Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Curse

47 ẹsẹ · 9 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì tẹ̀lé àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mo ń fi fún ọ lónìí.”

  2. Ní ọjọ́ kan náà Mose pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé.

  3. Nígbà tí ìwọ bá ti kọjá a Jordani, àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Gerisimu láti súre fún àwọn ènìyàn: Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Josẹfu àti Benjamini.

  4. Àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Ebali láti gé ègún: Reubeni, Gadi, àti Aṣeri, àti Sebuluni, Dani, àti Naftali.

  5. Àwọn ẹ̀yà Lefi yóò ké sí gbogbo ènìyàn Israẹli ní ohùn òkè:

  6. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó fín ère tàbí gbẹ́ òrìṣà ohun tí ó jẹ́ ìríra níwájú Olúwa, iṣẹ́ ọwọ́ oníṣọ̀nà tí ó gbé kalẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

  7. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dójútì baba tàbí ìyá rẹ̀.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

  8. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí òkúta ààlà aládùúgbò o rẹ̀.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

  9. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣi afọ́jú lọ́nà ní ojú ọ̀nà.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

  10. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí ìdájọ́ po fún àlejò, aláìní baba tàbí opó.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

  11. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó baba rẹ̀, nítorí ó ti dójúti ibùsùn baba rẹ̀.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

  12. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹranko.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

  13. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú arábìnrin rẹ̀, ọmọbìnrin baba rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá rẹ̀.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

  14. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyá ìyàwó o rẹ̀.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

  15. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó pa aládùúgbò rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

  16. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti pa ènìyàn láìjẹ̀bi.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

  17. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí kò gbé ọ̀rọ̀ òfin yìí ró nípa ṣíṣe wọ́n.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

  18. Nígbà náà ni Joṣua mọ pẹpẹ kan fún Olúwa Ọlọ́run Israẹli, ní òkè Ebali,

  19. gẹ́gẹ́ bí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli. Ó sì kọ́ ọ́ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ nínú ìwé òfin Mose, pẹpẹ odindi òkúta, èyí tí ẹnìkan kò fi ohun èlò irin kàn rí. Wọ́n sì rú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà ní orí rẹ̀ sí Olúwa.

  20. Níbẹ̀, ní ojú àwọn ará Israẹli, Joṣua sì ṣe àdàkọ òfin Mose èyí tí ó ti kọ sí ara òkúta náà.

  21. Gbogbo Israẹli, àjèjì àti ọmọ ìlú, pẹ̀lú àwọn àgbàgbà, olórí àti onídàájọ́ dúró ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì àpótí ẹ̀rí Olúwa tí ó kọjú sí àwọn àlùfáà tí ó rù ú, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi. Ìdajì àwọn ènìyàn náà dúró ní òkè Gerisimu, àwọn ìdajì si dúró ni òkè Ebali, gẹ́gẹ́ bí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ rí, pé kí wọn súre fún àwọn ènìyàn Israẹli.

  22. Lẹ́yìn èyí, Joṣua sì ka gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin, ìbùkún àti ègún, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé òfin.