Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Ark of the Covenant

88 ẹsẹ · 37 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà náà ni àwọn àlùfáà gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa wá sí ipò rẹ̀, sí ibi inú lọ́hùn ún ilé Olúwa, Ibi Mímọ́ Jùlọ, wọ́n gbé e sí abẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù.

  2. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti àwọn àgbàgbà Israẹli àti àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ láti gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa láti ilé Obedi-Edomu, pẹ̀lú inú dídùn.

  3. Nítorí Ọlọ́run tì ràn wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Lefi ẹni tí ó gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa, akọ màlúù méje pẹ̀lú àgbò méje láti fi ṣé ìrúbọ.

  4. Dafidi sì wọ efodu; aṣọ ìgúnwà ọ̀gbọ̀ dáradára, àti gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí ń ru àpótí ẹ̀rí náà, àti àwọn akọrin, àti Kenaniah olórí pẹ̀lú àwọn akọrin. Dafidi sì wọ aṣọ ìgúnwà funfun.

  5. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli gbé àpótí ẹ̀rí àti májẹ̀mú Olúwa gòkè wá pẹ̀lú ariwo, pẹ̀lú àyíká ìhó ayọ̀ àti láti fọn fèrè ti ìpè, àti kimbali, àti láti ta ohun èlò orin olókùn àti dùùrù olóhùn gooro.

  6. Nígbà náà ni Solomoni pe àwọn àgbàgbà Israẹli jọ sí Jerusalẹmu, gbogbo àwọn olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan àti àwọn olóyè àwọn ìdílé Israẹli, kí wọn kí ó gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa gòkè wá láti Sioni ìlú Dafidi.

  7. Gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli péjọ sí ọ̀dọ̀ ọba ní àkókò àjọ àgọ́.

  8. Gbogbo àwọn àgbàgbà Israẹli sì wá, àwọn ọmọ Lefi gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa.

  9. Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí náà gòkè àti àgọ́ ìpàdé àti gbogbo ohun èlò mímọ́ tí ó wà nínú àgọ́. Àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi ni ó mú wọn gòkè wá.

  10. Nígbà náà ni ọba Solomoni àti gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli tí ó péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wà níwájú àpótí ẹ̀rí náà wọ́n sì fi àgùntàn àti màlúù tí a kò le è kà tán rú ẹbọ, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è mọ iye wọn tán nítorí bí wọ́n ti pọ̀ tó.

  11. Nígbà náà ni àwọn àlùfáà gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa wá sí ipò rẹ̀, sí ibi inú lọ́hùn ún ilé Olúwa, Ibi Mímọ́ Jùlọ, wọ́n gbé e sí abẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù.

  12. Àwọn Kérúbù na ìyẹ́ wọn bo ibi àpótí ẹ̀rí náà àti àwọn ọ̀pá tí ó gbé e ró.

  13. Àwọn ọ̀pá rẹ̀ náà gùn tó bẹ́ẹ̀ tí a fi rí orí àwọn ọ̀pá náà láti ibi àpótí ẹ̀rí náà níwájú Ibi Mímọ́ náà, ṣùgbọ́n a kò rí wọn lóde. Níbẹ̀ ni ó sì wà títí di òní yìí.