Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Journey of Israel Through The Desert

759 ẹsẹ · 177 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Wọ́n padà wá bá Mose àti Aaroni àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní ijù Kadeṣi Parani. Wọ́n mú ìròyìn wá fún wọn àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn, wọ́n fi èso ilẹ̀ náà hàn wọ́n.

  2. Wọ́n sì fún Mose ní ìròyìn báyìí, “A lọ sí ilẹ̀ ibi tí o rán wa, lóòtítọ́ ló sì ń sàn fún wàrà àti fún oyin! Èso ibẹ̀ nìyìí.

  3. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tó ń gbé níbẹ̀ lágbára, àwọn ìlú náà jẹ́ ìlú olódi bẹ́ẹ̀ ni ó sì tóbi púpọ̀. A tilẹ̀ rí àwọn irú-ọmọ Anaki níbẹ̀.

  4. Àwọn Amaleki ń gbé ní ìhà gúúsù; àwọn ará Hiti, àwọn ará Jebusi àti àwọn ará Amori ni wọ́n ń gbé ní orí òkè ilẹ̀ náà, àwọn ará Kenaani sì ń gbé ẹ̀bá òkun àti ní etí bèbè Jordani.”

  5. Kalebu sì pa àwọn ènìyàn náà lẹ́nu mọ́ níwájú Mose, ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á gòkè lọ lẹ́ẹ̀kan náà láti lọ gba ilẹ̀ náà, nítorí pé àwa le è gbà á.”

  6. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ gòkè lọ yẹ ilẹ̀ wò sọ pé, “Àwa kò le gòkè lọ bá àwọn ènìyàn wọ̀nyí nítorí pé wọ́n lágbára jù wá lọ.”

  7. Báyìí ni wọ́n ṣe mú ìròyìn búburú ti ilẹ̀ náà, tí wọ́n lọ yọ́wò wá fún àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n wí pé, “Ilẹ̀ tí a lọ yẹ̀ wò jẹ́ ilẹ̀ tí ń run àwọn olùgbé ibẹ̀. Gbogbo àwọn ènìyàn tí a rí níbẹ̀ jẹ́ ènìyàn tó fìrìgbọ̀n tó sì síngbọnlẹ̀.

  8. A sì tún rí àwọn òmíràn (irú àwọn ọmọ Anaki) àwa sì rí bí i kòkòrò tata ní ojú ara wa, bẹ́ẹ̀ ni àwa náà sì rí ní ojú wọn.”

  9. Gbogbo ìjọ ènìyàn sì gbóhùn sókè, wọ́n sì sọkún ní òru ọjọ́ náà.

  10. Gbogbo ọmọ Israẹli sì kùn sí Mose àti Aaroni, gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sì wí fún wọn pé, “Àwa ìbá kúkú ti kú ní ilẹ̀ Ejibiti. Tàbí kí a kúkú kú sínú aginjù yìí.

  11. Kí ló dé tí Olúwa fi mú wa wá sí ilẹ̀ yìí láti fi idà pa wá? Àwọn ìyàwó wa, àwọn ọmọ wa yóò sì di ìjẹ. Ǹjẹ́ kò wa, ní í dára fún wa bí a bá padà sí Ejibiti?”

  12. Wọ́n sì sọ fún ara wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á yan olórí kí á sì padà sí Ejibiti.”

  13. Wọ́n dìde ní àárọ̀ ọjọ́ kejì wọ́n sì gòkè lọ sí ìlú orí òkè, wọ́n wí pé, “Àwa ti ṣẹ̀, àwa yóò lọ sí ibi tí Olúwa ṣèlérí fún wa.”

  14. Mose sì dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ṣẹ̀ sí òfin Olúwa? Èyí kò le yọrí sí rere!

  15. Ẹ má ṣe gòkè lọ nítorí pé Olúwa kò sí láàrín yín. Ki á má ba à lù yín bolẹ̀ níwájú àwọn ọ̀tá yín.

  16. Nítorí pé àwọn ará Amaleki àti àwọn ará Kenaani ń bẹ níwájú yín, ẹ̀yin yóò sì ti ipa idà ṣubú. Nítorí pé, ẹ ti yà kúrò ní ọ̀nà Olúwa, Olúwa kò sì ní í wà pẹ̀lú yín.”

  17. Síbẹ̀síbẹ̀, pẹ̀lú àìfarabalẹ̀ wọn, wọ́n gòkè lọ sórí òkè náà, láìjẹ́ pé àpótí ẹ̀rí Olúwa tàbí Mose kúrò nínú ibùdó.

  18. Àwọn ará Amaleki àti àwọn ará Kenaani tó ń gbé lórí òkè sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n, wọ́n bá wọn jà, wọ́n sì lé wọn títí dé Horma.

  19. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli wà nínú aginjù, wọ́n rí ọkùnrin kan tí ń ṣá igi ní ọjọ́ Ìsinmi.

  20. Àwọn tó sì rí i níbi tó ti ń ṣá igi wọ́n sì mú un wá sí ọ̀dọ̀ Mose àti Aaroni àti síwájú gbogbo ìjọ ènìyàn,

  21. wọ́n fi sí ìpamọ́ nítorí pé ohun tí wọn ó ṣe fún un kò tí ì yé wọn.

  22. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Kíkú ni ọkùnrin náà yóò kú kí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sọ ọ́ lókùúta pa ní ẹ̀yìn ibùdó.”

  23. Wọ́n mú un jáde sí ẹ̀yìn ibùdó, gbogbo ìjọ ènìyàn sì sọ ọ́ lókùúta pa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  24. Kora ọmọ Isari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi àwọn ọmọ Reubeni: Datani àti Abiramu, àwọn ọmọ Eliabu, àti Oni ọmọ Peleti mú ènìyàn mọ́ra.

  25. Wọ́n sì dìde sí Mose, pẹ̀lú àádọ́ta lé nígba (250) ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Israẹli, ìjòyè nínú ìjọ, àwọn olórúkọ nínú àjọ, àwọn ọkùnrin olókìkí.