lọ).

  2. Dafidi sì banújẹ́ gidigidi, nítorí pé àwọn ènìyàn náà sì ń sọ̀rọ̀ láti sọ ọ́ lókùúta, nítorí ti inú gbogbo àwọn ènìyàn náà sì bàjẹ́, olúkúlùkù ọkùnrin nítorí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti nítorí ọmọ rẹ̀ obìnrin ṣùgbọ́n Dafidi mú ara rẹ̀ lọ́kàn le nínú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.

  3. Abiṣai ọmọ Seruiah sì wí fún ọba pé, “Èéṣe tí òkú ajá yìí fi ń bú olúwa mi ọba? Jẹ́ kí èmi kọjá, èmi bẹ̀ ọ́, kí èmi sì bẹ́ ẹ́ lórí.”

  4. Ọba sì wí pé, “Kín ni èmi ní ṣe pẹ̀lú yín, ẹ̀yin ọmọ Seruiah? Bí ó bá ń bú èébú, nítorí tí Olúwa ti wí fún un pé, ‘Bú Dafidi!’ Ta ni yóò sì wí pé, ‘Kín ni ìdí tí o fi ṣe bẹ́ẹ̀.’ ”

  5. Dafidi sì wí fún Abiṣai, àti fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wò ó, ọmọ mi tí ó ti inú mi wá, ń wá mi kiri, ǹjẹ́ mélòó mélòó ni ará Benjamini yìí yóò sì ṣe? Fi í sílẹ̀, sì jẹ́ kí o máa yan èébú; nítorí pé Olúwa ni ó sọ fún un.

  6. Bóyá Ọlọ́run yóò wo ìpọ́njú mi, Olúwa yóò sì fi ìre san án fún mi ní ipò èébú rẹ̀ lónìí.”

  7. tálákà yóò jẹ yóò sì yó; àwọn tí n wá Olúwa yóò yin jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ wà láààyè títí ayérayé!

  8. Ó ṣe amọ̀nà àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ohun tí ó dára, ó sì kọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ọ̀nà rẹ̀.

  9. Yà kúrò nínú ibi kí o sì ṣe rere; wá àlàáfíà, kí o sì lépa rẹ̀.

  10. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ilẹ̀ náà, wọn yóò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.

  11. Nínú ọláńlá rẹ, máa gẹṣin lọ ní àlàáfíà lórí òtítọ́, ìwà tútù àti òtítọ́; jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ohun ẹ̀rù.

  12. Ìwọ ń ṣe ìdájọ́ láti ọ̀run, ilé ayé bẹ̀rù, ó sì dúró jẹ́ẹ́,

  13. nígbà tí, ìwọ Ọlọ́run, bá dìde láti ṣe ìdájọ́, láti gba àwọn ẹni ìnilára ilẹ̀ náà. Sela.

  14. Olúwa wa pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ó rẹ̀ àwọn ènìyàn búburú sílẹ̀.

  15. Nítorí Olúwa ní inú dídùn sí àwọn ènìyàn rẹ̀ ó fi ìgbàlà dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé.

  16. Onísùúrù ènìyàn ní òye tí ó pọ̀, ṣùgbọ́n onínú-fùfù ènìyàn máa ń fi ìwà aṣiwèrè hàn.

  17. Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ yí ìbínú padà ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ líle máa ń ru ìbínú sókè.

  18. Ènìyàn onínú ríru dá ìjà sílẹ̀ ṣùgbọ́n onísùúrù paná ìjà.

  19. Ó sàn láti jẹ́ onísùúrù ju ajagun ènìyàn lọ, ẹni tí ó pa ìbínú mọ́ra ju ajagun ṣẹ́gun ìlú lọ.

  20. Òkèlè gbígbẹ tòun tàlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ sàn ju ilé tí ó kún fọ́fọ́ fún ẹran àti ìjà.

  21. Ọgbọ́n ènìyàn a máa fún un ní sùúrù; fún ògo rẹ̀ ni láti fojú fo àṣìṣe dá.

  22. Iyì ni ó jẹ́ fún ènìyàn láti sá fún ìjà, ṣùgbọ́n gbogbo aláìgbọ́n a máa tètè wá ìjà.

  23. Nípa sùúrù a lè yí ọba lọ́kàn padà ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ rírọ̀ sí egungun.

  24. Àwọn ẹlẹ́yà a máa ru ìlú sókè, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn máa ń mú ìbínú kúrò.

  25. Òpin ọ̀rọ̀ dára ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ, sùúrù sì dára ju ìgbéraga lọ.