- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1446–1406 BC
The Wilderness Years
Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Deuteronomi 27:20nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó baba rẹ̀, nítorí ó ti dójúti ibùsùn baba rẹ̀.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
- Deuteronomi 27:21nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹranko.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
- Deuteronomi 27:22nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú arábìnrin rẹ̀, ọmọbìnrin baba rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá rẹ̀.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
- Deuteronomi 27:23nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyá ìyàwó o rẹ̀.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
- Deuteronomi 27:24nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó pa aládùúgbò rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
- Deuteronomi 27:25nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti pa ènìyàn láìjẹ̀bi.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
- Deuteronomi 27:26nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí kò gbé ọ̀rọ̀ òfin yìí ró nípa ṣíṣe wọ́n.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
- Deuteronomi 28:1nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Bí ìwọ bá gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ ní kíkún kí o sì kíyèsára láti tẹ̀lé gbogbo ohun tí ó pàṣẹ tí mo fi fún ọ lónìí, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbé ọ lékè ju gbogbo orílẹ̀-èdè ayé lọ.
- Deuteronomi 28:2nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Gbogbo ìbùkún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ bí o bá gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.
- Deuteronomi 28:3nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ìbùkún ni fún ọ ni ìlú, ìbùkún ni fún ọ ní oko.
- Deuteronomi 28:4nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ìbùkún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èso ilẹ̀ rẹ, àti irú ohun ọ̀sìn rẹ àti ìbísí i màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ.
- Deuteronomi 28:5nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ìbùkún ni fún agbọ̀n rẹ àti fún ọpọ́n ipò ìyẹ̀fun rẹ.
- Deuteronomi 28:6nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá wọlé, ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde.
- Deuteronomi 28:7nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Olúwa yóò gbà fún ọ pé gbogbo ọ̀tá tí ó dìde sí ọ yóò bì ṣubú níwájú rẹ. Wọn yóò tọ̀ ọ́ wá ní ọ̀nà kan ṣùgbọ́n wọn yóò sá fún ọ ní ọ̀nà méje.
- Deuteronomi 28:8nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Olúwa yóò rán ìbùkún sí ọ àti sí ohun gbogbo tí o bá dáwọ́ rẹ lé. Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún un fún ọ nínú ilẹ̀ tí ó ń fi fún ọ.
- Deuteronomi 28:9nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Olúwa yóò fi ọ́ múlẹ̀ bí ènìyàn mímọ́, bí ó ti ṣe ìlérí fún ọ lórí ìbúra, bí o bá pa àṣẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ mọ́ tí o sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
- Deuteronomi 28:10nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé yóò rí i pé a pè ọ́ ní orúkọ Olúwa, wọn yóò sì bẹ̀rù rẹ.
- Deuteronomi 28:11nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Olúwa yóò fi àlàáfíà fún ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, fún ọmọ inú rẹ, irú ohun ọ̀sìn rẹ àti àwọn èso ilẹ̀ rẹ ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá rẹ láti fún ọ.
- Deuteronomi 28:12nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Olúwa yóò ṣí ọ̀run sílẹ̀, ìṣúra rere rẹ̀ fún ọ, láti rọ òjò sórí ilẹ̀ rẹ ní àsìkò rẹ àti láti bùkún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ. Ìwọ yóò yá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ṣùgbọ́n ìwọ kò ní í yá lọ́wọ́ ẹnìkankan.
- Deuteronomi 28:13nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Olúwa yóò fi ọ́ ṣe orí, ìwọ kì yóò sì jẹ́ ìrù. Bí o bá fi etí sílẹ̀ sí àṣẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ tí mo fi fún ọ kí o sì máa rọra tẹ̀lé wọn, ìwọ yóò máa wà lókè, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò wà ní ìsàlẹ̀ láé.
- Deuteronomi 28:14nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Má ṣe yà sọ́tùn tàbí sósì kúrò, nínú èyíkéyìí àwọn àṣẹ tí mo fi fún ọ ní òní yìí, kí o má ṣe tẹ̀lé àwọn ọlọ́run mìíràn láti máa sìn wọ́n.
- Deuteronomi 28:15nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n bí o kò bá gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì rọra máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mò ń fún ọ lónìí, gbogbo ègún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ.
- Deuteronomi 28:16nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ègún ni fún ọ ní ìlú, ègún ni fún ọ ní oko.
- Deuteronomi 28:17nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ègún ni fún agbọ̀n rẹ àti ọpọ́n ìpo-fúláwà rẹ.
- Deuteronomi 28:18nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ègún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èso ilẹ̀ rẹ, ìbísí màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ.