- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Contracts
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Nígbà náà ni Joṣua ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú wọn láti dá wọn sí, àti àwọn olórí ìjọ ènìyàn fi ọwọ́ sí àdéhùn náà nípa ṣíṣe ìbúra.
Ní ẹ̀yìn ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n ti ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn ará Gibeoni, àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ pé aládùúgbò wọn ni wọ́n, tí ń gbé ní tòsí wọn.
Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli kò si kọlù wọ́n, nítorí pé àwọn àgbàgbà ìjọ ènìyàn ti búra fún wọn ní orúkọ Olúwa Ọlọ́run Israẹli. Gbogbo ènìyàn sì kùn sí àwọn àgbàgbà náà,
ṣùgbọ́n gbogbo àwọn olórí dáhùn pé, “Àwa ti búra fún wọn ní orúkọ Olúwa Ọlọ́run Israẹli, a kò sì lè fọwọ́ kàn wọ́n nísinsin yìí.
Èyí ní àwa yóò ṣe sí wọn, àwa yóò dá wọn sí, kí ìbínú kí ó má ba à wá sórí wa, nítorí ìbúra tí a búra fún wọn.”
Wọ́n tẹ̀síwájú, “Ẹ dá wọn sí, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí wọn jẹ́ gégigégi àti apọnmi fún gbogbo ìlú.” Àwọn àgbàgbà náà sì mú ìlérí wọn ṣẹ fún wọn.
Nígbà náà ni Joṣua pe àwọn ọmọ Gibeoni jọ pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi tàn wá wí pe, ‘Àwa gbé ní ibi tí ó jìnnà sí yín,’ nígbà tí ó jẹ́ pé tòsí wa ní ẹ̀yin ń gbé?
Nísinsin yìí, ẹ̀yin di ẹni ègún, ẹ̀yin kò sì ní kúrò ní gégigégi àti apọnmi fún ilé Ọlọ́run mi.”
Wọ́n sì dá Joṣua lóhùn pé, “Nítorí tí a sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ dájúṣáká bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti pàṣẹ fún Mose ìránṣẹ́ rẹ̀, láti fún yín ní gbogbo ilẹ̀ náà, kí ó sì pa gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà run kúrò ní iwájú yín. Nítorí náà, àwa bẹ̀rù ẹ̀mí wa nítorí yín, èyí sì ni ìdí tí a fi ṣe bẹ́ẹ̀.
Nísinsin yìí, àwa wà ní ọwọ́ yín. Ohunkóhun tí ẹ bá rò pé ó yẹ ó si tọ́ lójú yín ní kí ẹ fi wá ṣe.”
Bẹ́ẹ̀ ní Joṣua sì gbà wọ́n là kúrò ní ọwọ́ àwọn ọmọ Israẹli. Wọn kò sì pa wọ́n.
Ní ọjọ́ náà ni ó sọ àwọn Gibeoni di aṣẹ́gi àti apọnmi fún àwọn ará ìlú àti fún pẹpẹ Olúwa ní ibi tí Olúwa yóò yàn. Báyìí ni wọ́n wà títí di òní yìí.
Àwọn ènìyàn mi yóò mú igi náà sọ̀kalẹ̀ láti Lebanoni wá sí Òkun, èmi ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí ọ ní fífò lójú omi Òkun Ńlá títí dé ibi tí ìwọ ó na ìka sí fún mi. Níbẹ̀ ni èmi yóò ti yà wọ́n sọ́tọ̀, ìwọ yóò sì kó wọn lọ. Ìwọ yóò sì gba ìfẹ́ mi nípa pípèsè oúnjẹ fún ilé mi.”
Báyìí ni Hiramu sì pèsè igi kedari àti igi firi tí Solomoni ń fẹ́ fún un,
Solomoni sì fún Hiramu ní ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) òsùwọ̀n ọkà oúnjẹ fún ilé rẹ̀, àti ogún òsùwọ̀n òróró dáradára. Solomoni sì ń tẹ̀síwájú láti ṣe èyí fún Hiramu lọ́dọọdún.
“Nítorí ìjọba ọ̀run dàbí ọkùnrin tí ó jẹ́ baálé kan, tí ó jíjáde lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, tí ó gba àwọn alágbàṣe sínú ọgbà àjàrà rẹ̀.
Òun pinnu láti san dínárì kan fún iṣẹ́ òòjọ́ kan. Lẹ́yìn èyí ó sì rán wọn lọ sínú ọgbà àjàrà rẹ̀.
“Ní wákàtí kẹta ọjọ́ bí ó ti ń kọjá níwájú ilé ìgbanisíṣẹ́, ó rí díẹ̀ nínú àwọn aláìríṣẹ́ tí wọ́n dúró ní ọjà.
Ó wí fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin pàápàá, ẹ lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà mi, bí ó bá sì di òpin ọjọ́, èmi yóò san iye ti ó bá yẹ fún yín.’
Wọ́n sì lọ. “Ó tún jáde lọ́sàn án ní nǹkan bí wákàtí kẹfà àti wákàtí kẹsànán, ó túnṣe bákan náà.
Lọ́jọ́ kan náà ní wákàtí kọkànlá ọjọ́, ó tún jáde sí àárín ìlú, ó sì rí àwọn aláìríṣẹ́ mìíràn tí wọ́n dúró. Ó bi wọ́n pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin kì í ṣiṣẹ́ ní gbogbo ọjọ́?’
“Wọ́n sì dáhùn pé, ‘Nítorí pé kò sí ẹni tí yóò fún wa ní iṣẹ́ ṣe.’ “Ó tún sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà ẹ jáde lọ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú nínú ọgbà àjàrà mi.’
“Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ẹni tó ni ọgbà àjàrà sọ fún aṣojú rẹ̀ pé, ‘Pe àwọn òṣìṣẹ́ náà, kí ó san owó iṣẹ́ wọn fún wọn, bẹ̀rẹ̀ láti ẹni ìkẹyìn lọ sí ti ìṣáájú.’
“Nígbà tí àwọn ti a pè ní wákàtí kọkànlá ọjọ́ dé, ẹnìkọ̀ọ̀kan gba owó dínárì kan.
Nígbà tí àwọn tí a gbà ṣiṣẹ́ lákọ̀ọ́kọ́ fẹ́ gba owó tiwọn, èrò wọn ni pé àwọn yóò gba jù bẹ́ẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gba owó dínárì kan.